1 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, ìgbeyàwó kan wáyé ní Kánà ti Gálílì, ìya Jésù sí wà níbẹ̀ pẹ̀lú. 2 A sì pe Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ sí ibi àsè ìgbeyáwò. 3 Nígbà tí wáínì sí taǹ án, ìya Jésù wí fún un, "wọn kò ní wáínì mọ́." 4 Jésù sí wì fún un, "arábìnrín, è é se tí ìwó fi tọ̀ mí wá? Àkókò mi kò í tì tó." 5 Ìya rè wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà, "Ohunkóhun tí ó bá sọ, ẹ sé e." 6 Nítòsí ni ìkòkò omi mẹ́fà sí wà fún ìwẹnùmó àwọn Júù, ọ̀kọọ̀kan wọn sí gbà tó ìwọ̀n jálá omi méjì sí mẹ́ta. 7 Jésù wí fuń wọn, "Ẹ kún ìkòkò omi náà pẹ̀lú omi." Nítorí náà wọ́n kún áwọn ìkòkò omi náà dé etí. 8 Nígbà náà ní Ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà, "Ẹ bù díẹ̀ nísinsìn yí, kí ẹ sì mu u tọ olórí alásè lọ." Wọ́n sì se bẹ́ ẹ̀. 9 Olórí alásè náà sì tọ́ omi tí ó di wáínì náà wò, ṣùgbọ́n kò mọ̀ ibi tó tí wá (ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ tó bù ú mọ̀). Nígbà náà ni ó pe ọkọ ìyàwó náà 10 ósì wí fún un, "Gbogbo ènìyàn kọ́kọ́ ma a ń pín wáínì dáradára, àti lẹ́yìn èyí i nì, èyí tí owó rẹ̀ kò wọ́n púpọ̀ àní lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mu àmuyó. Ṣùgbọ́n ìwo pá èyí tó dárá mọ́ tí tí ó fi di àkókò yí í." 11 Èyí í ni iṣẹ́ àmì àkọ́kọ́ tí Jésù se ní Kánà ti Gálílì, ó sì se àfihàn ògo rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sí gbà á gbọ́. 12 Lẹ́yìn èyí, Jésù, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ èyìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapanáúmù wọ́n sì dúró níbẹ̀ ní ọjọ́ melòókan. 13 Nísinsìn yí àjọ ìrékọọjá àwọ̀n Júù súnmọ́ tòsí, Jésù sí gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. 14 Ó rí àwọn olùta màálù àti àgùntàn àti ẹyẹlé àti onípàsípààrọ̀ tí wọ́n jókò níbẹ̀. 15 Nítorí náà, Ó hun pàsán, Ó sì le gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹ́mpílì àti àwọn àgùntàn àti màálù náà pẹ̀lú. Ó sì fọ́n owó àwọn onípàsípàrọ̀ náà dànù, Ó sì yí tábílì wọn dànù. 16 Sí àwọn tó ń ta ẹyẹlé, Ó wípé, "Ẹ mú àwọn ǹkan wọ̀nyí kúrò ní ibì yì í. Ẹ dẹ́kun àti ma sọ ilé bàbá mi di ibi ìtájà. 17 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, "Ìtara fún ilé rẹ̀ yóò jẹ mí run." 18 Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àwọn Júù dáhùn wọ́n wí fún un, "àmì wo lo Ó fi hàn wá, níwọ̀n ìgbà tí Ò ń se ǹkan wọ̀nyí? 19 Jésù dáhùn, "ẹ wó tém̀pílì yí palẹ̀, àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Èmi yóò gbe dìde." 20 Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àwọn Júù wí pé "Tẹ́m̀pílì yí ni a fi ọdún mẹ́rìndínníọgọ́ta kọ́, Ìwọ yóò sí gbe dìde láàrín ọjọ́ mẹ́ta?" 21 Bó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé, Ó sọ nípa tẹ́m̀pílì ti àgọ́ ara rẹ̀. 22 Lẹ́yìn tí a ji Í dide kúrò níipò awọ̀n òkú, àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ rántí pé Ó ti wí èyí í, wọ́n si gba ìwé mímọ́ gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí Jésù ti sọ. 23 Nísinsìn yí, nígbà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù ní bi àsè àjọ ìrékọjá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ nínu orúkọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n rí àwọn iṣé àmì tí Ó se. 24 Ṣùgbọ́n Jésù kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú wọn nítorí Ó mọ gbogbo wọn, 25 nítorí òun kò ní lò ẹnikẹ́ni láti jẹ̀rí fún un nípa ènìyàn, nítorí tí Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.