1 Nígbànâ ni Pilatu sì mún Jesu ósì lǔ. 2 Àwọn ọmọ ogun sì ṣe adé ègún. Wọ́n sì fi dée orí Jesu wọ́n sì wọ̌ ní asọ elése àlùkò. 3 Wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì wípé, "Eyin ọba Àwọn Ju!" wọ́n sì lǔ. 4 Nigbànâ ni Pilatu sì jáde lêkan si ósì wífun wọn pé, " Èmi ó mun wá sí gbangba fuń yiń kí ẹ̀yin kí ó le mọ̀ pé èmi kò rí ẹ̀bi nínú rẹ̀." 5 Jesu sí jáde pẹ̀lú adé ẹ̀gún àti asọ ilése àlùkò. Pilatu sì wípé, " Ẹ wǒ, okùnrin nân ni èyí. 6 Nítorínâ nígbàtí àwọn àlúfà ati àwọn olóyè sì rí Jesu, wọ́n pariwo wọ́n sì wípé, " Kǎn mọ́ ágbélébǔ, Kǎn mọ́ ágbélébǔ!" Pilatu sì wí fún wọn pé, ẹ mún ki ẹ sì kǎn mọ́ ágbélébǔ, nítorí èmi kò rí èbi kanakan nínú rẹ̀. 7 Àwọn Juu sì dáa lóhùn, "Àwá ní òfin, àti pé gẹ́gẹ́ bí òfin ó yẹ láti kú nítorí ó pe ara nì ọmọ Olọ́run." 8 Nígbàtí Pilatu sì gbọ́ èyí èrù bàá, 9 ó sì wọ inú ilé lọ ósì wífún Jesu pe, " Níbo ni ìwọ́ ti wa?" Ṣùgbọ́n Jesu kó dâ lódùn. 10 Nígbànâ ni Pilatu wí fun pé, "Nje ìwọ kò ní bá mi sọ̀rọ̀? ṣé ìwọ kò mọ̀ pé mo ní agbára láti tú ọ sílẹ̀ àti lati kàn ọ́ mọ́ ágbélébǔ?" 11 Jesu sì dáa lódùn wípé, "Ìwọ kò ní agbára kankan lórí mi àfi ètí tí a ti fi fún ọ látòkè wá.Nítorínâ, ẹni tí ó fi mì fún ọ ní ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ga ju. 12 Ìdáhùn yí, Pilatu gbìyànjú àti tu sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn Ju pariwo, wípé, "Bí ìwọ́ bá tú arákùnrin yìí sílẹ́, ìwọ kì ṣe ọ̀rẹ́ Caesar. Ẹni kẹ́ni tí ó sì fi ara rẹ̀ jọba a má sọ̀rọ̀ lòdi sí Caesar." 13 Nígbàtí Pilatu sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mún Jesu wá sí ìta ósì jókǒ lórí ìtẹ́ ìdájọ́, tí a n pè ní "Gabbatha" ní èdè Heberu. 14 Ójẹ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún àjọ ìrékọjà nígbànâ, ni wákàtí kewǎ. Pilatu sì wí fún àwọn Ju pe, "Wǒ, ọba yín ni èyí!" 15 Wọ́n sì kígbe, "Kǎn mọ́ ágbélébǔ, kǎn mọ́ ágbélébǔ!" Pilatu sì wí fún wọn pe, "Ṣé kí a kan ọba yín mọ́ ágbélébǔ,?" Olóye àlúfà si dáa lóhùn, " Àwa kò ní ọba bíkòse Caesar. 16 Nítorínâ Pilatu fi Jesu fún wọn láti kàn mọ́ ágbélébǔ. 17 Nígbànâ ni wọ́n mún Jesu, Ósi jáde lọ, Ó gbé ágbélébǔ rẹ̀, lọ si ibi tí à n pè ní "Ibi egungun orí" tí à n pè ní "Golgotha" ní èdè Heberu. 18 Níbẹ̀ ni wọ́n ti kan Jesu mọ́ ágbélébǔ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin méjì, ọ̀kòkan wọn ní apá kọ̀kọ̀kan Jesu sì wà ní àrin wọn. 19 Pilatu sì kọ àmì kan ó sì gbe sórí ágbélébǔ. Oun tí a kọ nì yí: JESU, ARÁ NASARẸTI, ỌBA ÀWỌN JU. 20 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Ju ni ó ka èyí nìtorí ibi tí a ti kan Jesu mọ́ ágbélébǔ sún mọ́ ìlu. Akọ àmìn nân ni ède Heberu, Latin àti Greeki. 21 Nígbànâ ni ìjòyè àlúfà ti àwọn Ju sọ fún Pilatu pé, "Má ṣe kọ, 'Oba àwọn Ju' ṣùgbọ́n bíkòse, 'Eléyǐ sọ pe, ''Èmi ni Oba àwọn Ju."" 22 Pilatu sì dáhùn, "Oun tí èmí ti kọ èmí ti kọ́ ná" 23 àwọn ọmọ ogun sì ti kan Jesu m Jesu abélébǔ, wọ́n pín asọ rẹ̀ sí ònà mẹ́rin, ọ̀kan fún ẹnìkọkan wọn; 24 Nígbànâ ni wọ́n wí fún ara wọn, "Ẹmaá ṣe jẹ́ kí a yaá, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a sẹ́ gègé kí ále mọ ọ̀dọ̀ ẹni ti yíò bọ́sí. "Èyí sẹlẹ̀ kí a le mún ìwé mímọ́ ṣẹ tií o wípé, "Wọ́n pín asọ mi láàrin ara wọn wọ́n sì sẹ́ gègé fún asọ mi. 25 Àwọn tí o wà ẹ́gbẹ̌ ágbélébǔ Jesu ni ìya rẹ̀, àbúrò ìya rẹ́ obìnrin, Maria aya Klopas, àti Maria Magdalnani. 26 Nígbàtí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ ẹ̀yìn re tí o nífě si tí ó dúró lẹ́gbẹ̌ ibẹ̀, Ó wí fún ìya rẹ̀, "Ìyá, wo ọmọ rẹ!" 27 Nígbànâ ni Jesu wí fún ọmọ ẹ̀yin nâ pé, "Wo, ìyá rẹ!" Lati wákàtí nâ ọmọ ẹ̀yìn nâ mún lọ sí ilé rẹ̀. 28 Lẹ̀yin nân, ti o mọ̀ pé oun gbogbo ti parí ati pe kí á leè mún ìwé mímọ́ ṣẹ, Jesu wipe, "Òrùgbẹ n gbẹ mí." 29 A sì gbé Ìkòkò tí ó kún fún otí kíkan kalẹ̀, nígbànâ ni wọ́n mún kànkàn ti ó kún fún otí kíkan tí a fi sí orí ọ̀pá Hyssop wọ́n sì nǎ síi ní ẹnu. 30 Nígbàtí Jesu sì ti mun otí kíkan nâ, Ó wípe, "Ó parí." Ó tẹ orí rẹ̀ ba ósì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ lọ. 31 Nítorínâ àwọn Ju, nítòrí ójẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, àti pé kí ara wọn má baà wà lórí ágbélébǔ ni ọjọ́ (Sabbath), Pilatu sí pàṣẹ kí á fọ́ wọn ní ẹsẹ̀ kí á sì gbé wọn kúrò lórí igi. 32 Nígbànâ ni ọmọ ogun nâ wa ó sì fọ́ egungun ẹsẹ́ àwọn méjì tí a kaǹ mọ́ ágbélébǔ pẹ̀lú Jesu. 33 Nígbàtí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n ri pé óti ku, nítorínâ wọn kò fọ́ egungun rẹ̀. 34 Ó sìse, ọ̀kán nínu àwọn ọmọ ogun fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ kún ní ẹ̀gbẹ̀, lójúkannâ ẹ̀jẹ̀ áti omi jàde. 35 Ẹni tí o rí èyí sì ti jệrí, ẹ̀rí nâ sì dájú. Ó mọ oun tí ó rí pé òdodo ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú leè gbàgbọ́. 36 Oun kan wọ̀nyí sẹllè kí ále mún ìwé mímọ́ ṣe, "Kò sì ọ̀kan nínu egungun rẹ̀ tí yíò kan." 37 Bákannâ, ni ìwé mímọ́ tún sọ, "Wọn ó wo ẹni tí a gún ní ọ̀kọ̀ 38 Lẹ́yìn oun kan wọ̀nyí, Josefu ará Arimathea, nígbàtí o n si ṣe ọmọ ẹ̀yin Jesu (Sùgbọ́n ní kọ̀kọ̀ nítorí ẹ̀rù àwọn Ju), o bèrè lọ́dọ̀ Pilatu bí o n bále gbé ara Jesu. Pilatu sì fun ní àṣẹ. Josẹfu sì wá ósì gbé ara rẹ̀ lọ. 39 Nikodemu pẹ̀lú wá, ẹni tí óti kọ́kọ́ lọ rí Jesu ni òru. Ó mún òróró ìkunra tí ó tó ìwọ̀n mérinlélọ́gbọ̀n. 40 Nítorínâ wọ́n mú ara Jesu wọ́n si wa ni asọ pẹ̀lú ìkunra, gẹ́gẹ́ bí àsà ìsìnku àwọn Ju. 41 Ọgbà àjàrà kán wa ní ibi tí ati kǎn mọ́ ágbélébǔ; ibojì kán sì wà nínú ọgbà náà nínú èyí tí a kò tí sin ẹnikẹ́ni sí. 42 Nítorí ó jẹ̀ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ ti Ju àti pé ibojì náà sún mọ́ wọ́n tẹ́ẹ sínú rẹ̀.