Orí Kọkànlélógún

1 Lẹ́yìn àwọn nǹkan wọ̀nyí, Jésù sì tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn ní òkun Tíbéríásì. Báyìí ni Ó ṣe fi ara rẹ̀ hàn: 2 Símónì Pétérù wà papọ́ pẹ̀lú Tómàsì tí à ń pè ní Dídímọ́sì, Nàtáníẹ̀lì láti Kánà ti Gálílì, àwọn ọmọ Ṣébédè, àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù méjì míràn. 3 Símónì Pétérù wí fún wọn pé "èmi lọ ń pẹja." Wọ́n sì wí fun pé "àwa nà yíò tẹ̀le ọ." Wọ́n lọ, wọ́n sì kó sí inú ọkọ̀ ojú-omi kan, ṣùgbọ́n wọn kò ri ẹja kankan mú ni gbogbo òru náà. 4 Nísisìyí, nígbàtí ó ti di òwurọ̀ kùtùkùtù, Jésu dúró ní etí bèbè, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-èhìn kò mọ́ pè Jésù ni. 5 Nígbànáà ni Jésù wí fún wọn pé "ẹ̀yin ọ̀dọ́-kùnrin, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní ohunkóhun fún jíjẹ"? Wọ́n da lòhùn pé "rárá." 6 Ó sì wí fún wọn pé, "ẹ ju àwọ̀n yín sí apá ọ̀tún ọkọ̀, ẹ ó sì rí àwọn kan." Nígbànáà ni wọ́n ju àwọ̀n, wọn kò sì le fàá sínú ọkọ̀ nítorì ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja. 7 Nígbànáà ni ọmọ-ẹ̀hìn tí Jésù fẹ́ràn wí fún Pétérù pé "Olúwa ni." Nígbàtí Símónì Pétérù gbọ́ pé Olúwa ni, ó ró asọ móra (nítorí tí kò wọ ẹ̀wù), ó sì ju ara rẹ̀ sínú òkun. 8 Áwọn ọmọ-ẹ̀hìn yókù sì wá pẹ̀lú ọkọ̀ (nítorí tí wọn kò jìnnà sí ilẹ̀, ìwọn bi igba ìgbùnwọ́), wọ́n sì ń fa àwọn tí ó kún fún ẹja. 9 Nígbàtí wọ́n sì jáde sí ilẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yìn-iná kan níbẹ̀ ti ẹja wà lórí rẹ̀, pẹ̀lú àkàrà. 10 Jésù wí fún wọn pé, "ẹ mú díẹ̀ wá nínú àwọn ẹja tí ẹ sẹ̀sẹ̀ mú." 11 Símónì Pétérù sí gòkè lọ láti fa àwọ̀n wá sí ilẹ̀, tí ó kún fún àwọn ẹja ńlá. Ẹ́tà-lé-ní-àádọ̀jọ ni wọ́n, bí wọn sì ti pọ̀ tó, àwọ̀n nà kò ya. 12 Jésù wí fún wọn pé, "ẹ wá jẹ óuńjẹ òwúrọ̀." Kòsì sí ìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí ó jẹ́ bi í lérè pé, "tani ìwọ?" Wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. 13 Jésù wá, ó mú àkàrà, Ó sì fi fún wọn, àti ẹja pẹ̀lú. 14 Èyí ni ìgbà kẹ̀ta tí Jésù fi ara hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn lẹ́yìn tí ó ti jí dìde nínú òkú. 15 Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ óúnjẹ òwúrọ̀ tán, Jésù sọ fún Símónì Pétérù pé, "Símónì ọmọ Jòhánù, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn nǹkan wọ̀nyí lọ bí?" Pétérù sì wí fun pé, "bẹ́ẹ̀ni Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ Ọ." Jésù sì wí fun pé, "bọ́ àwọn ọmọ-àgùtàn mi." 16 Ó sì tún sọ fun ní ẹ̀kejì, "Símónì ọmọ Jòhánù, sé o fẹ́ràn mi?" Pétérù sì wí fun pé, "bẹ́ẹ̀ni Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ Ọ." Jésù si wí fun pé, "ma tọ́jú àwọn àgùtàn mi." 17 Ó sọ fun ní ìgbà kẹ̀ta pé, "Símónì ọmọ Jòhánù, ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ mi bí?" Inú Pétérù bàjẹ́ nítorí tí Jésù ti sọ fun ní ìgbà kẹ̀ta, "Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ mi bí?" Ó sì wí fún pè "Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo, Ìwo mọ̀ pé mo fẹ́ Ọ." Jésù si wí fun pé, "ma bọ́ àwọn àgùtàn mi. 18 Lótìtọ́, lótìtọ́ ni Mo wí fún ọ, nígbàtí ìwọ wà ní kékeré, ìwọ ma ń da aṣọ bo ara rẹ láti lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá dàgbà, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíràn yóò sì da aṣọ bò ọ́ láti gbé ọ lọ sí ibi tí o bá fẹ́ lọ." 19 Nísisìyí, Jésù sọ eléyìí láti fi irú ikú tí Pétérù yóò kú fún ògo Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Ó ti sọ èyí, Ó wí fún Pétérù pé, "Tẹ̀lé mi." 20 Pétérù wo ẹ̀yìn, ó sì rí ọmọ-ẹ̀hìn tí Jésù fẹ́ràn tí ó tẹ̀lé wọn, èyí kánnà ni ó gbé ara le Jésù ní óunjẹ́ alẹ́, tí ó sì wípé, "Olúwa, tani yóò fi Ọ́ hàn?" 21 Pétérù ri i, ó sì wí fún Jésù pé, "Olúwa, kínni ọkùnrin yìí yóò ṣe?" 22 Jésù wí fun pé, "Tí Mo bá fẹ́ kí ó wà títí tí màá fi dé, kínni èyí jẹ́ fún ọ? Tẹ̀lé mi". 23 Ọ̀rọ̀ nà sì tànká láàrín àwọn ará-kùnrin, pe ọmọ-ẹ̀hìn náà kì yóò kú. Ṣùgbọ́n Jésù kò sọ fún Pétérù pé ọmọ-ẹ̀hìn náà kì yóò kú, ṣùgbọ́n, "Tí Mo bá fẹ́ kí ó wà títí tí màá fi dé, kínni èyí jẹ́ fún ọ?" 24 Èyí ni ọmọ-ẹ̀hìn tí ó ṣe elérìí àwọn nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ àwọn nǹkan wọ̀nyi, a sì mọ̀ pé ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́ òtítọ́. 25 Àwọn nǹkan míran sì wà tí Jésù ṣe. Tí a bá kọ ìkọ̀kan wọn sílẹ̀, mo lérò pé ayé kì yó le gba àwọn ìwé tí a ó kọ.