Ori Kìnní

1 Ní àtètèkọ́se ni ọ̀rọ̀ wà, ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni ọ̀rọ̀ náà. 2 Òun nâ ló ti wà ní àtètèkọ́se pẹ̀lú Ọlọ́run. 3 Nípa sẹ rẹ̀ lati da oun gbogbo, lẹ́yìn rẹ̀ akòdá o n kan nínú èyí tií adá. 4 Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè náà sìni ìmọ́lẹ̀ aráyé. 5 Ìmọ́lẹ̀ mọ́ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì le bori rẹ̀. 6 Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, tí a à n pè ní Johannu. 7 Ówá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ̀rìí láti jẹ́ẹ̀rí sí ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ẹ̀dá le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gbàgbọ́. 8 Johannu ti ka ra rẹ̀ kǐ se ìmọ́lẹ̀ nâ, ṣùgbọ́n ó wá láti jẹ́ẹ̀rí sí ìmọ́lẹ̀ náà. 9 Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́, tí ó fi ìyè fún aráyé, ó n bọ̀ wá sí ayé. 10 Ó wà nínú ayé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni afi dá ayé, ayé kò sì mọ̀ọ́. 11 Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ́ kò sì gbà á. 12 Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́, ni a fún ní àsẹ láti di ọmọ Ọlọ́run. 13 Àwọn ti a kò bí nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ìfẹ́ ẹran ara tàbí nípa ìfẹ́ ènìyàn bíkòse nípa ti Ọlọ́run. 14 Ọ̀rọ̀ nâ di ara ó sì n báwa gbé. A ti ri ògo rẹ̀, ògo bí ti ọ̀kan soso tí ó ti ọ̀dọ̀ bàbá wá, tí ó kún fún òtítọ́ àti òdodo. 15 Johannu sẹ̀lẹ́rí rẹ̀, ó ké pé, "Èyí ni ẹni náa ti mo ti wí, 'ẹni tí n bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀ jùmí lọ, nítorí Ó wà sájú mi."' 16 Nítorí nínú ẹ̀kun rẹ̀ ni àwa ti rí ore ọ̀fẹ́ kún ore ọ̀fẹ́ gbà. 17 Afi òfin fún ni láti ọwọ́ Mose. Ore ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ tí ọ̀dọ̀ Jesu Kristi wa. 18 Kòsí ẹni náà tóti kọ́rí Ọlọ́run; Ọlọ́run ọ̀kan soso, tí ó wà ní ìhà Bàbá, òhun ló ti fi Ọlọ́run hàn fún ni. 19 Èyí ni ẹ̀rí Johannu nígbàtí àwọn ju rán àwọn àlúfà àti àwọn léfì sí láti Jerusalemu wá, láti bí wípé, "Tani ìwọ íse?" 20 Ó jẹ́wọ́, ko setan, Ó jẹ́wọ́ pé, "Èmi kìí se Kristi náà." 21 Wọ́n sì bi wípé, 'kíni ìwọ? Ìwọ́ íse Elijah bí?" Ó dáhùn, "Bẹ́ẹ̀ kọ́." Wọ́n ní, Ìwo ise Wòlíì bí?" Ó dáhùn, "Rárá." 22 Nígbànà ni wọ́n sì wí fún pé, "Tani ìwọ, kíá baà le jísẹ́ fún àwọn tí ó rán wa? Kíni o wí nípa ara rẹ?" 23 Ò dáhùn, "Èmi ni ohùn, ti óún kígbe ní aginjù: Ẹse ọ̀nà Olúwa ní títọ́, gẹ́gẹ́ bí wòlí Isaiah ti wí." 24 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Farisi náà ni a rán, 25 wọ́n bií lérèè, wọ́n sì wí fun pé, "Èése tí ìwọ fi n baptisi bí ìwọ kìí báse Kristi náà, tàbí Elijah tàbí Woli?" 26 Johannu dá won lóhùn, wípé, "Èmí baptisi pẹ̀lú omi. Ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ẹ kò mọ̀ dúró lárin yín. 27 Òun ni ẹni náà tí ó n bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹnití èmi kòtó láti tú." 28 Òun kan wọ̀nyi sẹlẹ̀ ní Bẹthani ni apá kejì Jordani, níbi tí Johannu ti n se ibaptisi. 29 Ní ijọ́ kejì, Johannu rí Jesu bí ó tin bọ̀ wá, ó wípé, "Kíyèsi, ọ̀dọ́ àgùtàn Ọlọ́run tí ó kó ẹ̀sẹ̀ aráyé lọ! 30 Èyí ni ẹni náà tí moti wí, ''Ẹni tí ó n bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀ jùmí lọ, nítorí óti wà sájú mi.'' 31 Èmi kò mòó, ṣugbọ́n èyí sẹ kíá le fi hàn fún israeli pé, èmí wá láti baptisi pẹ̀lú omi." 32 Johannu jẹ̀ẹ́rì sí n kan wọ̀nyí, wípé, "Morí ẹ̀mí bí àdàbà tí óhún ti ọ̀run bọ̀wá, ó sọ̀kalọ̀, ósi bàlée. 33 Èmi kò damọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tó rán mi láti baptisi pẹ̀lú omi wí fún mi pé, 'Lórí ẹni tí ìwọ ó ti rí ẹ̀mí tó sọ̀kalẹ̀ tọ́sì dúró lélórí, òhun ni ẹni náà tí yio baptisi pẹ̀lú Ẹ̀mí mímọ́.' 34 Èmí tiríi, mo sì ti sẹlẹ́ẹ̀rí èyí, wípé, èyí ni ọmọ Ọlọ́run." 35 Lẹ́ẹ̀kan si, ní ọjọ́ kejí, bí Johannu si se dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, 36 wọ́n rí Jesu bi ó ti n kọjá lọ, Johannu sì wípé, "Kíyèsi, ọ̀dọ́ àgùtàn Ọlọ́run!" 37 Lọ́gán tí ó sọ èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀ le Jesu lọ. 38 Nìgbànà ni Jesu bojú wẹ̀yìn, orí wọ́n, ósì bi wọ́n wípé, "Kíni ẹ̀yin fẹ́?" Wọ́n da lóhùn, "Rabbi" (ìtumọ́, olùkọni), "Níbo ni ìwọ n gbé?" 39 Ósì wí fún wọn pé, "Ẹwá wòó." Wọ́n wá, wọ́n sì ri ibi tí n gbé; wọ́n dúró pẹ̀lú rẹ̀ lọ́jọ́ náà nítorí ó ti n di wákàtí kẹwà ọjọ. 40 Ọ̀kan nínú àwọn méjí tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johannu tí ó sì tẹ̀lé Jesu ni Anderu, arákùnrin Simoni Peteru. 41 Orí arákùnrin rẹ̀ Simoni ó sì wífún pé, "Àwá tirí Messia náà" (Ìtumọ̀, "Kristi") 42 Ó mun wá sọ́dọ̀ Jesu, Jesu wó, ó sì wípé, "Ìwọ ni Simoni ọmọkùnrin Johannu. A ó ma pé ọ ní, Kephasi'' (Itumo, Peteru). 43 Ní ijọ́ kejì, nígbàtí Jesu fẹ́ máa lọ sí Galili, Ó rí Philipi Ó sì wí fun pé, "Máa tọ̀ mí lẹ́yìn." 44 Philipi jẹ́ ará Bethsaida ti ìlú aràkùnrin Anderu àti Peteru. 45 Philipi rí Nathanieli, ósì wí fún pé, "Ẹnìkan náà tí Moses kọ nínú ìwé òfin àti àwọn Wòlí, àwá ti rí: Jesu ọmọ Josefu ará Nasarẹti." 46 Nathanieli wí fún pé, "Njẹ́ ohun rere kán a lè ti Nasarẹti wá?" Philipi sì da lóhùn pé, "Wá wǒ." 47 Jesu rí Nathanieli bí ó ti n tọ̌ bọ̀ ósì wí níparẹ̀ pé, "Wòó, Israeli tòótọ́ nínú enití ẹ̀tàn kòsí!" 48 Nathanieli fèsì, "Báwo ló se mò mí?" Jesu dáhùn ósì wí fún pé, "Kí Philipi tó pè ọ́, nígbàtí o wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo rí ọ." 49 Nathanieli sì dáhùn, "Rabbi, ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ se! Ọba Israeli sì ni ìwọ ise!" 50 Jesu da lóhùn ósì wí fún pé, "Nítorí Èmí wí fún ọ pé, 'ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́' ni ìwọ se gbagbọ bí? Wọ o rí oun tí ó tóbi ju yi lọ." 51 Nígbánà ni ówí pé, "Lótìtọ́ lótìtọ́ ni mowí fún ọ, ìwọ yíò rí awọn ọ̀run sí sílẹ̀, àwọn angẹli Ọlọ́run wọ́n digba sọ̀kalẹ̀ gòkè lórí Ọmọ eniyan."