Orí Kọkànlá

1 Nísinsìnyí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Lásárù ṣàìsàn d'ójú iku. Ó wá láti Bétánì, abúlé tí M̀àriá àti àbúrò rẹ̀ Màtá ti wá. 2 Màríà, ẹni náà tì ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Lásárù ṣàìsàn ni ẹni tí ó fi òróró kun Jésù ní ẹsẹ̀ tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nùú. 3 Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ l'óbìnrin ránsẹ́ pe Jésù, wípé, "Olúwa, wòó, ẹni tí o fẹ́ràn gidigidi ńṣàísàn. 4 Nígbàtí Jésù gbọ́, Ó wípé. "Àìsàn yí kìí ṣe fún ikú. Ṣùgbọ́n, dípò bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run kí orúkọ ọmọ Ọlọ́run leè di ìmúṣògo". 5 Nísinsìnyí Jésù fẹ́ràn Màtá, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ óbìnrin àti Lásárù. 6 Nígbàtí Ó gbọ́ wípé Lásárù ńsàìsàn. Jésù dúró ní ọjọ́ mejì síi ní ìletò tí ó wà. 7 Lẹ́yìn èyí, Ó wí fuń àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, "Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Jùdíà lẹ́ẹ̀kan si." 8 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wípé, "Olùkọ́ni, nísinsìnyí àwọn Júù ńgbèrò láti sọ Ọ́ ní òkúta, O sì tún ńpadà lọ síbẹ̀ bí? 9 Jésù dáhùn, "Kìí waá ṣe wákàtí méjìlá ni ó wà nínú ọjọ́.? Bí ẹnikẹ́ní bá rìn ní ọ̀sán, ki yóò kọsẹ̀, nítorí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yì. 10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, bí ó bá rìn ní òkùnkùn, yóò ṣubú nítorí kò sí ìmọ̀lè lára rẹ̀. 11 Ó sọ àwọn ǹkan wọ̀nyí àti lẹ́yìn wọn, Ó sọ fún wọn wípé, "ọ̀rẹ́ẹ wa Lásárù ti sùn, ṣùgbọ́n mò ńlọ láti jíi nínú oorun". 12 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, "Olùwa, tí o ba jẹ wípe o sùn, yóò jí. 13 Báyìí Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n lérò wípé ó ńsọ nípa oorun ìsinmi. 14 Lẹ́yiǹ èyí Jésù sọ fuń wọn ní èdè ti yóò yè wọn, "Lásárù ti kú." 15 Jésù tún tẹ̀síwájú, "Inú mi dun, nítorí yín, wípé Èmi kò sí níbẹ̀ kí ẹ̀yin ki o le gbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀". 16 Tómáásì, tí á ńpè ní Dídímù, sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹlẹgbẹ́ rẹ, "ẹ jẹ́ kí a lọ kí àwa náà le kú pẹ̀lú rẹ̀." 17 Nígbàtí Jésù dé, O di mímọ̀ fún un wípé Lásárù tí wà ní ibojì fún ọjọ́ mẹ́rin. 18 Báyìí Bẹ́táánì sún mọ́ Jérúsálẹ́mù, ní ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ta. 19 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù wá sí ọ́dó Màtá àti Màríà, láti tù wọ́n nínú fún tí arákùnrin wọ́n. 20 Nígbàtí Màtá, gbọ́ wípé Jésù ḿbọ̀, ó lọ pàdé rẹ̀, ṣùgbọ́n Màríà jókòó nínú ilé. 21 Màtá sì sọ fún Jésù, "Olúwa, bí ìwọ bá ti wà níhinyìí, arákùnrin mí kì bá tí kú. 22 Síbẹ̀ báyìí, mo mọ wípé ohunkóhun tí ìwọ bá bèèrè lọ́wọ́ Olúwa, yóò fifún ọ". 23 Jésù sọ fuń un wípé, "Arákùnrin rẹ yóò tún jí dìde." 24 Màtá sì wí fún un pe, mo mọ wípé yóò jí dìde ní àjíǹde ìkẹyìn" 25 Jésù sì wí fuń un pé, "Èmi ní àjíǹde àti ìyè; ẹnikẹní tí ó bà gbá mí gbó, bí ó tílè kú, yóó yè 26 àti 'pé ẹni tí ó bà wà láàyè tí ósì gbà mí gbọ́ kì yóò kú. Ǹjé ẹ gbà èyí gbọ́"? 27 Ó wí fún un pe, "Lóòótọ́, Olúwa, mo gbàgbọ́ wípé ìwọ ni Krístì náà, ọmọ Ọlọ́run, tí ó ḿbọ̀ wá sí ayé." 28 Nígbàtí ó sì sọ èyí, ó jáde lọ o sì pe arábìnrin rẹ Màríà sí ìkọ̀kọ̀. Ó wípé, "Olùkọ́ni wa ní ibíyìí ó sì ńpè ọ" 29 Nígbà ti ó gbọ́ èyí, ó dìde kíá lọ s'ọ́dọ̀ọ Rẹ̀. 30 Báyìí, Jésù kò sì tí dé sí ìletò náà ṣùgbọ́n Ó sì wà nìbití Màtá ti lọ pàdé Rẹ̀. 31 Nígbàtí áwọn Júù tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilé tí wọn ńtù ún nínú, rí Màríà tí ó dìde lọ́gán lọ sí ìta, wọ́n tẹ̀lẹ, wọ̀n lèrò wípé ó ńlọ sí ibojì láti lọ sọkún. 32 Nígbàtí Màríà dé ibití Jésù wà tí ó rii, ó wólẹ̀ l'ẹ́sẹ̀ Ẹ Rẹ ó sì wípé, "Olúwa, bí ìwọ bá ti wà níhìń yìí, arákùnrin mí 'ìbá tí kú". 33 Nígbàtí Jésù ríi ti o ńsọkún, pẹ̀lú àwọn Júù tí wọ́n tẹ̀le ńsọkún pẹ̀lú rẹ̀; O káànú wọn, ọkàn Rẹ̀ sì bajẹ́. 34 Ó wípé, "Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ si?" Wọ́n sì wí fun un pe, "Olúwa, wá wòó 35 Jésù sọkún. 36 Àwọn Júú si wípé, "Wò Ó bí ó ti fẹ́ràn Lásárù to". 37 Ṣùgbọ́n àwọn míràn nínú wọn wípé, " Ṣé kò yẹ kí ọkùnrin yì í, ẹni tí o la'jú ọkùnrin afọju ṣe é kí ọkùnrin yìí máṣe kú"? 38 Síbẹ̀, Jésù tí o ní ìrora ọkàn nínú Rẹ̀, lọ sí ibojì. Ní àkókó yìí ori ihò ni a gbé okúta lé. 39 Jésù wípé, "ẹ gbé òkúta náà kúrò". Màtá, arábìnrin Lásárù, ẹni tí ó kú, sọ fún Jésù, "Olúwa, ní àkóko yìí ara rẹ̀ yóò ti máa díbàjé nítorítí ó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin". 40 Jésù sọ ọ́ fun, "Ǹjẹ́ Èmi kò sọ fún ọ wípé tí ìwọ ba gbàgbọ́, ìwọ yóò ri ògo Ọlórun?" 41 Wọ́n sì gbé òkúta náà kúrò, Jésù gbé ojú rẹ̀ sókè ó sì wípé, Bàbá, mo dúpẹ́ ní ọwọ rẹ nítorí pé Ò ńgbọ́ tèmi 42 Mo mọ̀ wípé Ò ńgbọ́ tèmi, ṣùgbọ́n nítorí àwọn èrò tí o dúró yì miká ní mo se sọ èyí, kí wọn lè gbàgbọ́ pè Ìwọ ni O rán mi". 43 Nígbàtí Ó si ṣọ èyí tán, Ó kígbe ní ohún rara, "Lásárù, jáde wá?" 44 Òkú ọkùnrin náà si jáde, pẹ̀lú ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ tì ó wà ní dídì pẹ̀lú aṣọ, a sì fí aṣọ di ní ojú. Jésu wí fuń wọn wípé, "Ẹ tú sílẹ kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ." 45 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ Màríà rí ohun tí Jésù ṣe, wọ́n si gbàgbọ́. 46 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì padà si ọ̀dọ àwọn Farisí wọ́n sì ṣọ ohun gbogbo tí Jésù ti ṣe. 47 Àwọn Olórí Àlúfà àti Farísí kó ara wọn jọ àti àwọn ìgbimọ̀ lápapọ̀ wọ́n si wípé, "Kí ni àwa yóò ṣe? Ọkùnrin yìí ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣé àmìn. 48 Tí a ba fi sílẹ̀ lí òhunnìkan báyìí, gbogbo ènìyàn yóò gbàgbọ́ nínú rẹ̀; àwọn Róòmù yóò wa lati gba ààyè àti Orílè-ede wá." 49 Báyìí, ọkùnrin kan nínú wọn tí à ńpè ní Káyáfà, tí ó jẹ́ olórí àlúfáà ní ọdún náà, sọ fún wọ́n 'pé, "Ẹ kò mọ ohunkóhun. 50 Ẹ kò rò wípé ó sàn fun yín kí ẹnìkan kí ó kú fún àwọn ènìyàn ju kí orílè-èdè kí ó ṣègbé". 51 Nísinsìnyí kó sọ èyí ni ọ̀rọ̀ ara rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, 'pé ó jẹ́ olóórí àlùúfàà ní ọdún náà, ó ti ṣọtẹ́lẹ̀ wípé kí Jésù kù fuń orílẹ̀-èdè; 52 kìi sii ṣe fún orílẹ̀-èdè nìkan, ṣùgbọ́n kí àwọn ọmọ Ọlọ́run tí wọn ti fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan. 53 Láti ọjọ́ náà ni wọ́n gbèrò bí wọn yóò ṣe pa Jésù. 54 Kò pẹ́ tí Jésù rìn ní gbangba láàríń àwọn Júù, ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí ìletò kan nítòsí aginjù ní ìlú kan tí à ǹpé ní Éfírémù. Níbẹ̀ ni ó dúró pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. 55 Báyìí, Àjọ Ìrékọjá àwọn Júù súnmọ́ etílé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì lọ sí Jerúsálẹ́mù láti orílè-èdè sí ibi àjọ ìrékọjá láti ya ara wọn sí mímọ́. 56 Wọ́n ńwá Jésù, wọn sì mbá ara wọn sọ̀rọ̀ bií wọn ṣe dúró ní téḿpílì, "Kí ni o rò? Ṣe kò ní wá sí àjọ̀dún?" 57 Báyìí àwọn Olórí Alúfáà àti Farisí pàṣẹ pé bí ẹnikẹ́ni bá mọ ibití Jésù wà, kí wọn sọ kí wọn baà lè mú Un.