ORÍ KEJÌ

1 Nígbàtí Ó padà sí Kápánámù lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó di mímọ̀ wípé Ó wà nínú ilé. 2 Ọ̀pọ̀lọọpọ̀ sì péjọ níbẹ̀ tóbẹ̀ tí kò fi sí ààyè mọ́, kò sí lẹ́nu ìlẹ̀kùn pẹ̀lú, Jésù sì bá wọn sọ ọ̀rọ̀ náà. 3 Nígbànáà ni àwọn ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ. wọ́n gbe ọkùnrin arọ kan; ènìyàn mẹ́rin ni ó gbé e. 4 Nígbàtí wọ́n kò sì le dé ọ̀dọ̀ rẹ nítorí ọ̀pọ́ ènìyàn, wọ́n sí òrùlé ibi tí Jésù wa, lẹ́yìn èyí ni wọ́n rí ààyè, wọ́n sì sọ ibùsùn tí ọkùnrin tí arọ náà sùn sí. 5 Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn, Ó sì wí fún ọkùnrin arọ náà pé, "Ọmọkùnrin, a fi gbogbo ẹ̀sẹ̀ rẹ jìn ọ́" 6 Àwọn akọ̀wé sì joko síbẹ̀, wọ́n sì nrò nínú ọkàn wọn: 7 "Bawo ni ọkùnrin yi ti nsọ̀rọ̀ bayi? O nsọ̀rọ̀ òdì! Tani ẹni náà tí ó le fi ẹ̀sẹ̀ jìn bíkòse Ọlọ́run nìkan?" 8 Lójú ẹsẹ́ Jésù mọ ohun tí wọn nrò láàrin ara wọn nínú ọkàn rẹ. Ó wí fún wọn, "Kílódé tí ẹ̀yín fi nro èyí nínú ọkàn yin?" 9 Èwo ni ó rorùn jù láti wí fún ọkùnrin tí arọ náà, 'A dárí gbogbo ẹ̀sẹ̀ rẹ jìn ọ́' tàbí lati wípé 'Dìde, gbé ibùsùn rẹ kí o sì ma rìn?' 10 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó le mọ̀ wípé Ọmọ ènìyàn ní àsẹ ní ayé lati dárí ẹ̀sẹ̀ jìn" Ó wí fún ẹnití ó rọ náà, 11 "mo wí fún ọ, dìde, gbé ení rẹ, kí o sì ma lọ sí ilé rẹ." 12 Ó dìde lójú ẹsẹ́, ó sì gbé ení rẹ, ó sì jáde kúrò ninú ilé náà lójú gbogbo ènìyàn, tóbẹ̀ tí ẹnu sì ya gbogbo wọn, tí wọ́n sì fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì wípé, "A kò rí irú èyí rí rárá." 13 Ó sì tún jáde lẹ́ba omi adágún kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, Ó sì kọ́ wọn. 14 Bí Ó sì ti nkọjá lọ, Ó rí Lefi ọmọ Álféusì ti o joko ni àgọ́ agbowó òde, Ó sì wí fún un pé, "Tọ̀ mí lẹ́yìn." Ó dìde, ó sì tọ lẹ́yìn. 15 Jésù si njẹun nínú ilé Lefi àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ, wọn ba a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí wà níbẹ̀, wọ́n si ntọ lẹ́yìn. 16 Nígbàtí àwọn akọ̀wé, ti wọn jẹ́ Farisí, rí tí Jésù njẹun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sẹ̀ àti àwọn agbowó òde, wọ́n wí fún àwon ọmọ ẹ̀yìn rẹ pe, "Kíló sẹlẹ̀ tí O nfi bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀ jẹun?" 17 Nígbàtí Jésù gbọ́ ọ̀rọ̀ yí Ó wí fún wọn pe, "Àwọn ènìyàn tí ara wọn ya kò wá onísègùn; àwọn tí ara wọn kò yá ni wọ́n nílò rẹ. Èmi kò wá lati pe àwọn olododo bíkòse àwọn ẹlẹ́sẹ̀." 18 Ó sì se, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ti Farisí ngba àwẹ̀. Àwọn ènìyàn kan wá, wọ́n sì wí fún pe, "Kíló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ti Farisí fi ngbawẹ, sùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yín rẹ ko gbàwẹ̀?" 19 Jésù sí wí fún wọn pé, "Sé ó seése kí àwọn tì ó wá sí ibi ìgbéyàwó ma gbàwẹ̀ nígbàtí ọkọ ìyàwó sì wà pẹ̀lú wọn?" Níwọ̀n ìgbàtí wọn bá sì ní ọkọ ìyàwó larin wọn, kò seése fún wọn lati gbàwẹ̀. 20 Sùgbọ́n ọjọ́ nbọ nígbàtí a o mu ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, nígbàyí, wọn yio gbàwẹ̀. 21 Kòsí enìkan tí nran aṣọ titun mọ́ ẹwu tí ó ti gbó, bíbẹ́ẹ̀kọ́, aṣọ titun tí a rán yio ya kúrò lára ti àtijọ́, yio si ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. 22 Kòsí ẹnìkan tí nfi wáìnì titun sínú awọ wáìnì àtijọ́, bíkòsebẹ wáìnì náà yio bẹ́ awọ ti wáìnì àti awọ wáìnì yio sì sègbé pọ̀. Dípòo bẹ́ẹ̀, fi wáìnì titun sínú awọ wáìnì titun." 23 Ní ọjọ́ ìsinmi, Jésù nkọjá larin àwọn oko ọkà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ si nre orí ọkà. 24 Àwọn Farisí sì wí fún pe, "Kíyèsíi, kí ni ó dé tí wọn nfi se èyí tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi?" 25 Ó sì wí fun wọn pé, "Ẹ̀yin kò tí ka ohun tí Dáfídì se nígbàtí ó se aálaìní tí ebí sì npa á,- oun pẹ̀lú àwọn okùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ- 26 bí ó ti wọ ilé Ọlọ́run nígbàtí Ábíátárì nse olú àlùfáà, ó sì jẹ àkàrà pẹpẹ, èyí tí kò bá òfin mu fún ẹnikẹ́ni láti jẹ àfi àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.?" 27 Jésù wípé, "Ọjọ́ ìsinmi wà fún ènìyàn, kìí se ènìyàn fún ọjọ́ ìsinmi." 28 Nítorínáà, Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa, àní ti ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lu.