Orí Kìnńí

1 Ìwé ìrandíran Jésù Krístì Ọmọ Dáfídì, Ọmọ Ábráhámù. 2 Ábráhámù ni bàbá Ísákì, Ísákì sì ni bàbá Jákóbù, nígbàtí Jákóbù jé bàbá Júdà àti àwọn arákúnrin rẹ̀. 3 Júdà ni bàbá Pẹ́rẹ́sì àti Ṣérà ti Rámà bí fún un; Pérésì ni bàbá Héṣrónì; Héṣrónì sì ni bàbá Rámà. 4 Rámà ni bàbá Ámínádábù, Ámínádábù ni bàbá Násónì, Násónì si ni bàbá Sálímónì 5 Sálímónì ni bàbá Bóásì tí Ráhábù bí fún un; Bóásì ni bàbá Óbédì ti Rúùtù bí, Óbédì si ni Bàbá Jéésè. 6 Jéésè ni bàbá Dáfídì Ọba, Dáfídì ni bàbá Sólómónì tí ìyàwó Ùráyà bí fún un. 7 Sólómónì ni bàbá Rèhóbóámù, Rèhóbóámù ni bàbá Ábíjàh, Ábíjàh ni bàbá Asà, 8 Asà ni bàbá Jèhósáfátì, Jèhósáfátì ni bàbá Jórámù, Jórámù ni bàbá nla Úṣṣáyà. 9 Úṣṣáyà ni bàbá Jórámù, Jórámù ni bàbá Áhásì, Áhásì ni bàbá Hesikáyà. 10 Hesikáyà ni bàbá Mánásè, Mánásè ni bàbá Ámónì, Ámónì ni bàbá Jòsáyà. 11 Jòsáyà ni bàbá Ńlá fún Jekonáyà àti àwon arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkónilerú lọ sí Bábílónì. 12 Lẹ́yìn ìkónilerú lọ si Bábílónì, Jekonáyà ni bàbá Shéáltíelì, Shéáltíelì sì ni bàbá Ńlá fún Ṣèrúbábélì. 13 Ṣerubábélì ni bàbá Ábíúdì, Ábíúdì ni bàbá Élíákímù, Élíákímù sì ni bàbá Ásórì. 14 Ásórì ni bàbá Ṣádókù, Ṣádókù ni bàbá Ákhímù, Ákhímù ni bàbá Élíúdì. 15 Élíúdì ni bàbá Élíáṣárì, Élíáṣárì ni bàbá Mátthánì, Mátthánì ni bàbá Jákọ́bù. 16 Jákọ́bù ni bàbá Jósẹ́fù ọkọ Màríà tí ó bí Jésù tí a ńpè ní Krístì. 17 Gbogbo Ìran, láti Ábráhámù wá sí Dáfídì jẹ́ ìran mẹ́rìnlá, láti ọ̀dọ̀ Dáfídì títí dé àsìkò ìkónilẹ́rú lọ sí Bábílónì jẹ́ ìran mẹ́rìnlá, àti àsìkò ìkónilẹ́rú lọ sí Bábílónì títí àsìkò Krístì jẹ́ ìran mẹ́rìnlá. 18 Báyìí ni ìbí Jésù Krístì se sẹlẹ̀. Màríà jẹ́ aya àfẹ́sọ́nà fún Jósẹ́fù, sùgbón, kí wọn kí ó tó má gbé papọ̀, a ri wípé Màríà ní oyún láti ipasẹ̀ Ẹ̀mí mímó. 19 Ọkọ rẹ̀, Jósẹ́fù, olódodo ènìyàn, kò fẹ́ láti dójú tìí ní gbangaba. Nítorínáà, o pinnu ní ìkọ̀kọ̀ láti fi òpin sí àdéhùn ìfẹ́ tí ó wà láàrin wọn. 20 Bí ó ti ń ro ńkàn yìí nínú ọkàn rẹ̀, Ángélì Olúwa kan yọ si ní ojú àlá, wípé: "Jósẹ́fù, Ọmọ Dáfidì, máse kọminú láti gba Màríà gẹ́gẹ́bí aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀, oyún Ẹ̀mí Mímó ni. 21 Yóò sì bí ọmọkùnrin kan, Jésù ni ìwọ yóò pe orúkọ rẹ̀, nítorítí yóò gba àwon ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú àwon ẹ̀sẹ̀ wọn. 22 Gbogbo ǹkan wònyí sẹlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìmúsẹ ọ̀rọ̀ Olúwa láti ẹnu wòlíì Áísáyà, wípé: 23 "Kíyèsi, wúndíá náà yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, Ìmmánúélì ni won yóò pe orúkọ rẹ̀" - ìtumọ̀ èyí ti n se: "Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa." 24 Jósẹ́fù jí ni ojú oorun rẹ̀, ó sì se bí Ángẹ́lì Olúwa ti paaláse fún un, ó sì gbá Màríà gẹ́gẹ́bí aya rẹ̀. 25 Ṣùgbọ́n kò ní ìbálòpò pẹ̀lú rẹ̀ títí ó fi bí àkọ́bí ọmọkùnrin. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.