1
Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ tí ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí, ayọ̀ mi àti adé mi, báyìí ni kí ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Olúwa, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n.
2
Mò ń rọ Éúódíà, mo sì ń bẹ Síńtíkè, ẹ ní ọkàn kan náà nínú Olúwa.
3
Bẹ́ẹ̀ sì ni mò ń rọ ìwọ náà pẹ̀lú, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi tòótọ́: ran àwọn obínrin wọ̀nyí lọ́wọ́. Nítorí wọ́n ṣe làálàá pẹ̀lú mi fún ìtànkálẹ̀ ìhìnrere pẹ̀lú Klẹ́mẹ́ńtì àti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi yòókù tí orúkọ wọn wà nínú Ìwé Ìyè Náà.
4
Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbàgbogbo. Lẹ́ẹ̀kansíì màá tún sọ pe, ẹ máa yọ̀.
5
Ẹ jẹ́ kí ìwàpẹ̀lẹ́ yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Olúwa wà nítòsí.
6
Ẹ má ṣe káyàsókè nítori ohunkóhun. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú àdúrá áti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ọpẹ́, ẹ sọ ẹ̀bẹ̀ yín di mímọ̀ fún Ọlọ̀run,
7
àlàáfíà Ọlọ́run tí ó tayọ gbogbo òye yíò sì pa àwọn ọkàn àti àwọn èrò yín mọ́ nínú Krístì Jésù.
8
Níparí, ẹ̀yin ará mi, àwọn ohunkóhun yówù tí ó jẹ́ òtítọ́, àwọn ohunkóhun yówù tí ó lọ́lá, àwọn ohunkóhun yówù tí ó tọ́, àwọn ohunkóhun yówù tí ó mọ́, àwọn ohunkóhun yówù tí ó wuni, àwọn ohunkóhun yówù tí ó ní ìròyìn rere, bi ohunkóhun bá pegedé, bi ohunkóhun bá yẹ fún ìyìn, ẹ máa ronú lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí.
9
àwọn nǹkan tí ẹ ti kọ́ tí ẹ sì ti gbà, tí ẹ ti gbọ́ tí ẹ sì ti rí nínúù mi, ẹ máa ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, àlàáfíà Ọlọ́run yíó sì wá pẹ̀lú yín.
10
Mo yọ̀ gidigidi nínú Olúwa nítorí nísinsìnyí, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹ ti sọ àníyán yín fún mi dọ̀tun. Lóòótọ́ ni ọrọ mí ti ká yín làra tẹ́lẹ, ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfàní láti ṣe ìrànlọ́wọ́.
11
Èmi kò sọ èyí nítorí pé mo ṣe aláìní. Nítorí mo ti kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínu ipòkípò tí mo bá wà.
12
Mo mọ ohun tí ó pè fún láti ṣe àìní, bẹ́ẹ̀ sì ni mo mọ ohun tí ó pè fún láti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ní gbogbo ọ̀nà àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ bí a ṣe ń jẹ àjẹyó tàbí bí a ṣe ń wà lébi, bí a ṣe ń wà nínú ọ̀pọ̀ tàbí bí a ṣe ń ṣe aláìní.
13
Mo lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Ẹnití ó fi okun fún mi.
14
Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ ṣe dáadáa láti nawọ́ sí mi nínú ìṣòro mi.
15
Ẹ̀yin ará Fílípì mọ̀ pé, ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìhìnrere, nígbàtí mo kúrò ní Masidóníà, ìjọ kankan kó kún mi lọ́wọ́ níti fífúnni àti gbígbà bíkòṣe ẹ́yin níkan.
16
Kódà nígbàtí mo wà ní Tẹsalóníka, ẹ fi ìrànwọ́ ráńṣẹ́ láti mójúto àìní mi ju ẹ̀ẹ̀kan lọ.
17
Kìíṣepé mò ń wá ẹ̀bùn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, mò ń wá àlékún èso fún un yín.
18
Mo ti gba gbogbo àwọn nǹkan náà, mo sì ní ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Mo ti ní ànító. Èpáfródítu ti fi àwọn nǹkan tí ẹ fi rán an jíṣẹ́ fún mi. Wọ́n jẹ́ ọrẹ olóòórùn-dídùn, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì wu Ọlọ́run.
19
Ọlọ́run mi yíò bá gbogbo àìní yín pàdé ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ Rẹ̀ nínú ògo nínú Krístì Jésù.
20
Ǹjẹ́ nísinsìnyí ògo ni fún Ọlọ́run àti Bàbá wa láí àti láíláí. Àmín.
21
Ẹ kí olúkúlúkù onígbàgbọ́ nínú Krístì Jésù. Àwọn arákùnrin tí wọ́n wà pẹ̀lú mi ń kí yín.
22
Gbogbo àwọn onígbàgbọ́ níbí ń kí yín, pàápàá jùlọ àwọn ará ilé Késárì.
23
Kí oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jésu Krístì wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmin.