Orí Kẹta

1 Nísinsìn yí ìjòyè kan sí wà tí orúkọ rẹ̀ a má a jẹ́ Nikodémù, aládarí Júù kan. 2 Arákùnrin yì tọ Jésù wá ní òru Ó sí wí fún un pé, "olùkóni, à wá mọ̀ pé olùkọ́ni tí ó ti ọdọ Ọlọ́run wá ni Ìwọ ń se, nítorí kò sí ẹni tí ó le ṣe àwọn iṣé àmì wọ̀n yí tí Ìwọ ń ṣe àyàfi bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú rẹ̀." 3 Jésù dá a lóhùn pé, "lóòtọ́, lóòtọ́, bí kò se pé atún ènìyàn bí, kò le rì ìjọba Ọlọ́run. 4 Nikodémù wí fún un pé, "Bá wo ni a ṣè lé tún ènìyàn bí lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dàgbà tán? kò le wọ inú ìyá rẹ̀ ní ìgbà kejì kí á sì tún ń bí, Ó le ṣé bí?" 5 Jésù dáhùn,"lóòtọ́, lóòtọ́ bí kò bá ṣe pé abí ènìyàn nípa omi àti ẹ̀mí, kò le wọ ìjọba Ọlọ́run. 6 Èyí tí a bí nípa ti ara ti ara ní, àti èyí tí a si bí nìpa ti ẹ̀mí ti ẹ̀mí ni. 7 Kó má se yà ọ́ lẹ́nu wípé mo wí fún ọ́ pé, 'o gbọdọ̀ di àtùnbí.' 8 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ibikíbi tí ó wù ú; ìwọ ń gbúro rẹ̀, ṣùgbọ̀n ìwọ kò mọ ibi ti ó ti ń wá tabi ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni gbogbo ẹni tí a bí nípa ti ẹ̀mí." 9 Nikodémù dáhùn ó sì fún un pe, "ǹkan wọ̀n yí yóò ti se le rí bẹ́ ẹ̀?" 10 Jésù dáhùn ó sì wí fún un pe, "Olùkọ́ni ti Ísírẹ́lì ni ìwọ sí í ǹ sé e, bẹ́ ẹ̀ sì ni ìwọ kò si mọ ǹkan wọ̀n yí í?" 11 lóòtọ́ lóòtọ́, Mo wí fún ọ, àwa ń sọ ǹkan tí àwa mọ̀, àti pé, àwa ńjẹ̀rí nípa ohun tí àwa tí rí í. Síbẹ̀ ẹ̀yin kò gbá ẹ̀rí wa. 12 Bí mo bá sọ nípa àwọn ohun ti ayé tí o kò bá sí gbàgbọ́, bá wo ni ó ti se gbàgbọ́ tí mo bá sọ nípa ohun ti ọ̀run fún ọ. 13 Kò sí ẹni tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò se ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wa- àní Ọmọ ènìyàn. 14 Gẹ́gẹ́ bí Mósè ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni agbọdọ̀ gbé Ọmọ ènìyàn sókè, 15 wí pé kí gbogbo ẹni tí o bá gbàgbọ́ nínú rẹ̀ bá a lè ní iyè àìnípẹ̀kun. 16 Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ ẹ̀ gẹ̀ ẹ́, tí o fí jẹ́ wí pé Ó fi ọmọkùnrin rẹ kan soso fún ni, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà à gbọ́ kì yòó kú, sùgbọ́n yòó nì iyè àìnípẹ̀kun. 17 Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ náà wá sí ayé láti da' aráyé lẹ́bi, ṣùgbọ́n láti gba aráyé la nípa sẹ rẹ̀ 18 Ẹnikẹ́ni tó bá gbà á gbọ́ a kò da lẹ́jọ́, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí kò gbà á gbọ́ ati dá a lẹ́jọ́ ná nítorí kò gbàgbọ́ nínú orúkọ ọmọ bíbí kan soso ti Ọlọ́run. 19 Èyí í ni ìdí fún ìdájọ́ nà: ìmọ́lẹ̀ nà wá sínú ayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn fẹ́raǹ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ wọn burú. 20 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń se ibi a má a kórira ìmọ́lẹ̀, bẹ́ ẹ̀ si ni kì í wá síbi ìmọ́lẹ̀ náà kí iṣé rẹ̀ má ba di àfihàn. 21 Ẹ̀wẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń se òtítọ́ a má a wá sí ibi ìmọ́lẹ̀ náà kí ó bà lè hàn kedere pé, àwọn isẹ́ rẹ̀ ni ase nínú Ọlọ́run 22 Lẹ́yìn ǹkan wọ̀nyí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yiǹ rẹ̀ kọjá lọ sí ilẹ̀ Jùdíà. Níbẹ̀ ni Ó lo ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú wọn ósì se ìrìbọmi pẹ̀lú. 23 Nísinsìn yí, Jòhánú ń se ìrìbọmi bákan náà ni Énónì nítòsí Sálímù nítorí omi púpọ̀ wá níbẹ̀. Àwọn ènìyàn ń wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ a sì ń rí wọ́n bọmi, 24 nítorí a kò tí ì fi Jòhánù sínú túbú. 25 Nígbà náà, èdè àìyedè kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánú àti Júù kan nípa ìwẹ̀númọ́. 26 Wọ́n tọ Jòhánú lọ wọ́n sì wí fún un pe, "Olùkọ́ni, ẹni tí Ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìhàkejì ti odò Jódánì, ẹni tí ìwọ jẹ̀ri nípa rẹ̀, wò ó, óuń se ìrìbọmi, àwọn ènìyàn sí ń lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀." 27 Jòhánù dáhùn wípé, "Ènìyàn kò le rí ohunkóhun gbà àyàfi tí a bá fi fún un láti ọ̀run wá. 28 Ẹ̀yin tìkaráyín pẹ̀lú le è jẹ̀rí pé mo wí pe, 'Èmi kì í se Kírísítì náà,' ṣùgbọ́n dípò bẹ́ ẹ̀, ''a ti rán mi sáájú rẹ̀.' 29 Ìyàwó jẹ́ ti ọkọ ìyàwó. Nísinsì yí, ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó, èyí tó dúró tó sì gbọ́ òhùn rẹ̀ yọ ayọ̀ ńlá gidigidi nítorí ó gbọ ohùn ọkọ ìyàwó. Èyí yí ló sí mú ayọ̀ mi kún. 30 Ó gbọdọ̀ má a pọ̀ si, kí èmi sí má a dín kù. . 31 Ẹni tí ó wá láti òkè Ó ju ohun gbogbo lọ. Ẹni tí ó wá láti ayé ti ayé ní se, òun a sì ma sọ nípa ohun ti ayé. Ẹni tí ó wá láti ọ̀run ju ohun gbogbo lọ. 32 òun a má a jẹ́ri nípa ohun tí Ó rí àti èyí tí Ó tí gbọ́. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33 Ẹni tí ó sì ti gba ẹ̀rí rẹ̀ fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pe òtìtọ́ ni Ọlọ́run. 34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run rán ń sọ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí kò fi ẹ̀mí náà fún ni nípa òdiwọ̀n. 35 Baba náà fẹ́ràn Ọmọ náà, Ó sì ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀. 36 Ẹni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọmọ náà, ó ní iyè àìnípèkun, ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó ba se àìgbọràn sí ọmọ náà kí yóò rí iyè, ṣùgbọ́n ìbínú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.