1
Pọ́ọ̀lù àti Tìmótíù, àwọn ìráńṣẹ́ Krístì Jésù, sí gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ nínú Krístì Jésù tí wọ́n wà ní Fílípì, pẹ̀lú àwọn alábójútó àti àwọn díákónì.
2
Oore-ọ̀fẹ́ fún yín àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Bàbá wa àti Olúwa wa Jésù Krístì.
3
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín.
4
Ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń gbàdúrà fún gbogbo yín, tayọ̀tayọ̀ ni mo fi ń gbàá.
5
Mo dúpẹ́ fún bí ẹ ti ṣe alábàpiń nínu ìhìnrere náà láti ìbẹ̀rẹ̀ títí di ìsinsìnyí.
6
Mo ní ìgboyà ohun kan yí, pé Ẹnití ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín yíò tẹ̀síwájú láti yanjú rẹ̀ títí di ọjọ́ Jésù Krístì.
7
Ó yẹ kí n ní ìmọ̀lára yìí nípa gbogbo yín nítorí mo fi yín sọ́kàn. GBogbo yín ti jẹ́ alábàápín oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú mi nínú ìgbèkún mi, nínú àwíjàre mi àti nínú ìfìdímúlẹ̀ ìhìnrere.
8
Ọlọ́run mọ̀ bí ọkàn mi ṣe ń pòǹgbẹ fún gbogbo yín pẹ̀lú ìkáànú Krístì Jésù.
9
Àdúrà mi nì yí: pé kí ìfẹ́ yín le máa gbilẹ̀ síi nínú ìmọ̀ àti gbogbo òye.
10
Mò ń gbàdúrà yí kí ẹ̀yin kí ó le ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ó yege, kí ẹ sì wà ní àìní àbùkù kankan lọ́jọ́ Krístì.
11
Mo gbàdúrà pé kí á fi èso òdodo tí ó wá láti ipasẹ̀ Jésù Krístì kún un yín, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.
12
Ǹjẹ́, ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ti mú kí ìhìnrere gbilẹ̀ síi.
13
Nítorí ìdí èyí, ó ti di mímọ̀ fún gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti àwọn yókù pé mo jẹ́ òǹdè fún Krístì.
14
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará ni wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run síi nítorí ìdè mi tí wọ́n sì ní ìgboyà láti sọ ọ̀rọ̀ náà.
15
Nítòótọ́ àwọn kan ń kéde Krístì pẹ̀lú owú àti ìlara, àti àwọn míran pẹ̀lú inú-rere.
16
Àwọn wọ̀nyí ń ṣe é pẹ̀lú ìfẹ́, wọ́n mọ̀ pé a pè mí kí n wá wíjọ́ nítorí ìhìnrere ni.
17
Ṣùgbọ́n àwọn tọ̀hún ń kéde Krístì nínú ìlépa-taraẹni-nìkan ni, kìí ṣe nínú òtítọ́. Wọ́n rò pé àwọn yóò pa mí lára nígbàtí mo wà nínú ìdè.
18
Kí ló tún kù? Kìkì i pé ní gbogbo ọ̀nà, bóyá pẹ̀lú ìdíbọ́n àbí pẹ̀lú òtítọ́, Krístì di kíkéde, èyí sì fún mi láyọ̀. Bẹ́ẹ̀ni, èmi yóò sì yọ̀,
19
nítorí mo mọ̀ pé èyí yóò yọrí sí ìdáǹdè mi nípa àdúrà yín àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Jésù Krístì.
20
Nípasẹ̀ àfojúsùn mi àti ìrètí tí ó dájú wípé ojú kì yóò tì mí rárá, pẹ̀lú gbogbo ìgboyà, nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ pe, a ó gbé Krístì ga lára mi, ní yíyè tàbí ní kíkú.
21
Nítorí fún mi láti wà láàyè jẹ́ fún Krísti láti kú sì jẹ́ èrè.
22
Ṣùgbọ́n bí mo bá wà láàyè, ó túmọ̀ sí iṣẹ́ tó léso fún mi. Síbẹ̀ èwo ni kí n yàn? N kò tilẹ̀ mọ̀.
23
Méjéèjì ń ṣe kámikàmìkámi. Ó wù mí kí n kú kí n le wà pẹ̀lú Krístì, èyí tí ó sàn jù,
24
síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì kí n wà láàyè nítorí tiyín.
25
Pẹ̀lú àrídájú ohun kan yìí, mo mọ̀ pé èmi yóò wà pẹ̀lú yín síi fún ìtẹ̀síwájú yín àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́.
26
Kí ẹ̀yin kí ó lè ní ìdí síi láti yangàn nínú Krístì Jésù láti ipasẹ̀ mi nígbàtí mo bá tún tọ̀ yín wá.
27
Kìkì pé kí ẹ̀yin kí ó má gbé ìgbé-ayé yín ní ìbámu pẹ̀lú ìhìnrere Krístì, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bóyá mo wá wò yín tàbí n kò wá, èmi yóò lè máa gbọ́ nípa yín, pé ẹ̀ ń dúró ṣinṣin pẹ̀lú ẹ̀mí kan, ẹ sì ń lépa papọ̀ fún ìgbàgbọ́ ìhìnrere náà pẹ̀lú ọkàn kan.
28
Ẹ máṣe jẹ́ kí àwọn alátakò yín kí ó da jìnnìjìnnì bò yín bí tií wulẹ̀ kó mọ. Èyí jẹ́ àmì fún wọn fún ìparun wọn, ṣùgbọ́n fún ìgbàlà yín - láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì ni èyí.
29
Nítorí a ti fi fún un yín, nítorí Krístì, kì í ṣe láti gbà á gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí Rẹ̀ pẹ̀lú,
30
kí ẹ̀yín kí ó ní ìlàkọjá kan náà tí ẹ rí tí mo ní, tí ẹ sì gbọ́ tí mo ń sọ nísinsìnyí.