Orí Kẹwàá

1 Dájúdájú, mo sọ fún un yín wípé: ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà agbo àgùntaǹ wọ ilé, ṣùgbón tí o gba ọ̀nà ẹ̀bùrú wọ ilé; ìgárá ọlọ́ṣà àti olè ni. 2 Ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà wọ ilé, ni ojúlówó olùṣọ́ àgùntàn. 3 Asọ́gbà a sílẹ̀kún fún un. Nítorí àwọn àgùntaǹ dá ohùn rẹ̀ mọ̀, ó pè àwọn tirẹ̀, ó daríi wọn jáde. 4 Nígbàtí ó sì ti kó gbogbo àgùntaǹ tirẹ̀ tań, ó ṣiwájú wọn, wọn ńtẹ̀lée nítorí wọń mọ ohùn rẹ̀. 5 Àmọ́, wọn kò ní tẹ̀lé àjèjì nítorí wọn kò mọ ohùn rẹ̀, ńṣe ni wọn yóò yẹra fún un, nítorí wọn kò mọ ohùn àjèjì. 6 Bí Jésù tilẹ̀ sọ̀rọ̀ yìí bí òwe, síbẹ̀ kò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀. 7 Jésù tún tẹ̀ẹ́ mọ́ wọn létí wípé: "Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, 8 Ìgárá ọlọ́ṣà àti olé ni àwọn tí o ṣaájúù mi wá, àwọn àgùntaǹ kò sì tẹ́tí sí wọn." 9 Èmi ni ọ̀nà tàràtá bí ẹnikẹ́ni bá gba ọ̀dọ̀ mi wọ ilé, yóò wọ ilé yóò sì jáde yóò sì rí koríko tútù. 10 Ṣùgbọ́n ti olè kò rí bẹ́ẹ̀: wọ́n wá láti jalè, láti pa àti láti parun. Ṣùgbọ́n èmi wá láti fuń ni ní ìyè lẹ́kùnrẹ́rẹ́. 11 Láìṣiyèméjì, Olùsọ́ Àgùntaǹ dáradára ni mí. Olùsọ́ àgùtaǹ dáradára fi ẹ̀mí i rẹ̀ lélẹ̀ fùn àgùntàn an rẹ̀. 12 Alágbàṣe kò dá àgùntaǹ ni, kì í sì í ṣe Olùsọ́ Àgùntaǹ. Ó rí ìkookò lókèerè, ó da àgùntaǹ sílẹ̀, ó sì sálọ, ìkookò kó àgùntaǹ lọ, ó sì da agbo rú. 13 Èyí rí bẹ́ ẹ̀ nítorí alágbàṣe kò ní ìtọ́jú fún àwọn àgùntaǹ. 14 Mo mọ àwọn àgùntaǹ mi àwọn àgùntaǹ mi sì mọ̀ mí, nítorí mo jẹ́ Olùsọ́ Àgùntaǹ dáradára. 15 Èyí ni Baba ṣe mọ̀ mí tí èmi náà sì mọ Baba, tí mo sì fi ẹ̀mí mi lélẹ̀. 16 Mo ní àwọn àgùntaǹ míraǹ tí mo gbọ́dọ̀ múwá si ágbo; wọn yóò gbọ́ ohuń mi, yóò sì jásí pé: agbo kan àti Olùsọ́ Àgùntaǹ kan. 17 Ìdí èyí ni Baba ṣe fẹ́raǹ mi: mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ fuń ara à mi. 18 Kò sì si ẹni tí ó lé gbàá lọ́wọ́ mi. Mo ní àṣẹ láti fii lélẹ̀ àti láti gbàá padà. Mo ti gba àsẹ yìí lọ́dọ̀ Baba à mi” 19 Ìpinyà sì bẹ́ sílẹ̀ láàrín àwọn Júù nítorí àwọn ọ̀rọ̀ náà. 20 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn wípé “Ó ni ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì ti dàrú. Ẹ ṣe ntẹ́tí sí I ?" 21 Àwọn tí ó kù wípé, “Àwọn ọ̀rò yìí kò le ti ẹnu ẹ̀mí dẹ́mónì jáde. Àbi ẹ̀mí èṣù le lajú afọ́jú bí?” 22 Ó sì tó àkókò ọdún ìyàsímímọ́ ní Jérúsálẹ́mù. 23 Àkókò yìí jẹ́ ìgbà òtútù. Jésù sì ńrìn ni tẹ́mpilì ni ìloro Sólómónì. 24 Àwọn Júù sì pé bòó (wọ́n pagbo yí I ká), wọ́n wípé, “O ó ti tán wa ní sùúrù pẹ́ to? Bí Krístì bá ni Ọ́, sọ ọ́ ní gbangba.” 25 Jésù sí dá wọn l’óhun wípé: ”Mo ti sọ fuń un yín ṣùgbọ́n ẹ kò gbàgbọ́ pé àwọn iṣẹ́ tí mò ńṣe ní orúkọ Bàbá mi ńjẹ́rìí ohun tí mo jẹ́. 26 Síbẹ̀ ẹ kò gbàgbọ́ nítorí ẹ kì i ṣe àguùntaǹ mi. 27 Àwọn àguǹtaǹ mi mọ ohuǹ mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì tẹ̀lé mi. 28 Mo fuń wọn ní ìyè ayéraye, kò sì sí ẹni tí yóò já wọn gbà l’ọ́wọ́ mi. 29 Bàbá mi tí o fiwọ́n fún mi ga ju àwọn yòókù lọ. Kò si sí ẹni tí ó lè jáwọn gbà lọ́wọ́ọ Bàba. 30 Èmi àti Bàba jẹ́ ọ̀kan. 31 Lẹ́yìn èyí ni àwọn Júù mú òkúta lẹ́ẹ̀kansíi láti sọ́ lí òkúta. 32 Jésù dáwọn l’óhùn wípé: mo ti fi oríṣiríṣi iṣẹ́ rere láti ọdo Bàbá haǹ yín, nítorí iṣẹ́ rere wo ni ẹ fẹ́ fi sọ mí ní òkúta? 33 Àwọo Júù dá a lóhùn, “a kò sọ Ọ́ ni òkúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọń nítori ọ̀rọ̀ òdì rẹ, nítorí ìwọ ènìyaǹ nfi ara rẹ wé Ọlọ́run.” 34 Jésù dá wọn lóhuǹ:” a kò a tí kọọ́ sínú òfin yín, ‘Èmí wípé, “Ẹ̀yin ni Ọlọ́run? 35 Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlórun lára ẹni tí Bíbélì ti jade (àti 'pé a kò lè yi Ìwé Mímọ́ padà), 36 Ǹjẹ́ ẹ̀yin ṣe lè sọ fún ẹni tí Baba yà sọ́tọ̀ tí Ó sì rán wá sí ayé wípé: 'Ìwọ́ ńsọ̀rọ̀ òdì', nítorí mo wípé, ' Èmi ni Ọmọ Ọlọ́run'? 37 Bí èmi kò bá ṣe àwọn iṣẹ́ Bàbá mi, ẹ máṣe gbà mí gbọ́. 38 Ṣùgbọ́n bí mo bá ńṣe wọ́n, bí ẹ kò tilẹ̀ gbà mi gbọ́, ẹ gba iṣẹ́ ọwó mi gbọ́ kí ẹ̀yin lè mọ̀ wípé Baba ńgbé inú mi, èmi sì ńgbé inú Baba. 39 Lẹ́ẹ̀kansíi, woń gbìyaǹjú láti mú Un, ṣùgbọ́n Ó bọ́, Ó sì lọ sí ilẹ̀ míràn. 40 Ó sì tuń lọ lẹ́ẹ̀kan síi kọjá ìlà oòrùn odò Jọ́dánì níbití Jòhánnù ńṣe ìtẹ̀bọmi tẹ́lẹ̀, Ó sì tẹ̀dó síbẹ̀. 41 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyaǹ sì tọ̀ Ọ́ wá, woń sì wípé: "Jòhánnù kò fi àmì hàn, Ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí ó sọ nípa ọkùnrin yìí ni ó jẹ́ òtítọ́. 42 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ níbẹ̀.