1 Nígbà tí Jesu sì ti sọ ọ̀rọ̀ wòn yí tán, Ó jáde lọ sí apá kejì òkè odò kidroni pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀, níbití àgbàlá kan wà tí òun, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ wọ̀. 2 Judasi ẹnití yio fi Jesu han, pẹ̀lú mọ ibití wọ́n wà, nítorí Jesu pẹ̀lu àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ a má lọ síbẹ̀ nígbàkúgbà. 3 Nígbàna ni Judasi síwájú àwọn egbẹ́ ọmọ-ogun, àti àwọn onísẹ́ láti ọ̀dọ àwọn olórí alufa àti àwọn Farisí lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àtùpà, fìtíla ati àwọn oun ìjà lọ́wọ́. 4 Nítorí ti Jesu kò sai mọ oun gbogbo ti Òun sẹlẹ̀, Ó bọ́ síwájú Ósì bi wọ́n léèrè pé, "Tani ẹ̀yin nwa'? 5 Wọ́n da lóhùn pé, "Jesu ti Naṣarẹti" Jesu wi fun wọn pe, "Èmi nì yí." Judasi ẹni tí ófihàn pẹ̀lú, duro larin ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ogun. 6 Nígbà tí Ó wí fún wọn pé, "Èmi ni," wọ́n sún sẹ́yìn wọ́n sì subú lulẹ̀. 7 Nígbà na ni ó tún bi wọ́n pe, "Tani ẹ̀yin nwá?" wọ́n sì tún wípé, "Jesu ti Nasarẹstí." 8 Jesu daun wípé, "Mo wí fun yin pé, Émi ni. Bí ẹ̀yin bá sì n wá mi, ẹjẹ́ kí àwọn wọ̀n yí lọ." 9 Èyí ni láti fi ìdí ọ̀rọ̀ tí Ó ti sọ tẹ́lẹ̀ múlẹ̀ pe, "Nínú àwọn tí o fi fún mi, ọ̀kankan kò sọnù." 10 Nígbàna ni Simoni Peteru, tí ó ni idà lọ́wọ́, fa idà yọ, ókọ lu ìránsẹ́ olórí alufa, ósì ké etí lulẹ̀. Ẹni tí orúkọ rẹ̀ ńjé Malkọsi. 11 Jesu wí fún Peteru, "Fi idà rẹ padà sínú àkọ̀ rẹ. N kò a ní sai mu nínú ago tí Baba ti fi fún mí?" 12 Nígbà naa ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀sọ́, àti àwọn ónsẹ́ àwọn Ju mú Jesu wọ́n sì dé e. 13 Wọ́n kọ́ kọ́ faa lọ sí ọ̀dọ Anasi, nítorí àna Kaiafasi ni íse, ẹnití íse olórí alufa ní ọdún nà 14 Kaiafasi saa jẹ́ ẹnití óti gba àwọn Ju níyànjú pé, ódára kí ẹnìkan kú fun àwọn ènìyàn. 15 Simoni Peteru tẹ̀lé Jesu lẹ́yìn, bẹẹ sìni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn. Ọmọ ẹ̀yìn naa jẹ́ ojúlùkọ̀ fun olórí alufa, ósì tẹ̀lé Jesu wọ àgbàlá olórí alufa naa lọ; 16 sùgbọ́n, Peteru dúró sí ẹnun ọ̀nà ní ìta. ọmọ ẹ̀yìn naa tìí se ojúlùmọ̀ sí olórí alufa, jáde lọ sí ìta, óbá ọmọbìnrin kan tí oun wo ohun tó n sẹlẹ̀ lati ẹnun ọ̀nà, ósí mú Peteru wọlé. 17 Nígbà naa ni ìránsẹ́ bìnrin, asọ́nà, wí fún Peteru pé, "Ọ̀kan nínún àwọn ọmọ ẹ̀yin arákùnrin yii kọ́ ani ìwọ íse?" Ó dahún, "Èmi kọ́." 18 Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ àti àwọn ónsẹ́ dúró níbẹ̀, wọ́n sì ti dáná ẹyìn, ítorí otútù, wọ́n si n yáná. Peteru pẹ̀lú dúró ósi n yáná pẹ̀lú wọn. 19 Olórí alufa naa sì bi Jesu léèrè níti àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ àti níti ẹ̀kọ rẹ̀. 20 Jesu da lóhùn pe, "Èmí ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni Èmí ti ǹkọ́ ni ní sinagogu, ati ni tẹmpili níbití àwon Ju tín péjọpọ̀ sí. Kòsí oun tí mo sọ ní kọ̀kọ̀. 21 Èése tí ìwọ fín bimí léèrè? Bi àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo ti wí fún wọn. Kíyèsi, àwọn wọ̀n yi mọ ohun Èmí wí. 22 Nígbàtí Jesu ti sọ èyí tán, ọ̀kan nínú awon ónsẹ́ tí ódúró lu Jesu, ó wípé, "Sé olórí alufa ni ìwọ́ n da lóhùn bá un?" 23 Jesu da lóhùn, "Bí mo bá sọ oun tó burú jẹri si oun búburú na, sùgbọ́n bí ó bá se òtítọ́ ni, èése tí iwọ fi lù mí?" 24 Annasi sì ran lọ sí ọ̀dọ Kaiafasi olórí alufa. 25 Simoni Peteru dúró ó sin yáná. Àwon ènìyán sí wi fun pe, "Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ a kọ́ ni ìwọ? Ó kọ̀, ó ní, "Bẹẹ kọ." 26 Ọ̀kan nínú àwọn ìránsẹ́ olórí alufa tii se ìbátan arákùnrin ẹnití Peteru gé etí rẹ̀ bọ́, wípe, "Èmi kò a ri ọ nínú àgbàlá pẹ̀lu rẹ bi?" 27 Peteru si tun kọọ lẹkan si; lójú kannaa, àkùkọ́ kọ. 28 Nígbànâ ni wọ́n darí Jesu lati ọ̀dọ kaiafasi lọsí gbàngàn ìdájọ́. ósì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀, won ko le wọ gbàngàn naa kí wọn kí ó má baa di aláìmọ́, sùgbọ́n kí wọn le jẹ nínu àsè ìrékọjá. 29 NÍgbànâ ni Pilatu jáde sí wọn, ó wípé, "Ẹ̀sùn kin ni ẹmú wá fún arákùnrin yii?" 30 Wọ́n dáhùn, wọ́n wí fun n pé, "Bí arákùnrin yi kòbá jẹ́ olùse búburú, àwa ki ba ti fa a le ọ lọ́wọ́." 31 Pilatu si wí fún wọn pé, "Ẹmú n fún ra yín, kí ẹ sì da a lẹ̀jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin yín." Àwọn Ju dáhùn pé, "Kò tọ́ fún wa kí ápa ẹnikẹ́ni." 32 Wọ́n sọ èyí kí ọ̀rọ̀ Jesu le sẹ nípa irù íku ti yio kú. 33 Pilatu sì tún wọ inú gbàngàn ìdájọ́ lọ, ó pe Jesu ó bí wípé, "Ọba àwọn Ju a ni ìwọ íse?" 34 Jesu dáhùn wípé, "Ìwọ́ a sọ èyí fún ara Rẹ tàbí oun tí ẹlòmíràn sọ fún ọ nípa mi? 35 Pilatu dáhùn, "Èmí íse Ju bí? Àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn alufa ló fà ọ lémi lọ́wọ́. kí ni ìwọ́ se?" 36 Jesu dáhùn, "Ìjọba mi kii se ti ayé yi. Ìbá se bẹẹ, àwon ìránsẹ mi ki báá jà kí á má ba fà mí lé àwọn Ju lọ́wọ́. sùgbọ́n ìjọba mi kii se ti ìyín yí." 37 Nígbànâ ni Pilatu dáhùn wípé, "Ìwọ́ a íse ọba bi?" Jesu dáhùn, Ìwọ wípé ọba ni mí. Fún ìdí èyí ni a se bí mi, àti fún ìdí èyi ni mo se wá sínú ayé lati jẹ́ẹ̀rí sí òtítọ́ yí. Gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ti òtítọ́ n fetí sí ọ̀rọ̀ mi. 38 Pilatu wi fun pé, "Kíni òtítọ́?" Nígbàtí ó sọ èyí tan, ó jade lọ láti ba àwọn Ju, ó wípé, "Kòsí ẹ̀bi kan lòdì sí arákùnrin yi. 39 Ṣùgbọ́n ẹ̀yín ní àsà pé kí èmi dá ẹnìyan kan sílẹ̀ ní ọjọ́ọ àjọ ìrékọjá. Nítorí na, kí èmi kí o dá ọba àwọn Ju sílẹ̀ fun yín bí?" 40 Wọ́n sì tún kí gbe pé, "Kii se arákunrin yii ṣùgbọ́n Barabba." Barabba si jẹ́ ọ̀daràn.