1 Èmi ni àjàrà tòótọ́ọ́, Bàbá mì si nì Olùsọ́gbà. 2 Òun mú kùró gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí ko ṣo èso, Òun a si má a wẹ gbogbo ẹ̀ka ti n so èso kí o le máa so èṣo sii. 3 Ẹ̀yin ti di mímọ́ nípa ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún un yín. 4 Ẹ máa gbé inú mi àti èmi nínú n yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kàn ko ti le so èso fun ara rè àfi tí o ba dúró ní ara àjàrà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gé ni ẹ̀yin, àfi tí ẹ ba n gbé inú mi. 5 Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin sì ni ẹ̀ka. Ẹnití o ń gbé inú mi ati ti èmi si ń gbé inú rẹ̀, yóò so èso púpọ̀, nítorí láì sí mi ẹ̀yin ko le se ohun kóhun. 6 Bí ẹnikẹ̀ni kò bá gbé nínú mi, a ó sọ̀ ọ nù bi ẹ̀ka tí yóò si gbẹ, a ó sì ko irú àwon ẹ̀ka bẹẹ jọ a ó sì sọ wọ́n sínú iná. 7 Bí ẹ̀yin ba n gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá si n gbé inú yin, ẹ bèèrè ohun kóhun ti ẹ̀yin ba fẹ́, a ó sì ṣe é fún un yín. 8 Nínú èyí ni á ò ṣe Bàbá Mì lógo, pé kí ẹ̀yin kí ó so èso púpọ̀, kí ẹ̀yin kí o lè fihàn pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin íṣe. 9 Bí Bàbá sì ti fẹ́ mi, Èmi fẹ́ ẹ yín pẹ̀lú. Ẹ dúró nínú ìfẹ́ Mi. 10 Bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mì mọ, ẹ̀yin yóò si dúró nínú ìfẹ́ mi, gẹ́gẹ́bí Èmi ti pa òfin Bàba mi mọ́ tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀ 11 Èmi ti sọ àwon ǹkan wọ̀nyí fún n yín kí ayọ̀ mi ki o le wà nínú yín àti kí ayọ̀ yín kí o le pé. 12 Èyí ni òfin mi, pé ki ẹ̀yin ki o ni ìfẹ́ ara yín gẹ́gẹ́ bi Èmi ti fẹ́ẹ yìn. 13 Ẹnìkan kò ní ìfẹ́ tí ó ga ju èyí lọ, pé kí ó fi ayé rẹ lélẹ̀ fun àwọn ọ̀rẹ́ ẹ Rẹ̀ 14 Ẹ̀yin jẹ́ ọ̀rẹ́ mi bí ẹ̀yin bá se àwọn ohun tí mo pa lásẹ fún un yín. 15 Èmi kò pè yín ní ẹrú mọ́, nítorípé ẹrú kò mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń se. Èmi pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorípé ohun gbogbo tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Bàbá mi, ni mo jẹ́ kí ẹ mọ̀. 16 Ẹ̀yin kọ́ ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì yàn yín kí ẹ̀yin kí o lè lọ láti so èso, kì èso yín kí o lè dúró. Kí ohun kóhun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, Òun yóò fi fún un yín. 17 Àwọn ǹkan wọ̀nyí ni mo pa láse fún un yín, kí ẹ̀yin kí o ní ìfẹ́ ara yín. 18 Bí aráyé bá kóríra yín, ẹ mọ eyi pe o kóríra mi kí ó tó kóríra yín. 19 Bí ẹ̀yin bá jẹ́ ti ayé, aráyé yóò fẹ́ràn yín gẹ́gẹ́bìi tirẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorípé ẹ̀yin kì ísé ti ayé àti pé èmi yàn yín láti inú ayé wá, nítorí èyí àwọn aráyé kóríra yín. 20 Ẹ rántí ọ̀rọ̀ náà tí mo sọ fún un yín, 'Ìrásẹ́ kan kò ga ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.' Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí mi, wọn yó ṣe inúnibíni síi yín pẹ̀lú; bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yó pa ọ̀rọ̀ yín mọ́ pẹ̀lú. 21 Wọn yó ṣe àwọn nǹkan wònyí síi yín nítorí orúkọ mi, nítorípé wọn kò mọ ẹni náà tí ó rán mi. 22 Bí Èmi kò bá wá láti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kò bá tí dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọn kò ní àwáwí fún ẹ̀ṣẹ́ wọn. 23 Ẹnití ó bá kóríra mi, kóríra Bàbá mi pẹ̀lú. 24 Bí èmi kò bá ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹnìkan kò ṣe rí ní ààrin wọn, wọn kò ní ní ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọn ti rí, wọ́n sì kóríra èmi àti Bàbá mi. 25 Ṣùgbọ́n èyí ṣẹlẹ̀ kí á le mú ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú òfin ṣẹ, 'Wọ́n kóríra mi láì ní ìdí.' 26 Nígbàtí Olùtùnú náà, tí Èmi yóò rán síi yín láti ọ̀dọ̀ Bàbá, èyí tí se, Ẹ̀mí Òtítọ́ náà, tí o jáde wa láti ọ̀dọ̀ Bàbá bá dé, òun yóò Jẹ́ẹ̀rí nípa mi. 27 Ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń Jẹ́ẹ̀rí si nítorípé ẹ̀yin ti wà pẹ̀lú mi láti ìbẹ̀rẹ̀ náà.