1 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìníní ọ̀sẹ̀, nígbàtí ilẹ̀ kò tí mọ́ tán, Mary Magdalene wá sí ibi ibojì ósì ri pé a ti yí òkuta nâ kúrò lẹ́nu ibojì. 2 Nítorìnâ ó sáré lọ si ọ̀dọ̀ Simoni Peteru àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Jesu nifệ sí, ósì wí fún wọn pé, "Wọ́n ti yí òkuta kúrò lẹ́nu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ẹ si." 3 Nígbànâ ni Peteru àti àwọn ọmọ ẹ̀yin yókù sì jáde, wọ́n sì lọ sí ibi ibojì nâ. 4 Gbogbo wọ́n sì sáré papọ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yọ̌kù sì sáré kọjá Peteru wọ́n sì dé ibojì sájú rẹ̀. 5 Ósì dúró, írí asọ tí afi sée ni ibẹ̀, ṣùgbọ́n o n kò wọ inú rẹ̀. 6 Nígbànǎ ni Simoni Peteru dé ó sì wo inú ibojì nâ lọ. Ó rí aso tí a fi wée ní ibẹ́ 7 àti asọ tí ó wà níbi orí rẹ́. Kò sí pẹ̀lú aso tí a fi wée ṣùgbọ́n ó wà fún farẹ̀. 8 Lẹ́yìn nâ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yókù, àti ẹni tí ó kọ́kọ́ dé ibi ibojì, pẹ̀lú wọlé, ó sì ríi ó sì gbàgbọ́. 9 Nítorí títí di àsìkò nâ wọn kò mọ̀ pé ìwé mímọ́ ti sọ pé a ó jí dìde kúrò nínú òkú. 10 Nítorínâ àwọn ọmọ ẹ̀yìn padà sí ilé. 11 Ṣùgbọ́n Mary dúró ní etí ibojì ó n sọkún. Bí ó sì ti n sọkún, Ó wo inú ibojì lọ. 12 Ó rí angeli méjì tí wọ́n wọ asọ funfun wọ́n sì jôkó, ọ̀kan níbi orí èkejì níbi ẹsè níbi tí a gbe tẹ́ Jesu sí. 13 Wọ́n wí fún pé, "Arábìnrin, kílódé tí ìwọ fi n sọkún?'' Ó sì wí fún wọn pé, "Nítorí wọ́n gbé Olúwa mi lọ, èmi kò sì mo ibi tí a gbé tẹ sí." 14 Nígbàtí ó sí rí èyì, ó yí padà ó sì rí Jesu tí ó dúró, ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé Jesu ni. 15 Jesu sì wí fún pé, "Arábìnrin, kílódé tí ìwọ fi n sọkún?" Ó rò pé asọ́gbà ni, nítoríná ó dálóhùn, "Arákùnrin, tí ìwọ bá ti gbée kúrò, sọ fún mi ibi tí ìwọ gbé tẹ sí, èmi ó sì gbe kúrò. 16 Jesu sì wí fún pé. " Maria." Ó sì yí padà, ósì wí fún ní èdè Heberu pé, "Rabboni" (tí ó túmọ̀ sí "Olùkóni"). 17 Jesu sì wí fún pe, "Má se fọwọ́ kàn mí, nítorí èmi kò tí gòkè lọ sọ́dọ̀ bàbá, ṣùgbọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi kí o sì wí fún wọn pé èmí ó lọ sọ́dọ̀ bàbá mi àti bàbá yín , àti Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín." 18 Maria Magdalene wá ósì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, "Mo ti rí Olúwa," Ó sì ti sọ n kan wọ̀nyí fún mi. 19 Nígbàtí ó di àsálẹ́, ní ọjọ́ nâ, ọjọ́ kìnnín ọ̀sẹ̀, a sì ti ti ìlẹ̀kùn ibití àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbé wà nítorí ẹ̀rù àwọn Ju, Jesu sì wọlé ósì dúró láàrin wọn ósì wípè, "Àláfíà ni fún yín." 20 Lẹ́yìn tí ó ti so èyí, ó fi ọwọ́ rẹ̀ àti ẹ̀gbe rẹ̀ han wọ́n. Inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì dùn nígbàtí wọ́n rí Olúwa. 21 Jesu sì wí fún wọn lệkan síi, "Àláífà ni fún yín. Gẹ́gẹ́ bí baba ṣe rán mi, bệ gẹ́gẹ́ ni èmí rán yin. " 22 Nígbàtí Jesu ti sọ èyí, ó mí sí wọn, ósì wí fún wọn pé, "Ẹ gba ẹ̀mí mímọ́. 23 Ẹni tí ẹbá sì dárí ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ jìn ni a ó dáríjì, ẹ̀sẹ̀ eni tí ẹ kò bá dáríji ni a ó ká si ní orùn" 24 Thomas, ọ̀kan lára àwọn méjìlá, tí à n pè ní Didymus, kò sí si ní bẹ̀ nígbàtí Jesu wá. 25 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn yǒkù sì wí fun pé, "Àwá ti rí Olúwa." Ó sì wí fún wọn pé, "Títi tí èmi ó fi rí ọwọ́ rẹ̀ níbi tí a ti kàn ní èsó, tí èmi ó sì fi ọwọ́ mi síi ibití a ti kǎn ní èsó, tí èmi ó sì fi ọwọ́ mi síi ní ẹ̀gbẹ́, ẹ̀mi kì yíò gbàgbọ́." 26 Lẹ́yin ọjọ́ kẹjọ àwọn ọmọ èyin rẹ̀ sì tùn wà nínù ilé, Thomas sì wà pẹ̀lú wọn. Nígbàtí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu wọlé ósì dúró lârin wọn , ó sì wípé, "Àláfíà ni fún yín." 27 Ó sì wí fún Thomas pé, " Nan ọwọ́ rẹ síbí kí o sì rí ọwọ̀ mi. Nan ọwọ́ rẹ síbí kí o sì fi kan ẹ̀gbẹ́ mi, Má ṣe aláìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n gbàgbọ́. 28 Thomas sì dáhùn ósì wípé, "Olúwa àti Ọlọ́run mi." Jesu sì wí fún pé, 29 "Nítorí tí ìwọ́ rí mi, ìwọ́ gbàgbọ́. Ìbùkún ni fún àwọn tí wọn kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́. 30 Nísisìnyí Jesu ṣe isẹ́ ámín púpọ̀ ní wájú àwọn ọmọ èyin rẹ̀, isẹ́ àmìn tí akò ti kọ̀wé rẹ̀ sínú ìwé yí, 31 ṣùgbọ́n a ti kọ̀we rè kí á le gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, e ó ní ìyè nínú orúkọ́ rẹ̀.