1 Mò tí sọ́ awọ́n nkán wọ̀nyí fún yín kí ẹyín lè mú ẹsẹ̀ dúró. 2 Wọ́n ó jù yín jàde kúrò nínú sìnágọ́gú. Ṣùgbọ́n àkókò ná ńbọ̀ nígbà tí gbogbo ẹní tí ó bá n pa yín yóò rò wípé àwọn ń jọ́sìn fún Ọlọ́run. 3 Wọn ó ṣe gbogbo èyí nítorí wọn kò ì tíì mọ Bàbá tàbí èmi. Mo sọ́ àwọn nkán wọ̀n yí fún yìn, kí ẹyín lé rántí wípé mo sọ́ fún yín nígbà tí akókò tí wọ́n ó sẹlẹ̀ bá dé. 4 Èmi kó sọ àwọn ǹkàn wọ́nyì fún yín ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, nítorí èmi wá pẹ́lù yín. 5 Sùgbọ́n ní báyìí èmi ń lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ránmi, síbẹ̀ kòsí lára yín tí ó bimí pé, níbo ni o ńlọ? 6 Súgbọ̀n nítorí mo sọ ǹkan yí fún un yín, ìbànújẹ́ kún ọkàn yín. 7 Sùgbọ́n lótìítọ́ ni mo wí fún yín wípé, ó dára fún yín kí èmi kí ó lọ. Nítorí bí èmi kòbá lọ, Olùtùnú kò ní tọ̀ yín wá, ṣùgbọ́n bí èmi bá lọ, èmi yó rán an síi yín. 8 Nígbà tí ó bá dé, Olùtùnú náà yó fi àṣìṣe aráyé hàn wọ́n nípa ẹ̀ṣẹ̀, nípa òdodo, atí ìdájọ́- 9 nípa ẹ̀ṣẹ̀, nítorí wọ́n kò gbàgbọ́ nínú mi; 10 nípa òdodo, nítorí èmi ń lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá, ẹ kò sì ní rí mi mọ́ ; 11 àti nípa ìdájọ́, nítorí a ti dá aláṣẹ lẹ́jọ́. 12 Mo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti sọ fún un yín, ṣùgbọ́n kì yóò yé e yín báyìí. 13 Ṣùgbọ́n nígbà tí Òun, Ẹ̀mí òtítọ́, bádé, Òun yóò ṣé atọ́nà yín sí gbogbo òtítọ́, nítori ohún kí yóò sọ́ nìpá tí ará rẹ́. Ṣùgbọ́n, Òún yóò sọ ohun tí ó bá gbọ́, Òun yóò sì sọ fún yín àwọn ohun tí ó ń bọ̀. 14 Òun yóò yìn mí lógo, nítorí Òun yóò mú nínú ohun tí ṣe tèmi Òun yóò sì sọ fún yín. 15 Tèmi ni ohun gbogbo tí Bàbá ní. Nítórináà, èmi sọ wípé Ẹmí Mímọ́ yóò mú lára ohun tí ṣe tèmi Oun yóò sí sọ fún yín. 16 Láìpẹ́ ẹ̀yin kì yóò sì rími mọ́, àti lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ ẹ̀yin yóò sì tún rími. 17 Nígbánà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ láàrin ara wọn, "Kini èyí ti O ń sọ fún wa, 'Láìpẹ́ ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́ àti lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ ẹ̀yin yóò rí mi,' àti, 'Nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Bàbá' ?" 18 Nítorínáà wọ́n sọ pé, " Kíni èyí tí Òun ń sọ, 'Láìpẹ́' ? Àwa kò mọ̀ ohun tí Ó ń sọ́." 19 Jésù rí i wípé wọ́n fẹ́ bi Òun ní ìbéèrè, Ó sì sọ fún wọn pé, " Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń bi ara yín léèrè, ohun tí mo ní lọkàn nígbà tí mo wípé, 'Ní ìgbà díẹ̀ ẹ̀yin kì yóò rí mi, nígbà díẹ̀, ẹ̀yin yóò tún rí mi' ? 20 Lóòtítọ́, lóòtítọ́ ni mó wí fún yín wípé, ẹ̀yin yóò sunkún ẹ ó sì ké ìrora, ṣùgbọ́n àwọn tí ó jẹ́ ti ayé yóò kún fún ayọ̀. Ẹ̀yin yóò la ìpọ́njú ńlá kọjá, ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ yín yóò di ayọ̀. 21 Èyí dàbí obìnrin tí ó ń la ìrora ìrọbí kọ́já. Lẹ́yìn tí ó bá bí ọmọ náà tán, yóò gbàgbé ìrora rẹ̀ nítori a bi ọmọ náà sí ayé. 22 Ǹjẹ ẹyin ní ìbìnújẹ́ nísisìnyí, ṣùgbọ́n Èmi yóò tún rí i yín, ọkàn yín yóò sì ní ayọ̀, kì yóò sí ẹni tí yóò le gba ayọ̀ yín ní ọwọ́ yín. 23 Ní ọjọ́ náà, ẹ kò ní ní ìdí láti béèrè ohunkóhun ní ọwọ́ mi. lóòtítọ́, lóòtítọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní ọwọ́ Bàbá ní orúkọ̀ mi, Òun yóò fi fún yín. 24 Títí di àkókò yì ẹ̀yin kó í tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ̀ mi. Ẹ béèrè, ẹ̀yin yóò sì rí gbà kí ayọ̀ yín lè di kíkún. 25 Mo pa àwọn ǹkan wọ̀nyí ní òwe fún yín, ṣùgbọ́n wákàtí náà ńbọ̀ tí èmi kò ní fi òwe báa yín sọ ọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ fún yín ní kedere nípa Bàbá. 26 Nì ọjọ́ ná ẹ̀yin yóò béeré ni orúkọ̀ mí èmi kò sọ fún yín pé èmi yóò gbàdúrà sí Bàbá fún yín, 27 nítorí Bàbá fún rarẹ̀ fẹ́ràn yín nítorí pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi àti wípé ẹ̀yin gbàgbọ́ pé èmi wá láti ọ̀dọ̀ Bàbá. 28 Èmi wá láti ọ̀dọ̀ Bàbá, èmi sì ti wá sínú ayé. Àti wípé, èmi ń fi ayé yìí sílẹ̀, èmi sì ńlọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá." 29 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wípé, wòó, ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ tí ó yé wa báyìí tí kìí ṣe òwe. 30 Nísisìnyí àwa mọ̀ wípé ìwọ mọ ohun gbogbo, ìwọ ò sì nílò láti béèrè lọ́wọ́ ẹnìkankan. Nítorí èyí, àwa gbàgbọ́ wípé ìwọ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run." 31 Jésù dáwọn lóhùn pé, "Ṣé ẹ̀yin gbàgbọ́ nísisìnyí? 32 Wóó, wákàtí náà ḿbọ̀ nígbàtí wọn o tú yín ká, olúkúlùkù sí ilè ara rẹ̀, ẹ̀yin ó sì fi èmi nìkan sílẹẹ̀. Síbẹ̀ kìí ṣe èmi nìkan nítorí Bàbá mi wà pẹ̀lú mi. 33 Mo ti sọ àwọn ǹkan wọ̀nyí fún yín kí ẹ̀yin le ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé ẹ̀yin o rí ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ ní ìgboyà: Mo tí ṣẹ́gun ayé."