1 Nísinsìnyí kí àsè àjọ ìrékọjá tó dé. Jésù mọ̀ wípé àkókò rẹ titó láti fi ayé yìí sílẹ̀ kí ó sì kọjá lọ sí ọ̀dọ̀ Baba. Bí Ó ṣe fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà nínú ayé, Ó fẹ́ wọn títí dé òpin, 2 Nísinsìnyí èsù ti fi sí ọkàn Júdásì Ìskárọ́tù ọmọ Símónì, láti fi Jésù hàn. 3 Ò mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ Òun àti wípé bí Ó ti wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí Ó sì ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 4 Ó dìde nínú oúnjẹ alẹ́ Ó sì bọ́ asọ ìwọ̀lékè Rẹ̀. Nígbà náà ni Ó mú aṣọ ìnura kan, ó dàá bo ara rẹ̀. 5 Nígbà náà ni Ó da omi sínú agbada Ó sì bẹ̀rẹ̀ síí wẹ̀ ẹsẹ̀ àwọn ọmọẹ̀yìn náà Ó sì nùn ún pẹ̀lú asọ ìnura tó dà bo ara rẹ̀. 6 Ò wá sọ́dọ̀ Símónì Pétérù, Pétérù sì sọ fún un pé, "Olúwa, ṣé ìwọ yóò wẹ ẹsẹ̀ mi nù?" 7 Jésù dáhùn, Ó sì wí fùn un pé, "Ohun tí Èmi ń se kò yé ọ nísinsìyí, ṣùgbọ́n èyí yóò yé ọ tó bá yá." 8 Pétérù sọ fún un pé, "O kò ní wẹ ẹsẹ̀ mi láí. "Jésù dáa lóhùn pe, "Tí Èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín pẹ̀lúù Mi." 9 Símọ́nì Pétéru sọ fún Un pé, "Olúwa, máse wẹ ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí ì mi pẹ̀lú." 10 Jésù sọ fun pé, "Ẹni tí a ti wẹ̀ kò nílò àtúwẹ̀, bíkòse pé kí á wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n ó mọ́ pátápátá; ìwọ mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn." 11 (Nítorí tí Jésù mọ ẹni tí yóò fi í hàn, ìdí nì yí tí ó fi wípé, "Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.") 12 Nígbàtí Jésù ti wẹ ẹsẹ̀ wọn, tí ó sì ti mú ẹ̀wù Rẹ̀, tí Ó sì tún jókò, Ó wí fún wọn pé, "Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ ohun tí mo ti ṣe fún un yín? 13 Ẹ pè mí ní 'Olùkóni' àti 'Olúwa,' bí ó ti rí ni ẹ̀yín ń wí, nítorí pé bẹ́ẹ̀ni Èmi jẹ́. 14 Bí Èmi tí Ó jẹ́, Olúwa náà àti Olùkóni náà, bá ti wẹ ẹsẹ̀ yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú wẹ ẹsẹ̀ ara yín. 15 Nítorí tí mo ti fún un yín ní àpẹrẹ, kí ẹ̀yín pẹ̀lú náà le ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún un yín. 16 Lootọ, lootọ, ni mo wí fun yín, ọmọ ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ; bákan náà ni ẹni tí a rán níṣẹ́ kò ju ẹni tí ó rán an lọ. 17 Tí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí; alábùnkúnfún ni yín, tí ẹ̀yin bá ṣe wọ́n. 18 Èmi kò wí nípa gbogbo yín; mo mọ àwọn tí mo ti yàn - ṣùgbọ́n èyí ri bẹ́ẹ̀, láti le mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ: 'Ẹnití ń bá mi jẹun pọ̀, gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè lòdì sí mi. 19 Mo sọ èyí fun yín nísinsìnyi kí ó tó ṣẹlẹ̀ pé tí ó bá ṣẹlẹ̀, ẹ ó le è gbàgbọ́ wípé Èmi ni. 20 Lótìítọ́, lótìítọ́, ni mo wí fun yín, ẹni tí ó bá gba ẹniyòówù tí mo rán, ó gbà mí; àti ẹni tó bá gbà mi, gba ẹni tó rán mi. 21 Nígbà tí Jésù wí èyí, ọkàn Rẹ̀ dàrú. Ó jẹri si, Ó sì wípé; "Lotìítọ́, lotìítọ́, ni Mo wí fun yín pé ẹnìkan nínú yín yóò dàmí." 22 Àwọn ọmọẹ̀yìn wo ara wọn, ó yà wọ́n lẹ́nu ẹni tí ó ń wí nípa rẹ̀. 23 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ẹnití Jésù fẹràn, fi ara tì ni ẹ̀bá tábìlì tó dojúkọ Jésù. 24 Símọ́nì Pétérù fi ara sọ̀rọ̀ fún ọmọ ẹ̀yìn yí wípé, "Béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ ẹnití ó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀." 25 Nígbà náà ni ó fẹ̀hìn ti ẹ̀gbẹ́ Jésù padà ó sí wí fún un pé, "Olúwa, tani í se?" 26 Nígbà náà ni Jésù dáhùn, " Òun ni ẹniti Èmi yóò bu búrẹ́dì fun tí N ó sì fi fún un." Nígbàtí Ó ti bu búrẹ́dì náà, Ó fi fún Júdásì ọmọ Símónì Ìsìkárọ́tù. 27 Lẹ́yìn jíjẹ búrẹ́dì; Èṣù wọnú rẹ̀. Nígbà náà ni Jésù sọ fún un pé, "Ohun tí ìwọ ń ṣe, ṣeé kánkáń." 28 Nísinsìnyí kò sí ẹnìkan tó fara ti tábìlì tí ó mọ ìdí tí Ó fi sọ èyí sí i. 29 Àwọn kan rò wípé, nítorí ti Júdásì jẹ́ akápo, Jésù sọ fún un pé, "Ra ohun tí a nílò fun àpèjẹ náà," tàbí kí ó le fi nǹkan fún àwọn tálákà. 30 Lẹ́yìn tí Júdásì gba búrẹ́dì, ó jáde lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Alẹ́ ti lẹ́. 31 Nígbà tí Júdásì ti lọ, Jésù wípé, "Nísinsìnyí a yin Ọmọ Ènìyàn náà lógo, àti wípé Ọlọ́run di àyìnlógo nínú rẹ̀. 32 Ọlọ́run yóò ṣeé lógo nínú ara Rẹ́, àti wípé, yóò sì ṣeé lógo lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 33 Ẹ̀yin ọmọdé, Èmi wà pẹ̀lú u yín síbẹ̀ fún àkókò díẹ̀. Ẹ ó wá mí, àti wípé, bí mo ti sọ fún àwọn Júù náà pe, 'Níbi tí mo ń lọ, ẹ̀yin kò le wá.' Nísinsìnyí mo tún sọ èyí fún yín. 34 "Òfin titun ni mo ń fi fún yín, wípé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; bí Mo ti fẹ́ràn yín, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni kí ẹ se fẹ́ràn ara yin. 35 Nípa èyi gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn mi ni ẹ̀yin ń ṣe, tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ara yín." 36 Símónì Pétérù sọ fun pé, "Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?" Jésù dáhùn, "Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kò le tẹ̀lé mi lọ nísinsìnyí, ṣùgbọ́n ìwọ ó tẹ̀lé mi lọ nígbà tó bá yá." 37 Pétérù sọ fún un pé, "Olúwa, kíló dé tí èmi kò le tẹ̀lé ọ nísinsìnyi? Èmi yó fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ fún ọ." 38 Jésù dáhùn, "Sé ìwọ yóò fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ fún mi? Lótìítọ́, lótìítọ́, ni mo sọ fún ọ, àkùkọ kò ní tí ì kọ, kí ìwọ tó ṣẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.