Orí Kínní

1 Èyí ni Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere ti Jésù Kristì, Ọmọ Ọlọ́run. 2 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé: “Wò ó, Èmi ń ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ, Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.” 3 “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ 4 Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. 5 Gbogbo ilẹ̀ Judea àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 6 Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì ń jẹ eṣú àti oyin ìgàn. 7 Ó wàásù wí pé, “Ẹnìkan ń bò tí ó lágbára jù mí lọ, èmi kò tọ́ ní ẹni tí ń wólẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀. 8 Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.” 9 Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọn nì tí Jesu ti Nasareti ti Galili wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. 10 Bí Jésù se ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. 11 Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi. Inú mi dùn sí o gidigidi.” 12 Ẹ̀mí Mímọ́ náà sì darí Rẹ̀ sí inù aginjù. 13 Ó sì wà ní aginjù fún ogójì ọjọ́, ti Satani ń dán an wò. Ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́, àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un. 14 Nísinsìyí lẹ́yìn ìgbà tí a mú Johanu sínú ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti Ọlọ́run. 15 Ó ń wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.” 16 Nígbà ti ó ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi awọ̀n wọn pẹja, torí pé apẹja ni wọ́n. 17 Jesu sì wí fún wọn pé, “Ẹ wa, ẹ tẹ̀lé mi, Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 18 Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀lé e. 19 Bí Jésù sì ti rìn síwájú díẹ̀, Ó rí Jakọbu ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀, wọ́n wa nínú ọkọ̀ wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. 20 Ó ké wọn, wọ́n sì fi Sébédè baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 21 Lẹ́yìn náà wọ́n wọ Kápérnáúmù, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, Jésù lọ sínú Sínágọ́gù ó sì ń kọ́ni. 22 Ẹnu sì yà wọ́n nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin. 23 Nígbànáà ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sínágọ́gù wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, 24 wí pé, “Kí ni àwa ní se pèlu rẹ, Jésù ti Násárẹ́tì? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!” 25 Jesu si bá èmí èsù náà wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀!.” 26 Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e sánlè, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà bí ó ti ń ké ní ohùn rara. 27 Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń bi ara wọn pé, "Irú kíni èyí? Ẹ̀kọ́ tuntun pẹ̀lú àsẹ? Ó tún pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀!” 28 Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbègbè Galili. 29 Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú Sínágọ́gù, wọ́n lọ sí inú ilé Símónì àti Áńdérù pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù . 30 Ìyá- ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jésù nípa rẹ̀. 31 Ó sì wá, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; ibà náà si fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. 32 Ní àṣálẹ́, tí oòrùn ti wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. 33 Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. 34 Ó sì wo ọ̀pọ̀ tí ó ní onírúurú ààrùn sàn, ó sì tún lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, ṣùgbọ́n kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sọ̀rọ̀ nítorí tí wọ́n mọ̀ ọ́. 35 Ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́, Ó kúrò ó sì lọ sí ibi tí ó dákẹ̀ láti lọ gbàdúrà. 36 Símónì àti àwọn tí ó wà pẹ́lu rẹ̀ lọ láti wá a. 37 Wọ́n rí I wọ́n sì wí fún pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!” 38 Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ibò mìíràn, sí àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni mo ṣe wá.” 39 Ó ń lọ káàkiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. 40 Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá. Ó sì ń bẹ̀ẹ́; ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí fún n pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.” 41 Àánú sì se é, Jésù na ọwọ́ rẹ̀ ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.” 42 Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ó sì di mímọ́. 43 Jésù sì kìlọ̀ fún un gidigidi ó sì rán an lọ. 44 Ó wí fún n pé, “Rí i dájú pé o kò sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n lọ fi ara rẹ̀ hàn àlùfáà, kí o sì mú ẹ̀bùn lọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ èyí tí Mósè pàṣẹ, èyí tí í ṣe ẹ̀rí fún wọn.” 45 Ṣùgbọ́n ó jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí, ó ń tan ìròyìn kálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Jésù kò sì le wọ ìlú kankan mọ́. Ó sì dúró ní ibi ìdákẹ́jẹ́, àwọn ènìyàn tọ̀ ọ́ wá láti ibi gbogbo.