Orí Kìńní

1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́stélì Krístì nípa ìfe Ọlọrun, pè̩lú Tímótíù arákùnrin wa, 2 sí àwo̩n ènìyaǹ mímó̩ O̩ló̩run àti àwo̩n ará olóòtọ́ọ́ ninu Kristí ti wón wà ní Kólósè. Kí oore-ò̩fé̩ wà fún yín àti àlááfíà láti ò̩do̩ O̩ló̩run Bàbá wa 3 Àwá fi o̩pé̩ fún O̩ló̩run, Bàba Jésù Krístì Olúwa wa, bákannaa ni à ń gbàdúrà fún yín nígbà gbogbo. 4 Àwá ti gbọ́ nípa ìgbàgbó yín nínú Krístì Jésù àti nípa ti ìfẹ́ tí ẹ̀yín ní sí gbogbo àwọn ènìyaǹ mímọ́ O̩ló̩run. 5 Ìfẹ́ yìí ni ẹ̀yín ní nítorí ìrètí tí ó wà ní ìpamọ́ fún yín ní ọ̀run. Ẹ̀yin ti kọ́kọ́ gbọ́ sáájú nípa ìrètí yìí nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, àní ìyìnrere, 6 èyítí ó tọ̀ yín wá. Ìyìnrere yìí ń so èso bẹ́ẹ̀ni ó sì ń gbilẹ̀ si ní gbogbo àgbáyé. Bákanńà ni ó sì ń dàgbà nínú yín pẹ̀lú láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́ tí ẹ sì ti kọ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ O̩ló̩run nínú òtítọ́. 7 Eléyìí sì ni ìyìnrere náà bí ẹ̀yin ti kọ́ láti ọ̀dọ Ẹpáfrà, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa ọ̀wọ́n, ẹnití ó tún ṣe ìránṣẹ́ tòótọ́ ti Kristi ní ipò àwatìkárawa. 8 Ẹpáfrà si ti sọ ìfẹ́ tí ẹ̀yin ní nínú Ẹ̀mí di mímọ̀ fún wa. 9 Nítorí ìfẹ́ yìí, àwa ko dáwọ́ àdúrà dúró lórí yín. Àwa sí ti ń béèrè pé kí á fi ìmọ̀ ìfẹ́ Rẹ̀ kún yín nínú gbogbo ọgbọ́n àti òye ohun Ẹ̀mí. 10 Àwá sí tí ń gbàdúrà pé ẹ̀yin yó rìn ní pípé nínú àwọn ọ̀nà tí ó mú inú Ọlọ́run dùn. Àwa ti ń gbàdúrà pé ẹ̀yin yó so èso rere nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹ̀yin yó dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run. 11 Àwa gbàdúrà pé kí á fi okun fún yín ní ipá gbogbo gẹ́gẹ́bí agbára ògo Rẹ̀ sínú ìfàyàrán àti sùúrù. 12 Àwá gbàdúrà pe ẹ̀yin yóò fi ayọ̀ fi ọpẹ́ fún Baba, ẹnití Ó ti mú yín ní ìpín nínú ogún ìbí àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run nínú ìmọ́lẹ̀. 13 Ó ti gbàwá lọ́wọ́ ìjẹgàba òkùnkùn bẹ́ẹ̀ni Ó fiwá sọwọ́ sínú ìjọba Ọmọ Rẹ̀ ọ̀wọ́n, 14 nínú ẹnití àwá ní ìgbàlà, àti ìdáríjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wá. 15 Òun sì ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò rìí, àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá. 16 Nítorí nínú Rẹ̀ lati ṣẹ̀dá ohun gbogbo, àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ ní ayé, àwọn ohun tí à ń rí àti àwọn ohun tí a kò rí. Yálà àwọn ìtẹ́ tàbí àwọn ìjẹgàba tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn agbára, ohun gbogbo ní a dá nípasẹ̀ Rẹ̀ àti fún-Un. 17 Òun tìkálára Rẹ̀ wà ṣaájú ohun gbogbo, nínú Rẹ̀ ní ohun gbogbo ṣọ̀kan. 18 Òun ni orí fún ara, àní fún ìjọ. Òun ni ìpilẹ̀sẹ̀ àti àkóbí nínú àwọn òkú, nítorínà ni Ó ṣe ní ipò ìṣaájú nínú ohun gbogbo. 19 Nítorí ó wu Ọlọ́run pé kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Òun máa gbé inú Rẹ̀, 20 àti láti ṣe ìbálàjà ohun gbogbo sọ́dọ̀ ara Rẹ̀ nípasẹ̀ Ọmọ. Ọlọ́run ṣe ètò àlááfìa nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ àgbélébùú Rẹ̀. Ọlọ́run ṣe ìbálàjà ohun gbogbo sọ́dọ̀ ara Rẹ̀, yálà àwọn ohun tí ń bẹ ní ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ ni ọ̀run. 21 Ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àlejó sí Ọlọ́run àti ọ̀tá nígbàkan rí nínú ọkàn yín àti nínú àwọn ìṣe búburú yín. 22 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí Òun ti ṣe ìbálàjà fún yín nípaṣẹ ikú Rẹ̀. Òun ṣe èyí láti mú yín wá síwájú Rẹ̀ ní mímọ́, àìlábàwọ́n àti àìlábùkù, 23 bí ẹ̀yin bá tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́, ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti ìdúróṣinṣin, láì yọ ẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ìyìnrere tí ẹ ti gbọ́. Èyí ni ìyìnrere tí a ti kéde fún gbogbo ènìyàn lábẹ́ ọ̀run. Eléyìí ni ìyìnrere tí èmi, Pọ́ọ̀lù, jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ́. 24 Nísinsìnyí èmi ń yọ̀ nínú àwọn ìjìyà mi fún yín, àti pé èmi fi ara mọ́ ìjìya Krístì tí ó kù nítorí ara Rè, eléyìí tí ṣe ìjọ̀. 25 Nítorí ti ìjọ ni èmi ṣe jẹ́ ìránṣẹ́, gẹ́gẹ́bí ojúṣe tí a fi fún mi sí yín láti ọ̀dọ Ọlọ́run wa, láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ. 26 Èyí ni ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ayérayé àti láti ìrandíran, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ati fihàn fún àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run. 27 Àwọn ní Ọlọ́run fẹ́ láti fi ìjìnlẹ̀ ọrọ̀ ògo Rẹ̀ hàn fún láàrin awọn Kèfèrí, eléyìí tí ṣe Krístì nínú yín, ìrètí ògo. 28 Àwa ń wàásù Rẹ̀, àwá ń kìlọ̀ fún a sì ń kọ́ olúkúlúkù nínú ogbọ́n gbogbo, kí á lè mú olúkúlùkù wa ní pípé nínú Krístì. 29 Fún ìdí èyí ni èmi ń ṣiṣẹ́ tí mo sì ń làkàkà nípasẹ̀ okun tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú mi nínú agbára.