Orí Kìnńí

1 Pọ́ọ̀lù, ìránsẹ́ Krístì Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, sí àwọn ènìyàn, Ọlọ́run, mímọ́ tí ó wà ní Éfésù, tí won se olóòtọ́ nínú Krístì Jésù. 2 Ore ọ̀fẹ́ sí yín àti àláfià láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa Jésù Krístì. 3 Kí Ọlọ́run àti Baba Jésù Krístì Olúwa gba ògo, ẹnití ó ti bùkún wà pẹ̀lú gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí nínú àwọn ọ̀run nínú Krístì. 4 Ọlọ́run yàn wa nínú rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé, pé kí àwa lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlàbúkù níwájú rẹ̀. 5 Ọlọ́run yàn wá síwájú àkókò fún ìsọdọmọ láti jẹ́ ọmọ nípasẹ̀ Jésù Krístì, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú rere ti ifẹ́ Rẹ̀ 6 Ìsọdọmọ wa yọrí sí ìyìn ògo ore - ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tí ó fi fún wa lọfẹ nínú Ẹnití ó fẹ́ràn. 7 Nínú Jésù Krístì àwá ni ìràpadà nípa ẹ̀jẹ̀ àti nípa ìdáríjìn ẹ̀sẹ̀ wa gbogbo nípa ọ̀rọ̀ ore ọ̀fẹ́ Rẹ̀. 8 Ó tú ore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ lé wa lórí pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti òye. 9 Ọlọ́run sọ di mímọ́ fún wa, ète ìfẹ́ Rẹ̀ ti o wà nínú ìpamọ́ gẹ́gẹ́bí ohun tí o wù ún, ti o si ti se àfihàn rẹ̀ nínú Krístì, 10 Pẹ̀lú èròngbà láti pinnu fún kíkún àkókò, láti mú ohun gbogbo papọ̀, tí ḿbẹ ní ọ̀run àti ní ayé lábẹ́ Krístì ti i se Orí. 11 Nínú Krístì a yàn wá láti jẹ́ ajogún. Ati se ìpinnu síwájú àkókò gẹ́gẹ́bí ète Rẹ̀, ẹnití o se ìgbéjáde ohun gbogbo gẹ́gẹ́bí ìpinnu ìfẹ́ Rẹ̀. 12 Ọlọrun yàn wa gẹgẹbí ajogún ìrètí nínú Krístì, kí àwa ba leè jẹ́ ìyìn ògo Rẹ̀. 13 Nínú Krístì, ẹ̀yin pẹ̀lu, nígbàtí ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtìtọ́, ìhìnrere ìgbàlà náà, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, a sì fi Ẹmi Mimo ti a sèlèrí se èdìdí yín. 14 Ẹnití o se ìdánilojú ogún tí a jẹ títí ìgbà tí a ó fi ogún náà sí abẹ́ ìsàkoso wa sí ìyìn ògo Rẹ̀. 15 Fún ìdí èyí, láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ yín nínú Olúwa Jésù àti ìfẹ́ yín fún gbogbo àwon ènìyàn mímọ́. 16 N kò tíì dẹ́kun láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run bí mo se n dárúko yín nínú àwon àdúrà mi. 17 Mo ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run Olúwa wa Jésù Krístì, Baba ògo, kí ó fún yín ní ẹ̀mí Ọgbọ́n àti ìfihàn ninú ìmọ̀ òun tìkálára Rẹ̀. 18 Mo gbàdúrà kí ojú inú ọkàn yín kí ó lè gba ìtúnríran, ki eyin kí ó lè mọ ìdánilójú ìrètí tí ó ti fi pè yín sí àti ọrọ̀ náà, ti ogún tí ó ni ògo láàrin àwon ènìyàn mímọ́. 19 Nínú àdúrà mi, mo béèrè wípé kí ẹ̀yin kí ó lè mọ títóbi agbára Rẹ̀ tí kó ní òsùnwọ̀n nínú àwa tí ó gbàgbọ́ gẹ́gẹ́bí síse isẹ́ títóbi nípa okun Rẹ̀. 20 Èyí ni òduwọ̀n agbára kannà tí Ọlọ́run fi sisẹ́ nínú Krístì, nígbàtí Ó jíi dìde nínú àwọn òkú tí ó sì mú kí ó jòkó ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ nínú àwon ọ̀run. 21 Ó mú kí Krístì jòkó rékọjá gbogbo ìsàkoso àti àsẹ àti agbára, àti ìjọba àti orúkọ kórukọ́ tí a lè dá. Krístì yóò se àkoso, kìí se ní ayé yìí nìkan ṣùgbọ́n, kódà ní ayé tí ḿbọ̀ pẹ̀lú. 22 Ọlọ́run fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ Krístì, Ó sì fi I fún ìjọ gẹ́gẹ́bí Orí ohun gbogbo. 23 Ìjọ jẹ́ ara Rẹ̀, kíkún ẹnití ó kún ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.