1
Nítorí ìdí èyí, èmi Pọ́ọ̀lù, ẹlẹ́wọ̀n Jesù Krístì ni mí fún àwọn Kèfèrí
2
Mo lérò wípé ẹ ti gbọ́ nípa ìrìjú ti ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi nítorí tiyín.
3
Mo ń kọ̀wé gẹ́gẹ́bí ìfihàn tí a mú kí n mọ̀. Èyí ni òtítọ́ tí ó pamọ́, tí mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín ní kía.
4
Nígbàtí ẹ bá ka èyí, yóò le yé yín, òye ti mo ní nípa òtítọ́ tí o pamọ́ nípa Krístì.
5
Ní àwon ìran míran, òtítọ́ yìí kò di mímọ̀ sí àwọn ọmọ ènìyaàn. Sùgbọ́n nísinsìnyí, ó ti di fífihàn nípa Ẹ̀mí sí àwọn àpòstélì àti wòólì tí a yà sọ́tọ̀ fún isẹ́ yìí.
6
Òtítọ́ tí ó pamọ́ yìí ni wípé, àwọn kèfèrí pẹ̀lú àwọn ajogún àti àwọn akẹgbẹ́, àti pé wọ́n pín nínú ìlèrí tí ó wà nínú Krístì Jésù nípa ti ìhìnrere náà.
7
Nítorí mo di ìránsẹ́ ìhìnrere nípa ẹ̀bùn ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi nípa isẹ́ agbára Rẹ̀.
8
Ọlọ́run fún mí ní ẹ̀bùn yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ó kéré jù nínú àwon ènìyàn, Ọlọ́run, mímọ́. Ẹ̀bùn yìí ni wípé, mo gbọ́dọ̀ kéde ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ìhìnrere Krístì sí àwon Kèfèrí.
9
Ẹ̀bùn Ọlọ́run fún mi ní wípé n gó mú ẹnìkọ̀kan wá sínú ìmọ́lẹ̀ ohun tí ète Ọlọ́run jẹ́. Ète yìí tí wà nínú ìpamọ́ láti aìmoye ọdún sẹ́yìn nípa Ọlọ́run tí ó dá ohun gbogbo.
10
Ète yìí ni a sọ di mímọ̀ nipaseẹ̀ ìjọ, kí àwọn ìjoba àti alásẹ ní àwọn ọ̀run leè mọ̀ irúfẹ́ ìsẹ̀dá ọgbọ́n Ọlọ́run.
11
Èyí sẹlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ète ayérayé tí ó di mímúse nínú Krístì Jésù Olúwa wa.
12
Nítorí nínú Krístì a ní ìgboyà àti ọ̀nà pẹ̀lú ìkiniláyà nítorí ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀,
13
Nítorínáà, mo béèrè wípé kí ẹ máse rẹ̀wẹ̀sì nítorí, ohun tí mo ńjìyà fún yín, èyí tí íse ògo yín.
14
Nítorí ìdí èyí, mo wà lórí orúnkún mi sí Baba.
15
Láti ọ̀dọ̀ ẹnití a ti sọ gbogbo ìdílé ní Ọ̀run àti ní aye ní orúkọ.
16
Mo gbàdúrà pé kí O fifún yín gẹ́gẹ́bí ọrọ̀ ògo Rẹ̀, kí ó fún yín ní okun pẹ̀lú agbára nípa Ẹ̀mí Rẹ̀ tí ó wà nínú yín.
17
Mo gbàdúrà kí Krístì lè gbé nínú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́, pé kí ẹ lè ta gbòngbò mọ́lẹ̀, kí á sì gún yín kúnná nínú ìfẹ́.
18
Kí ó fún yín ní ọkun, kí òye kí ó leè yé yín pẹ̀lú gbogbo àwọn onígbàgbọ́, kí ni fífẹ̀, gígùn, gíga, àti jíjìn
19
Àti pé kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ ìfẹ́ Krístì tí ó tayọ ìmọ̀, àti wípé kí á lè fún yín pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run.
20
Ǹjẹ́ nísinsìnyí, sí ẹnití ó lè se gidigidi ju ohun gbogbo tí a nbéèrè, tàbí tí a ń rò, gẹ́gẹ́bí agbára tí ó ńsisẹ́ nínú wa
21
Ohun ni ògo wà fún nínú ìjọ àti nínú Krístì Jésù sí gbogbo ìrandíra laí àti laílaí, àmín.