Orí Kejìlá

1 Ọjọ́ kẹfà ṣíwájú Àjọ Ìrékọjá, Jésú wá sí Bẹ́tánì, níbití Lásárù tí Jésù jí dìde kúrò nínú òkú gbé wà. 2 Wọ́n sì ṣe àṣè oúnjẹ alẹ́ níbẹ̀, Màtá ń ṣe olùpín oúnjẹ náà, ṣùgbọ́n Lásárù jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó dùbúlẹ̀ ní tábìlì pẹ̀lú Jésù, . 3 Màríà sì mú nínú òróró olóòórùn iyebíye, ó fi kun ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi irun orí i rẹ̀ nuǹ nún. Inú ilé sì kún fún òórùn òróró ìkunra náà. 4 Júdásì Ìskáríótù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀, ẹni tí yóò fi í hàn, wípé, 5 È é ṣe tí a kò ta òróró yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó dénárì kí á sì fi fún àwọn aláìní. 6 Ó sì wí bẹ́ẹ̀, kìí ṣe wípé ó bìkítà fún àwọn aláìní, ṣùgbọ́n olè ni: àpò owó wà ní ọwọ́ rẹ̀, yóò sì jí nínú èyí tí ó wà níbẹ̀ 7 Jésù wípé, ''Ẹ gbàá láàyè, láti tọ́jú ohun tí ó ní fuń ọjọ́ ìsìnkú mi. 8 Àwon aláìní yóò máa wà láàrin yín ní ìgbà gbogbo. Ṣùgbọń ẹ kì yóò rí mi ní ìgbà gbogbo. 9 Báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn Júù gbọ́ wípé Jéṣù wà níbẹ́, wọ́n ṣì wá, kì í ṣe nítorí Jéṣù nìkan, ,ṣùgbọń láti rí Láṣárù ẹni tí Jéṣù jí dìde kúrò nínú àwọ̀n òkú lẹ́ẹ̀kan 10 Àwọn olórí àlùfáà ṣì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Láṣárù; 11 nítorí rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù ńjáde lọ àti pé wọ́n gbàgbọ́ nínú Jéṣù. 12 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyaǹ ṣì wá ṣí ibi àjọ̀duń ní ọjọ́ kejì. Nígbàtí wọń gbọ́ wípé Jésú ń rékọjá ṣí Jèrúṣálẹ́mù 13 wọ́n mú ẹ̀ka imọ̀ ọ̀pẹ láti pàdé rẹ̀ wọ́n ṣì kígbe síta, ''Òṣánà! Olùbùkuń ni ẹni tí ńbọ̀ ní orúkọ Olúwa ,Ọba àwọn Íṣrẹ́lì." 14 Jéṣù rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ kan, ó ṣì jókòó ṣí orí i rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọọ́ 15 "Má bẹ̀rù, ọdọ́mọbìnrin Ṣíónì; kíyèsi, Ọba yiń ńbọ̀, ó jòkó ní orí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́." 16 Fuń ìgbà àkọ́kọ́ àwọn n ǹkan wọǹyí kò yé àwọn ọmọ ẹ̀yiǹ Rẹ̀; ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jésù lógo, wọ́n rántí wípé ati kọ ǹkan wọ̀nyí nípa Rẹ̀ àti wípé ati ṣe awọń ǹkan wọǹyí ṣí I. 17 Nígbànáà ni ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ́ri ṣí i wípé wọń wà pẹ̀lú Rẹ̀ nígbàtí ó jí Láṣárù dìde kúrò láàrin àwọn òkú. 18 Nítorí ìdí èyí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe tọ̀ọ́ lọ ,nítorípé wọ́n ti gbọ́ wípé ó ti ṣe iṣẹ́ àmìn yí. 19 Àwọn Fariṣí ṣí ṣọ láàrin ara wọn, ''Wòó, kò ṣí ohun tí ẹ lè ṣe, ayé ti tỌ̀ Ọ́ lẹ́yiǹ'' 20 Àwọn Gíríkì kań ṣì wà láàrin àwọn tó ń gòkè lọ fún ìjọ́ṣìn ní ibi àjọ̀dún. 21 Àwọn eléyìí lọ sọ́dọ̀ Fílípì, ẹni tí ó wá láti Bẹtsáídà ní Gálílì, o sì bií wípé, ''Alàgbà, àwa fẹ́ rí Jéṣù. 22 Fílípì lọ, ó ṣì ṣọ fuń Ańdérù; Ańdérù lọ pẹ̀lú Fílípì, wọń ṣì ṣọ fuń Jéṣù. 23 Jéṣù ṣì dá wọn lóhuǹ ó wípé, ''Àkókò ti tó fuń ọmọ ènìyaǹ láti ṣe ara rẹ̀ lógo. 24 Lótitọ́,lótitọ́ ni mo ṣọ fuń un yiń, tí kò bá ṣe wípé irúgbìn ọkà wá ṣí orí ilẹ̀ tí ó ṣì kú, òhun yóò dá wà ní òhun nìkan; ṣùgbọ́n tí ó bá kú, yíò ṣo èṣo lọ́pọ̀lọpọ̀. 25 Ẹni tí ó fẹ́raǹ ẹ̀mí rẹ̀ yíò pàdánù rẹ̀, ṣùgbọń ẹni tí ó kórirá ẹ̀mi rẹ̀ ní ayé yìí yóò paá mọ́ títí ayérayé. 26 Tí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí jẹ́ kí ó tẹ̀lé mi; àti níbi tí èmi bá wà pẹ̀lú, níbẹ̀ ni àwọn ìrańṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú. Tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣìnmí, Baba yóò bu ọlá fuń un. 27 Nísinsìyí ọkaǹ mi pòrurù àti kińni èmi yóò ṣọ? 'Bàbá, gbàmí kúrò nínú wákàtí yí? Ṣùgbọ́n nítorí ìdí èyí mo wá fún wákàtí yìí 28 Bàbá, fi ògo fún orúkọ Rẹ. Ohùn kan ṣì wá láti ọ̀run tí ó wípé ''Moti ṣe é lógo èmi yíò ṣì tuń ṣe ní ògo lẹ́ẹ̀kan ṣi i. 29 Ọ̀pọ̀ ènìyaǹ tí ó jókòó pẹ̀lú Rẹ̀ gbọ́ èyí wọ́n ṣì wípé ó tì ṣań àrá.Àwọn míraǹ wípé ''Áńgẹ́lì ti báa ṣọ̀rọ̀." 30 Jésù dáhuǹ ó ṣì wípé, ''Ohùn yí kò wà fún mi, ṣùgbọ́n fuń un yiń 31 Àkókò ti tó fún ìdájọ́ ayé: Báyí a ó lé àwọn aláṣẹ ayé yí kúrò. 32 Nígbàtí a bá gbé mi sókè kúrò nínú ayé, èmi yóò mú àwọn ènìyàn ṣuń mọ̀ mi . 33 Ó ṣọ eléyì í láti jẹ́ kí ó di mímọ̀ irú ikú tí òun yóò kú 34 Àwọn èrò ṣì dáa lóhuǹ, ''A ti gbọ́ọ nínú òfin wípé Jéṣù yóò wà títí. Èéṣe tí ó fi wípé, A ó gba ọmọ ènìyàn sókè bí?,Tani ọmọ ènìyàn náà? 35 Nígbànáà ni Jésù ṣọ fuń wọn ''ìmọ́lẹ̀ yóò ṣì tuń wà pẹ̀lú yiń fuń iye ìgbà díẹ̀,. Ẹ riǹ nígbàtí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí òkuǹkuǹ kì yóò fi borí yiń. Ẹni tí ó rìn nínú òkuǹkuǹ kò mọ ibi tí ó ń lọ 36 Nígbàtí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gbàgbọ́ nínú ìmọ́lẹ̀ kí ẹ̀yin kí ó le jẹ ọmọ ìmọ́lẹ̀'' Jésù ṣọ nkàn wọǹyí ó ṣì fi ara rẹ̀ pamọ́ kúró lọ́dọ̀ wọn. 37 Bí o ti lẹ̀ ṣe pé Jéṣù ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ àmiǹ ní ojú wọn, ṣíbẹ̀ wọn kò gbàgbọ́ nínú Rẹ̀. 38 Kí á le mú ọ̀rọ̀ Àìṣáyà wòólì ṣẹ, nínú èyí tí ó wípé: "Olúwa àwọ̀n wo ni ó ti gba ìròyiǹ wa gbọ́, àti àwọn wo sì ni ẹni tí a fi apá Olúwa hàn"? 39 Fuń idí èyí wọn kò le gbàgbọ́, nítorí Àíṣáyà náà ṣọ, 40 ''Ó ti fọ́ wọn ní ojú, a ṣì ti mú wọn ní ọkàn le; bíbẹ̀ẹ̀kọ́ wọn yóò ri pẹ̀lú ojú wọn, pẹ̀lú ọkaǹ wọn yóò ṣì yé wọn, wọn yóò yí padà, èmi yóò ṣì wò wọń saǹ.'' 41 Àíṣáyà ṣọ àwọn ǹkan wọǹyí nítori wípé ó rí ògo Jéṣù ó ṣì ṣọ nípa Rẹ̀. 42 Ṣùgbọ́n láìkàwọ́n kún, ọpọ̀lọpọ̀ nínú àwọn aláṣẹ gbàgbọ́ nínú Jéṣù; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Fariṣí, wọn kò fi í hàn kí á má baà lé wọn jáde kúrò nínú Ṣínágọ́gù. 43 Wọń ní fẹ́ sí ìyiǹ tí ó ti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá ju ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lọ. 44 Jéṣù kígbe ṣíta ó wípé, ''Ẹni tí ó gbà mi gbọ́ kò gbàgbọ́ ní inú mi nìkan ṣoṣo ṣùgbọń nínú ẹni tí ó rań mi pẹ̀lú, 45 àti pẹ̀lú wípé ẹni tí ó ń rími rí ẹni tí ó rań mi. 46 Mo ti wá gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ṣí inú ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ kí ó má ṣe wà nínú òkuǹkuǹ. 47 Tí ẹnikẹ́ni bá gbọ̀ ọ̀rọ̀ mi tí kò ṣì pa wọń mọ́, èmi kò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ;Nítorí wípé èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, ṣùgbọ́n láti gba aráyé là. 48 Ẹni tí ó kọ̀ mí tí kò ṣì gba ọ̀rọ̀ mi, ni ẹni tí ó ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí mo ti ṣọ yí ó ṣe ìdájọ ara rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyiǹ. 49 Nítorí èmi kò ṣọ ọ̀rọ̀ ara mi, ṣùgbọń Baba tí ó rań mi, tí ó sì ti fuń mi ní àṣẹ nípa ohun tí èmi yóò ṣọ àti bí èmi yóò ti ṣọọ́. 50 Mo mọ̀ wípé àìnípẹ̀kun ni àṣẹ rẹ̀, nítorí náà ni mo ṣe wípé - gẹ́gẹ́ bí Baba ti ṣọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni mo ń ṣọọ́.''