Orí Kejì

1 Sùgbọ́n nípa ti yín, ẹ̀yin ti kú nínú ẹsẹ àti ìrékojá yín. 2 Nínú ẹ̀sẹ̀ àti ìrékojá wọ̀nyí ni ẹ ń gbé gẹ́gẹ́bí ìse ti ayé yǐ. Ẹ̀yin ńgbé ayé gẹ́gẹ́bí fún alákoso àti àwon alásẹ òfúrufú, èmi náà tí ńsisẹ́ nínú àwọn ọmọ aláìgbọràn. 3 Nígbà kan rí, gbogbo wa n gbé láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí, nípa mímú ìfẹ́ burúkú ti ẹ̀dá ẹ̀sẹ̀ wá sí síse, àti láti máa mú ìfẹ́ ti ara àti ti ọkàn wá sí ìmúsẹ. Nípa ìsẹ̀dá ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́bí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn. 4 Sùgbọ́n Ọlọ́run nínú ọrọ̀ àánú Rẹ̀, àti nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ títóbi, tí ó fi fẹ́ wa. 5 Nígbàtí a ti kú nínú ìrékojá ó mú wa wà láàyè papọ̀ nínú Krístì, nípa ore ọ̀fẹ́ a gbà yín là. 6 Ọlọ́run jí wa dìde papọ̀ pẹ̀lú Krístì, Ọlọ́run sí mú wa jókò papọ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Krístì Jesu. su. 7 Ki o ba le jẹ́ wípeeé ni ayé ti ḿbọ̀, kí òhun kí ó leè fihàn wa , ọrọ̀ àánú Rẹ̀ tí ó tóbi láìlósùnwọ̀n ore ọ̀fẹ́ tí ó ti sọ nípa inú rere Rẹ̀ sí wa nínú Krístì Jésù. 8 Nítorí nípa ore ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là, nípa ìgbàgbọ́, èyí kò sì ti ọ̀dọ̀ yín wá, ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ni. 9 Ore ọfẹ́ kò ti ipa isẹ́ wá nítorináà ẹnìkan kò leè sògo. 10 Nítorí isẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ ni wá, tí a dá nínú Krístì Jésù láti se isẹ́ rere tí Ọlọ́run se èètò fún láti ọjọ́ tó ti pẹ́ fún wa, kí àwa kí ó lè rìn nínú won. 11 Nítorínaáà ẹ rántí wípé nígbàkan rí, ẹ jẹ́ kèfèrí nínú ara. A pè yín ní "aláìkọ̀là" nípa ohun tí a pè ní "ìkọ̀là" nínú ara tí a se nípa ọwọ́ ènìyàn. 12 Ní ìgbànáà ẹ wà ní ìyapa pẹ̀lú Krístì. Ẹ jẹ́ àlejò sí àwọn ara Isrẹlì. Ẹ jẹ́ àlejò sí majẹ̀mu náà tí a ti se ìlérí. Ẹ kò ní ìrètí kan fún ọjọ́ ọ̀la, Ẹ sì wà láìní Ọlọ́run nínú ayé. 13 Sùgbọ́n nísinsìnyí nínú Krístì Jésù ẹ̀yin tí ó ti jìnnà réré nígbàkanrí sí Ọlọ́run, ẹ̀jẹ̀ Jésù ti mú yín wá sí ìtòsí. 14 Nítorí ohun ni àláfìa wa. Ó ti sọ àwon mejèjì di ẹyọkan, nípa ara Rẹ̀, ó ti wó ògiri ìkórira, ìsọ̀tá tí ó pín wa níyà. 15 Èyí ní wípé, ó pa òfin, àsẹ àtọwọ́dọ́wọ́ run kí ó ba lé ọ̀tá okùnrin titun kan nínú ara Rẹ̀, kí ó ba le se aláfìa. 16 Krístì se ìlàjà àwọn ènìyàn sínú ara kan sí Ọlọ́run nípasẹ̀ àgbèlébù, ó ti pa ìkórira. 17 Jésù wá, ó polongo àlàfia fún ẹ̀yin tí ó wà ní ọ̀nà jíjìn réré àti àláfià fún àwọn tí ó wà ní ìtòsí. 18 Nítorí nípasẹ̀ Jésù, gbogbo wa ni ọ̀nà sí ipa ẹ̀mí kan sí ọdọ Baba. 19 Nítorínáà nísinsìnyí, ẹ̀yin Kèfèrí kìí se àlejò àti àjèjì mọ dipo bẹ́ẹ̀ ẹ ti di ọmọ ìbílẹ̀ kanna pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ àti ọmọ agbo ile Ọlọ́run. 20 A ti kó yin lé orí ìpìlẹ̀ àwọn Aposteli àti àwọn wóòli, ati Kristi Jesu funrarẹ si ni okuta igun ilé. 21 Nínú Rẹ gbogbo ilé ẹ di ara won papo, o si n dagba gẹ́gẹ́bí Tẹ́mpìlì nínú Oluwa. 22 Nínú Rẹ̀ ni a ti ń kọ́ ẹ̀yín pẹ̀lú papo gẹ́gẹ́bí ibùgbé fún Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí.