Orí Kínní

1 Pọ́ọ̀lù, ìránsẹ́ Jésù Kristí, tí a pè láti jẹ́ àpósítélì, tí asì yàsọ́tọ̀ fún ìhìnrere Ọlọ́run. 2 Ìhìnrere yìí ni Ó ti ṣèlérí sáájú látẹnu àwọn wòlíi Rẹ̀ nínú ìwé mímọ́ 3 Ó dá lóríi ọmọ Rẹ̀, ti ó ti ìran Dáfídì jáde wá. 4 Nítori àjíǹde kúrò nínú òkú, a pè É ní ọmọ Ọlọ́run tó l'ágbára nípa Ẹ̀mí iwa mímọ́, -- Jésù Krístì Olúwa wa. 5 Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a se gba ore-ọ̀fẹ́ àti ìjé ajíyìnrere fún ìgbọ́ràn ìgbàgbọ́ láàrin àwọn orílèdè, nítori orúkọ Rẹ̀. 6 Láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yìí ni a ti pe ẹ̀yin gan láti di ti Jésù Kristì. 7 Eléyi ni ìwé tí a kọ sí gbogbo àwọn olùfẹ Olórun tó wà ní rómù, àwọn tí a pè láti jẹ́ mímọ́. Kí ore-ọ̀fẹ́ àti àláfíà jẹ́ tiyín láti ọ̀dọ Ọlórun, bàba wa àti Olúwa Jésù Krístì. 8 Sáájú, mo dúpé lọ́wọ́ Ọlórun mi nípasẹ̀ Jésù Kristì fún ayé yín, nítorí ìròyín ìgbàgbọ yín tàn káàkiri àgbáyé. 9 Ọlọ́run tí mò ń sìn nínú ẹ̀mí mi àti nínú ìhìnrere ọmọ Rẹ̀ ṣẹ ẹlẹ́rìí mi, níti bí mo ṣe máa ń dárúkọ yín lemọ́lemọ́. 10 Gbogbo ìgbá ni mò ń gbàá mọ́ àdúrà pé ní gbogbo ọ̀nà kí n lè ṣe àṣeyorí níti wíwá sọ́dọ yín nípa ìfẹ Ọlọ́run. 11 Mo fẹ́ ríyín, kí n lè fún yín ní àwọn ẹ̀buǹ ẹ̀mí tí yó gbe yín ró. 12 Àní mo fẹ́ k'ájo ru ọkàn ara wa sókè, nípa ìgbàgbo ara wa, tiyín àti tèmi. 13 Ará, mi ò fẹ́ kí ẹ saláìmọ̀ pé mo máa ń gbìyànjú làti wá s'ódo yín (sùgbọ́n mo ní ìdíwọ́ títì di àsìkò yìí), kí n lè jèrè ọkàn lọ́dọ yín bí ti àwọn kèfèrí yòókù. 14 Mo jẹ́ onígbèsè fún àti gíríkì, àti àlejò, pẹ̀lu ọlọgbọ́n àti òmùgọ̀. 15 Torí èyí ni mo se ṣe tan láti kéde ìhìnrere fún èyin náà tí ẹ wà ní Rómù. 16 Èmi kò tijú ìhìnrere, nítorí agbára Ọlọ́run ni fún ìgbàlà fún àwọn tó gbàgbọ́, sáájú fún àwọn Júù àti fún àwọn Gíríkì. 17 Nínú rẹ̀ ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn láti ìgbàgbọ́ dé ìgbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí ati kọ́pé, "Olódodo yó ma gbé nípa ìgbàgbọ́". 18 Láti ọ̀run wá ni ìbínú Ọlọ́run tiń ru sórí gbogbo àìwàbí-Ọlọ́run àti àwọn àìsòdodo àwọn ènìyàn, àwọn tó ń fi àìsòdodo fa òtítọ́ sẹ́yìn. 19 Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Ọlórun ti fi ara hàn wọ́n, kedere sì ni lójú wọn. 20 Àwọn àbùda àìri Rẹ̀; agbára àìlópin àti àbùdá ọ̀run Rẹ̀, ni atirí kedere nínú àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀, láti ìgbà tí a ti d'áyé. Torí náà kò sí àríwíjọ́. 21 Èyí jẹ́bẹ̀ nítorí pé, bí wọń tilẹ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run, wọn kò fi ògo àti ọpẹ́ fún gẹ́gẹ́ bíi Ọlórun. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n di òmùgọ̀ nínú èrò wọn, ọkàn aláìlóye wọn si sókuǹkùn. 22 Wọ́n gbọ́n lójú ara wọn, sùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀. 23 Ògo tó yẹ fún Ọlọ́run tí kòledíbàjẹ́, wọ́n fi fún àwòrán tó lè díbàjẹ́ bíi ènìyàn, ẹyẹ, ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti àwọn t'ó ń rákòrò. 24 Torí náà ni Ọlọ́run ṣe fàwọ́n lé ìfẹ́kúfẹ okàn wọn láti di àìmọ́, kí ara wọn lè di àìlọ́lá láàrin wọn. 25 Àwọn ni ó pàrọ̀ òdodo Ọlọ́run fún irọ́, wọ́n sì ń foríbalẹ̀, wọn ń sin ẹ̀dá dípò Ẹlẹ́dàá; Ẹni tí ó ni ìyìn títí láí. Àmín. 26 Nítorí èyí, Ọlọ́run fàwọ́n lé ìfẹ́kùfẹ́ ara aláìlọ́lá, nítorí àwọn obìnrin wọn ń pàrọ̀ ìbásepọ̀ ojúlówó fún àtọwọ́dá. 27 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin ṣe kọ ìbásepọ̀ ojúlówó sílẹ̀ tí wọ́n ń bárawọ́n lòpọ̀ nínú ìfẹ́kùfẹ́. Àwọn yìí ni ọkùnrin tí wọ́n ń bá ọkùnrin ẹgbẹ́ wọn ṣèṣekúṣe, tí wọ́n sì jẹ ìyà tó tọ́ fún ìse wọn. 28 Wọn kò jọ̀wọ ara wọn fún ìwáláàye Ọlórun, Ó jọ̀wọ wọn fún iyè ríra láti máa se ohun tí kò tọ́. 29 Wọ́n ti kún fún orísirísi àìsòdodo, ìkà, ojúkòkòrò, asọ̀. Wọ́n kún fún owú jíjẹ, ìpànìyàn, àrankan, ẹ̀tàn àti ète ibi 30 Àwọn ni asòfófó, asọ̀rọẹnilẹ́yìn àti ọ̀ta Ọlọ́run. Àwọn ni oníjàgídíjàgan, alágídí, onígbèrega. Lọ́tunlọ́tun ni nkàn ibi lọ́dọ wọn, wọ́n tún jẹ́ aṣàìgbọràn sí òbí wọn. 31 Wọn kò ní òye; wọn kò sé gbẹ́kẹ̀lé, wọn kò ní ìkáànú tòótọ́ wọn kò sì làánú. 32 Wọ́n ní òye òfin Ọlọ́run, pé àwọn tó ń ṣe irú nkàn wọ́n yìí yẹ fún ikú. Ṣùgbọ́n kìí ṣe àwọn tín sé nìkan bíkòṣe àwọn tín ó ń gbè lẹ́yìn wọn.