1
Jákọ́bù, ìránsẹ́ Ọlọ́run àti ti Olúwa Jésù Krístì, sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́nká: mo kíi yín.
2
Ẹ̀yin ará mi, nígbàtí ẹ bá ń la onírúruú inúnibíni kọjá, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀,
3
Ẹ mọ̀ wìpé ìdánwò ìgbàgbó yín ń mú ìfaradà wá.
4
Ẹ jẹ́ kí ìfaradà parí isẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó le dàgbà ní ẹ̀kúnrẹ́ré àti odidi, kí ẹ má ṣe aláìní ohunkóhun.
5
Ṣùgbọ́n tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá nílò ọgbọ́n, kí ó bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, tí ó ún fún ni yàfùnyàfuǹ, àti lai bá àwọn tí ó béérè wí, yóò sì fi fún un.
6
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó bèèrè pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì ohunkóhun. Nítorí ẹni tí ó bá ṣiyèméjì dàbi ẹ̀fúùfù òkun tí afẹ́fẹ́ ń gbé káàkiri.
7
Kí ẹni náà má ṣe rò wípé òhun yóò rí ohunkóhun gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
8
Irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ oníyè méjì, aláìnídúró ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.
9
Jẹ́ kí òtòṣì arákùnrin ṣògo nínú ipò gíga rẹ̀,
10
sùgbọ́n ọlọ́rọ̀ nínú ipò ìrẹ̀sílẹ̀ rẹ̀, nítorí yóò kọjá lọ gẹ́gẹ́bí ìtànná koríko ìgbẹ́.
11
Nítorí òòrùn ń ráǹ pẹ̀lú ooru iná tí ó ń jó, ó sì ń mú kí àwọn koríko gbẹ. Òdòdó já lulẹ̀, ẹwà rẹ̀ sí ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọlọ́rọ̀ yóò parẹ́ ní àárín gbùgbùn ìrìn àjò rẹ̀.
12
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó fi ara da ìdánwò. Nítorí lẹ́yìn tí ó bá yege ìdánwò, yóò gba adé ìyè, tí a ti sèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run.
13
Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá ń la ìdánwò kọjá, Kí ó máṣe sọ wípé "Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò," nítorí a kò le fi ibi dán Ọlọ́run wò, Òun tìkalára Rẹ̀ kìí si dán ẹnikẹ́ni wò.
14
Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ọkaǹ olúkúlùkù a máa dán an wò, ó sì máa ń fàá kúrò, sí ìtànjẹ.
15
Tí ìfẹ́kùfẹ́ bá lóyún, a máa bí ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ̀ṣẹ̀ bá sì dàgbà tán, a máa bí ikú.
16
Kí á má ṣe tàn yín ẹ̀yin ará mi olùfẹ́.
17
Gbogbo ẹ̀bùn rere àti ẹ̀bùn tí ó péye wá làti òkè. A máa sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba ìmọ́lẹ̀. Pẹ̀lú rẹ̀, kò sí àyídá- yidà tàbí ìyí ọkàn padà.
18
Ọlọ́run yàn láti fún wa ní ìbí nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́, kí á le jẹ́ irúfẹ́ èso àkọ́so láàrín ohun gbogbo tí Ó dá.
19
Ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: kí olúkúlùkù kí ó yára láti gbọ́ ọ̀rọ̀, kí ó lọ́ra láti fèsì, kí o sì lọ́ra láti bínú.
20
Nítorí ìbínú ènìyàn kìí mú òdodo Ọlọ́run ṣẹ.
21
Nítorínà, ẹ gbé gbogbo ẹgbin ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, àti ọ̀pọ̀ ibi. Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sínú yín, tí ó sì lè gba ọkàn yín là.
22
Ẹ jẹ́ olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kí ẹ má se tan ara yín jẹ nípa jíjẹ́ olùgbọ́ nìkan.
23
Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ nàá, tí kò sì jẹ́ olùṣe, ó dà bí ọkùnrin tí ó ń wo ara rẹ̀ nínú dígí.
24
Ó wo ara rẹ̀, ó sí kọjá lọ, lọ́gán ó sì gbàgbé bí òun ti rí.
25
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó farabalẹ̀ wo òfin òmìnira pípé, tí ó sì ń tẹ̀ síwájú láti ṣe é, tí kò sì jẹ́ olùgbọ́ nìkan tí ń gbàgbé, yóò di alábùkún fún nínú àwọn ìṣe rẹ̀.
26
Tí ẹnikẹ́ni bá ro ara rẹ̀ bí olùfọkansìn, ṣùgbọ́n tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn rẹ̀, ìfọkànsìn rẹ̀ sì jẹ́ aláìnílárí.
27
Ìsìn tí ó mọ́, tí kò sì ní àbàwọ́n níwájú Ọlọ́run wa àti Bàbá ni èyí: láti ran aláìníbaba àti àwọn opó lọ́wọ́ nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní àbàwọ́n nínú ayé yìí.