Orí Kìńní

1 Pọ́ọ̀lù, àpóstélì Krístì Jésù gẹ́gẹ́ bi òfin Ọlórun Olùgbàla wa àti Krístì Jésù ìgbẹ́kẹ́lé wa, 2 sí Tímótíù, omọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́: Ore-ọ̀fẹ́, àánú ati àláfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Krístì Jésù Olúwa wa. 3 Dúró sí Éfésù kí o lè máa pàṣẹ fún àwọn ènìyàn kan, kìí wón máṣe kọ́ ìlànà tí ó yàtọ̀ sí bí moti kọ́ ọ nígbàtí mò ń tẹ̀síwájú lo sí Masidóníà. 4 Bákanáà kí wọn máse fiyèsí àwọn ìtàn àti àwọn ìtàn ìrandíran tí kò lópin. Àríyànjiyàn asán ni eléyìí má ńfà dípo kí ó ran ètò Ọlọ́run lọ́wọ́, tíí ṣe nípa ìgbàgbọ́. 5 Nísinsìyí, ìfojúsùn ti òfin yìí ni ìfẹ́ láti inú ọkàn tòótọ́, láti inú ẹ̀rí-ọkàn tó péye àti láti inú ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn. 6 Àwọn ẹlòmíràn ṣìnà, wọ́n sì ti yà kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí sínú sísọ ọ̀rò òmùgọ̀. 7 Wọ́n fẹ́ jẹ́ Olùkọ́ òfin náà ṣùgbọ́n wọn kò ní òye ohun tí àwọn tìkarawon ńwí tàbí ohun ti wọ́n gbàgbó. 8 Ṣùgbọ́n àwá mọ̀ pé òfin dára bí abá ṣe àmúlò rẹ̀ ní ọ̀nà tí ó bá òfin mu. 9 Àwa mọ èyí pé, a kòṣe òfin fún àwọn olótǐtọ́ ènìyàn, bíkòse fún àwọn aláìlófin àti àwọn aláìgbọràn, fún àwọn aláìwàbí Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àti fun àwọn aláìlọ́lọ́run, àti alágàbàgebè. Asé é fún àwọn tí ó pa bàbá àti ìyá won, àwọn apànìyàn, 10 Fún àwọn aláìlemáradúró, onísekúse, àwọn ajínigbé ṣẹrú, fún òpùrọ́, fún àwọn ajẹ́rìí-èké àti ohunkóhun tí ó lòdì sí ìlànà tí ó tọ́. 11 Àwọn ìlànà yìí ń tẹ̀lé ìyìnrere ti Ọlọ́run olùbùkún nínú èyí tí a gbélé mi lọ́wọ́. 12 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Krístì Jésù Olúwa wa, ti ó ró mi lágbára, torí ó kàmí yẹ gẹ́gẹ́bi olódodo, Ó sì fi mi sínú iṣẹ́ rẹ̀. 13 Èmi nígbàkan rí jẹ́ asọ̀rọ̀ọ̀dì, aṣekúpani àti oníjàgídíjàgan ènìyàn, sùgbọ́n, èmí rí àánú gbà nítorí èmí hùwà àìmọ̀kan yi nínú àìgbàgbọ́. 14 Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ore-ọ̀fẹ́ Olúwa kún àkúnwọ́sílẹ̀ àtí ìfẹ́ tí ó wà ninú Krístì Jésu. 15 Ìyìnrere yìí seé gbáralé, ósì yẹ fún gbígbà, pé, Jésù Krístì wá sáyé láti wá gba ẹlẹ́sẹ̀ là, mo sì jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ jùlọ. 16 Ṣùgbọ́n fún ìdí èyí morí àánú gbà, pé nínú mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀, Krístì Jésù leè ṣàfihàn gbogbo ìrẹ̀lẹ̀. Ósì ṣe èyí gẹ́gẹ́ bíi àpẹrẹ fún àwon ti yóò gbẹ́kẹ̀ wọn lée fún ìyè ayérayé. 17 Nísinsìnyí sí ọba ayérayé, Ẹni àìdibàjẹ́, Ẹni àìrì, Ọlọ́run kanṣoṣo, nikí ọlá àti ògo ye títí láí àti láíláí. Àmín. 18 Òfin yìí ni mofi fún ọ, Tímótíù ọmọ mi, ní ìbamu pẹ̀lú ìsotẹ́lẹ̀ èyí tí ati sọ nípa rẹ tẹ́lè, pé, kí ìwọ leja ìjà rere náà, 19 di ìgbàgbọ́ ati ẹ̀rí ọkàn tòótọ́ mú. Ní kíkọ èyí, àwọn kán ti pàdánù ìgbàgbọ́ wọn. 20 Àwọn ènìyàn bi Hímánéusì àti Alẹsándérù, tí mo fàlé Sàtánì lọ́wọ́ kí wọ́n leè kẹ́ẹ̀kọ́ láti máa sọ̀rọ̀ òdì.