Orí Kínní

1 Pọ́ọ̀lù, àpọstélì - àpọstélì tí kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn tàbí nípasẹ̀ ẹnikẹ́ni, bíkòṣe nípasẹ̀ Jésù Krístì àti Ọlọ́run Baba, tí Ó jí I dìde kúrò nínú àwọn òkú - 2 àti gbogbo àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi, sí àwọn ìjọ Gàlátíà: 3 Ore ọ̀fẹ́ àti àláfíà fún yín láti ọ̀dọ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Krístì Ọlọ́run, 4 ẹni tí ó fi ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ẹ̀sẹ̀ wa kí ó le gbàwá lọ́wọ́ ìgbà búburú yìí, ní ìbáámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run Baba wa, 5 tirẹ̀ ni ògo láí àti láíláí. Àmín. 6 Ìyàlẹ́nu lójẹ́ fún mi pé ẹ̀yin ń tètè yí padà kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ Krístì. Ìyàlénu lójẹ́ fún mi pé ẹ̀yín ń yí sí ìhìnrere mìíràn. 7 Èyí kìí ṣe láti sọ wípé ìhìnrere mìíràn wà, ṣùgbón àwọn ènìyàn kan wà tí ó ń yọ yín lẹ́nu tí wọ́n sìí fẹ́ láti yí ìhìnrere ti Krístì padà. 8 Kódà bí ó bájẹ́ àwa tàbí ángẹ́li kan láti ọ̀run ló bá kéde ìhìnrere míràn fún yín tí ó yàtọ̀ sí èyí tí a ti kéde fún yín, jẹ́ kí ó dí ẹni ìfiré. 9 Bí a ti ṣe sọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ni mo tún sọ fún un yín nísinsìnyí, "bí ẹnikẹ́ni bá kéde ìyìnrere tí ó yàtọ̀ sí èyí tí ẹ gbà, kí ódi ẹni ìfiré." 10 Ǹjé èmi ń wá òùntẹ̀ ti ènìyàn tàbí tí Ọlọ́run bí? Njẹ èmi ń wá láti tẹ́ ènìyàn lọ́rùn bí? Tí èmi bá sì ń wá láti tẹ́ ènìyàn lọ́rùn, èmi kìí ṣe ìránsẹ́ ti Krístì. 11 Nítorí mo fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ìhìnrere tí mo ń kéde kìí ṣe ìhìnrere ti ènìyàn. 12 Èmi kò gbàá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ni akò kọ́ mi. Ṣùgbọ́n, ójẹ́ nípa ìfihàn ti jésù krístì sími. 13 Ẹ ti gbọ́ nípa ìgbé ayé mi ti tẹ́lẹ̀ nínú ẹ̀sìn Jùú, bí mo ṣe ń ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run gidigidi tí mo sì ń gbìyànjú láti pa á run. 14 Mo tayọ nínú ẹ̀sìn Júù ju àwọn tí ó jẹ́ ọjọ orí kan náà pẹ̀lú mi, láti àárín àwọn ènìyàn mi. Bí mo ṣe jẹ́ alákatakítí tó nìyẹn fún àṣà àwọn baba ńlá mi. 15 Ṣùgbọ́n nígbàtí Ọlọ́run, tí ó ti yàmí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pèmí nípasè ore ọ̀fẹ́ Rẹ̀, 16 tí ṣe inú dídùn láti fi Ọmọ Rẹ̀ hàn nínú mi, kí èmi o le kéde rẹ̀ láàrín àwọn Kèfèrí, emí kò bá ẹran ara àtí ẹ̀jẹ̀ gbèrò papọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 17 Èmi kò gòkè lọ sí Jerusálémù sọ́dọ̀ àwọn tí ó ti di àpọ́stélì síwájú mi. Dípò bẹ́ẹ̀ mo lọ sí Arébíà mo sì padà sí damáskù. 18 Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, èmí lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ mọ Kẹ́fásì èmí síì wá pẹ̀lu rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún. 19 Ṣùgbọ́n Èmi kò rí ọ̀kankan nínú àwọn àpóstélì yókù lẹ́yìn Jákọ́bù arákùnrin ti Olúwa. 20 Nínú ohun tí mo kọ síi yín, mo ń fi dá yín lójú níwájú Ọlọ́run, pé èmi kò pa irọ́. 21 Nígbà náà ni mo lọ sí ìgbèríko ti Síríà àti Sílísíà. 22 Èmi tìkaraà mi kò tíì di mímọ̀ fún àwọn ìjọ Jùdíà tí ó wà nínú krístì. 23 Wọ́n kàn gbọ́ bí a tí nsọ ọ́ ni, "Arákùnrin tí ó ń gbógun tì wá nígbàkanrí tí waá ń kéde ìgbàgbọ́ eléyìí ti òun tìkararẹ̀ ti gbìyànjú láti parun nígbàkanrí." 24 Nítorí náà wón fi ògo fún Ọlọ́run nítorí mi.