1 Ẹ máse jẹ́ kí ọkán nyín kí ó dàrú. Ẹ̀yin ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹ̀lú. 2 Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn yààrá ni ó wà níbẹ̀. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, Èmi ìbá ti sọ́ fun yín, nítorí Èmi nlọ láti pèsè àyè sílẹ̀ fun yin. 3 Bí Èmi bá sì lọ láti pèsè àyé sílẹ̀ fún yín, èmi yóò padá wá láti gbà yiń sí ọ̀dọ̀ èmi tìkalára mi. 4 Ẹ̀yin mọ́ ọ̀nà sí ibi tí Èmí ń lọ. 5 Tọ́másì sì wí fún Jésù pè, "Olúwa, àwa ko mọ́ ibi tí ìwọ nlọ, báwo ni àwa ó se mọ ọ̀ná náà?" 6 Jésù sí wí fún un pé, "Èmi ni ọ̀nà náà, òtítọ́ náà àti ìyè náà; kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wà sọ́dọ̀ Baba bíkóse nípasẹ̀ mi. 7 Bí o bá ṣe pé ìwọ mọ̀ mí, ìwọ ìba si ti mọ Baba mi pẹ̀lú. Láti ìsisìnyí lọ ìwọ mọ̀ Ọ́n àti pé ìwọ sì ti rí I. 8 Fílípì sọ fún Jésù pé, "Olúwa, fi Baba hàn wá, ó sì tó fún wa. 9 "Jésù sí wi fún pé, "Èmi ti wà pẹ̀lú yín fún ọjọ́ pípẹ́ sibẹ ìwọ kò si mọ̀ mí, Filipi? Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti rí mi, ó ti ri Baba. Báwo ni o ṣe le sọ wípé, fi Baba hàn wá? 10 Sé ìwọ ko gbàgbọ́ pe Èmi wà nínú Baba àti pé Babá wà nínù mi? Àwọn ọ̀rọ̀ náà tí mo sọ fún yín Emi kò sọọ́ láti inú àṣẹ Èmi tìkalára mi wá, ṣùgbọ́n Bàbá tí Ó ń gbé nínú mi ni Ó ńṣiṣé Rẹ̀. 11 Gbà mí gbọ́ wípé Èmí wá ninu Baba, àti Bàbá náà wà nínú mi, tàbí kí o gbàgbọ́ nítorí awọn iṣẹ́ náà tìkalára wọn. 12 Lóòtọ́ọ́, lóòtọ́ọ́, ni mo wí fún ọ, ẹnití o bá gbà mí gbọ́ yóò ṣe àwọn iṣẹ́ náà ti Èmi se, yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ nítorípé Èmi ń lọ sí ọ́dọ̀ Baba. 13 Ohun kóhun ti ìwọ bá bèèrè ni orúkọ mi, Èmi yóò seé kí a le yin Baba lógo nínú Ọmọ. 14 Bí ìwọ ba bèèrè ohunkóhun lọ́wọ́ mi ní orúkọ mi, Èmi yóò ṣé é. 15 Bí ìwọ bá fẹ́ràn mi, ìwọ yóò pa àwọn òfin mi mọ́, 16 Èmi yóò sì gbàdúrà si Baba, Òun yóò si fún un yín ní Olùtùnú míraǹ kí Òun kí Ó lè máa wà pẹ̀lú yín títí láí 17 ti Í ṣe Ẹ̀mí Òtítọ́. Aráyé kò le gbà Á nítorípé wọn kò rí I tàbí mọ̀ Ọ́n. Ṣùgbọ́n ẹ̀yín mọ̀ Ọ́n, nítorì Ó ń gbé pẹ̀lú yín Ó si wà nínú yín. 18 Èmi kò ni fi yìn sílẹ̀ ní ẹ̀yin nìkan; Èmi yóò padà tọ̀ yín wá. 19 Síbẹ̀ ni àkókò kúkúrú aráyé kò ní rí mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ri mi. Nítorípé Èmi ye, ẹ̀yin o ye pẹ̀lú. 20 Ní ọjọ́ náà ẹ̀yin o mọ̀ wípé Èmi wa nínú Baba mi, àti pé ẹ̀yin wà nínú mi, àti Èmi nínú yín. 21 Ẹnití o ni àwọn òfin mi tí ó sì pa wón mọ́, òun ni ẹnití o fẹ́ mi, àti ẹnití o fẹ́ mi ni Baba mi yóò fẹ́, Èmi yoo si fẹ́ẹ, Èmi yoo si fi ara mi hàn án. 22 Júdásì (kì íse Ìskáríótù) sọ fún Jésù wípé, "Olúwa, kíni ìdí tí ìwọ óò fifi ara Rẹ hàn wá tí kìí si i ṣe fún aráyé. 23 Jésù dáhùn Ó si wi fún un pé, "Bi ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Baba mi yóò fẹ́ẹ, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, àwa ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀ 24 Ẹnití kò bá fẹ́ mi, kò pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́. Ọ̀rọ̀ tí ẹ gbọ́ kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Baba náà tí Ó rán mi. 25 Mo ti sọ àwọn ǹkan wọ̀nyí fún yín, nígbàtì mò ń bá yin gbé. 26 Ṣùgbọ́n, Olùtùnú náà, tí Í ṣe Ẹ̀mi Mímọ́ náà, Ẹnití Baba yoo rán ní orúkọ mi, yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán an yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún un yín. 27 Mo fi àlááfìa sílẹ̀ fún yín; Àlááfìa mi ní mo fún yín. Èmi kò fi í fún yín bí aráyé ti í fí fún ni. Máse jẹ́ ki ọkàn rẹ ki o dàrú, má sì ṣe bẹ̀rù. 28 Ẹ̀yin gbọ́ pé mo ṣọ fún un yín, 'Èmi nlọ kúrò, èmi yóò sì padà tọ̀ yín wá.' Bí ẹ̀yin ba fẹ mi, ẹ̀yin yóò yọ̀ nítorípé Èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba tóbi jù mí lọ. 29 Nísinsìnyí Èmi ti sọ fún un yín kí ó tóó ṣẹlẹ̀ ki ẹ̀yin, nígbàtì o ba ṣẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò gbàgbọ́ 30 Èmi ko ni sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ pẹlu yin mọ́, nítorí aláṣẹ ayé yìí ń bọ́ wá. Kò sì ní agbára lóríì mi, 31 ṣùgbọ́n ki aráyé kí o le mọ pé Èmi fẹ́ Baba, Èmi nse gẹ́gẹ́ bi Baba ti paá lásẹ fún mi. Ẹ jẹ ki a dìde ki a lọ kúrò ní ibíyìí. 30 Èmi ko ni sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ pẹlu yin mọ́, nítorí aláṣẹ ayé yìí ń bọ́ wá. Kò sì ní agbára lóríì mi, 31 ṣùgbọ́n ki aráyé kí o le mọ pé Èmi fẹ́ Baba, Èmi nse gẹ́gẹ́ bi Baba ti paá lásẹ fún mi. Ẹ jẹ ki a dìde ki a lọ kúrò ní ibíyìí.