Orí Kìíní

1 Póólu, ìránsẹ́ Ọlọ́run àti àpóstélì Jésù Krístì, fún ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí a yàn àti ìmọ̀ òtítọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìwà-mímọ́, 2 pẹ̀lú ìgboyà iyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run, tí kìí parọ́, ti se ìlérí sáájú ki ayé tó bẹ̀rẹ̀ . 3 Ní àkókò tí ó tọ́, ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó fi rán mi hàn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ láti jísẹ́. Ó yẹ kí n se èyí nípa àsẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa. 4 Sí Títù, ọmọ tòotú nínú ìgbàgbọ́ wa. Ore-òfẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Krístì Jésù Olùgbàlà wa. 5 Nítorí èyí ni mo se fi yín sílẹ̀ ní Crétì, pẹ́ kí ẹ lọ to oun gbogbo tí ó nílò àtúntò àti kí ẹ yan alàgbà ní gbogbo ìlú bí mo se rán yín. 6 Alàgbà gbọ́dọ̀ wà ni àìlẹ́bi, ọkọ aláya kan, pẹ̀lú àwọn ọmọ olọ́tìtọ́ tí a kò dá lẹ́bi ìwà búburú tàbí àìlẹ́kọ̌. 7 Ó pọn dandan fún alámòjútó náà, gẹ́gẹ́ bí olùsọ́ ilé Ọlọ́run, kó wà láì lẹ́bi. Kò gbọdọ̀ jẹ́ aláriwo tàbí aláìkóra-ẹniní-ìjánu . Ko gbodo yara lati maa binu, ko gbodo mu oti waini pupo, ko gbodo feran wahala, ati ko gbodo je wobia okunrin. 8 Dípò, kí ó jẹ́ ẹni tí ó kónimọ́ra, ọ̀rẹ ohun dáradára. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ọlọgbọ́n, olódodo, ìwà-bí- Ọlọ́run àti ìkóra ẹni ní ìjánu. 9 Kí ó di Ọ̀rọ̀ òtítọ́ tí a kọ́ ọ mu shinshin, kí ó ba lè gba àwọn tí ó kù ní ìyànjú pẹ̀lú ìkọ́ni dáradàra àti pẹ̀lú kí ó bá àwọn tí ó lòdì síi wí. 10 Nítorí àwọn ènìyàn tí ó ní agídí pọ̀, paapa àwọn ti ìkọlà. Ọ̀rọ̀ wọn já sí asán. Wọn ń tan àwọn ènìyàn wọn sì ń darí wọn ní ọ̀nà tí kò tọ̀. 11 Ó pọn dandan láti dá wọn lẹ́kun. Wọ́n ń kọ́ oun tí kò yẹ nítorí èrè àìtọ́ wọ́n sì ń da ilé rú. 12 Ọ̀kan nínú wọn, ọkùnrin ọlọgbọ́n wọn, ó wípé, " Àwọn ará Kritani ń parọ́ nígbàgbogbo, wọ́n jẹ́ ẹranko búburú, ọ̀lẹ alájẹkì." 13 Ọ̀rọ̀ yí jẹ́ òtítọ́, nítorínà bá wọn wí gidigidi kí wọ́n le yè koro nínú ìgbàgbọ́. 14 14 Ẹ máse fi ọkàn sí ẹ̀kọ́ asán ti àwọn Ju tàbi òfin àwọn ènìyàn tí wọ́n yí padà kúrò nínú òtítọ́. 15 Fún àwọn tí ó mọ́, ohun gbogbo ní ó mọ́. Sùgbọ́n sí àwọn tí a sọ di ẹlẹ́gbǐn àti aláìgbàgbọ́, kò sí ohun tí ó tọ́. Nítorí inú wọn àti ẹ̀rí-ọkàn wọn ni a sọ di ẹ̀gbin. 16 Wọ́n jẹ́wọ́ pé wọ́n mọ Ọlọ́run, sùgbọ́n wọ́n sẹ́ ẹ nípa ìse wọn. Wọ́n jẹ́ ẹni-ìríra àti aláìgbọ́ràn. A kò sì fi òùntẹ̀ lù wọ́n fún isẹ́ rere.