Ori Kẹrìndínlògùn

1 Mò fi ará bìnrin Phóébè wa hàn yín, ẹni tín ṣe ìránṣẹ́ ìjọ tí ó wà ni Cẹnchìrérì, 2 nítorí kí ẹ ba lè gbà á nínú Olúwa. Ẹ ṣe èyí ní ọ̀nọ̀ tí ó yẹ àwọn onígbàgbọ́ kí ẹ sì dúró tìí ní gbogbo ọ̀nọ̀ tí òun kì yo bá nílò ìrànlọ́wọ́ yín. Nítorí òun tìkararẹ̀ bàkan náà ti di ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀, àti sí èmi pẹ̀lú. 3 Ẹ kí Prìscíllà ati Àkuílà, alabaṣiṣẹpọ mi nínu Krístu Jésù, 4 ẹni tí nítorí ẹ̀mí ì mi fi ẹ̀mi i wọn wéwu. Mo dúpẹ́ lówọ́ wọn, kì í sì ṣe èmi nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ìjọ ti Kèfèrí 5 Ẹ kí ìjọ tí ó wà ní inú ilé wọn. Ẹ kí Èphrétù àyànfẹ́ mi, ẹni tí ó jẹ́ àkọ́so Ásíà sí Krístì. 6 Ẹ ki Màríà, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ kárakára fún yín. 7 Ẹ kí Andrónícúlùsì àti Jùnáìsì, ìyekanǹ mi àti ará mi nínú ìdè. Wọ́n ṣe pàtàkì láàrín àwọn àpóstélì. tí wọ́n sì wà pẹ̀lú Krístì sìwàju mi. 8 Ẹ kí Amphilátùsì, àyànfẹ́ mi nínú Olúwa. 9 Ẹ kí Úbánì, alábàṣiṣẹ́pọ̀ wa nínu Krístì, àti Stákì, àyànfẹ́ mi. 10 Ẹ kí Ápéllè, ẹni tí á fọwọ́sí. Ẹ kí àwọn tí ó wà nínu agbolé Àrístóbúlù. 11 Ẹ kí Héródíónì, ìyekanǹ mi. Ẹ kí àwọn ti agbolé Nárkíssù, tí ó wà nínú Olúwa. 12 Ẹ kí Trifẹ́nà àti Trifósà, tí wọ́n ṣiṣẹ́ takuntakun nínú olúwa.Ẹ kì Pérsì olùfẹ́,tí ón ṣe lǎlá nínú olúwa. 13 Ẹ kí Rúfù tí a yàn nínú olúwa àti ìya rẹ̀ àti tèmi. 14 Ẹ kí Asinkrítù, Flégónì,Hérmà, Pátróbà, Hérmè, àti àwọn arakùnrin tí ó wà pẹ̀lu wọn. 15 Ẹ kí Fílógù,àti Jùlía,Nèréú,àti àwọn arabìnrin rẹ̀, àti Òlímpà,àti,gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lu wọn. 16 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Gbogbo ìjọ Krístì kí yín. 17 18 Ará èmí sì bẹ̀ yín, ẹ má ro àwọn ohun tín se ìyapa àti ohun tí mún ìkọṣẹ̀ wá, wọ́n tako àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́,ẹ yà kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nítorí àwọn tí wọ́n rí bẹ̀ kò sin Jésù Krístì Olúwa wa, bíkòse ikùn ara wọn; ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ díduǹdídùn ni wọ́n fi ńpa àwọn aláìmọ̀nkan. 19 Nítorí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ yín tàn kálè dé ibi gbogbo.Nítorínà mo ní ayọ̀ lórí yín; sùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n sí ohun rere kí ẹ sì jẹ́ òpè sí ohun búburú. 20 Ọlọ́run àláfíà yóò sì tẹ sátánì mọ́lẹ̀ ní abọ́ àtẹ́lẹsẹ́ yín ní lọ́lọ́.Ki Oreọ̀fé Jésù Krístì olúwa .kí ó pẹ̀lú yín. 21 Tímótìù alabásiṣẹ́ mi ,àti Lúkíù àti Jáṣónì, àti Sosipàtérù,àwọn ìbátan mí n kí yín. 22 Èmi, Tértíù tí ńkọ Èpístélì yí, kí yín nínú olúwa. 23 Gáíù bǎlẹ̀ mi àti gbogbo ìjọ,kí yín. Érástù, olùtọ́jú ìsúra ìlú, kí yín, àti Kúárátù arákùnrin. 24 Kí oreọ̀fẹ́ Jésù Krístì Olúwa wa pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín. 25 Ǹjẹ́ fún ẹnití ó lí agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìhínrere mi àti ìwásù Jésù Krístì, gẹ́gẹ́ bí ìsípayá ohun ìjìnlẹ̀, tí a pamọ́ láti ìgbà aíyérayé. 26 Tí a si fihàn nísisìyí, àti nípa ìwé minọ́ àwọn wòlí,gẹ́gẹ́bí òfin ọlọ́run aíyérayé tí a fihan fún gbogbo oríle èdè sí ìgbóràn ìgbàgbọ́. 27 Sí Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n nìkansoso nípasè Jésù Krístì ni ògó wà fún láíláí. Àmín.