Orí Kẹẹ̀dógún

1 Nísinsínyí ó yẹ kí àwa tí a jẹ́ alágbára máa faradàá fún àìlera àwọn tí ó jẹ́ aláìlera, kí á má sì se ohun tí ó wu ara wa. 2 Jẹ́kí olúkúlùkù wu ọmọnìkejì rẹ̀ fún èyí tí ó dára, láti leè jẹ́ kí ó dàgbà sókè. 3 Nítori Krístì kò wu ara Rẹ̀. Dípòbẹ́ẹ̀, ó wà bí a ti kọ̀wé e rẹ̀, "Èébú àwọn tí ó bú u yín subú lé mi lórí." 4 Nítori ohun tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípa sùúrù àti ìmúnilọ́kànle ti ìwé mímọ́, àwa yóò ní ìgboyà. 5 Nísinsìnyí kí Ọlọ́run tí ń fún ni ní sùúrù tí ó sì ń múnilọ́kànle, mú kí ẹ wà ní ọkàn kan pẹ̀lú ara yín gẹ́gẹ́ bí i Krístì Jésù. 6 Kí Ó se èyí kí ẹ̀yin kí ó le è fi ọkàn kan pẹ̀lú ẹnu ǹ kan yin Ọlọ́run àti Bàbá Olúwa wa Jésu Kristì. 7 Nítorínáà, ẹ gba ara yín, gégé bí krístì ti gbà yín pẹ̀lù, fún ògo Ọlọ́run. 8 Nítori mo wípé, a ti sọ Krístì di ẹrú ìkọlà nípasẹ̀ òtítọ́ Ọlọ́run, kí á le è fi ìdí ìlérí tí a fifún àwọn bàbá múlẹ̀, 9 àti pé kí àwọn Kèfèrí le yin Ọlọ́run lógo fún àánu Rẹ̀. Ó wà bí a ti kọ́, "Nítorínà ni Èmi yóò yín Ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí, èmi yóò sì kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ." 10 Ó tún wípé, "Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin Kèfèrí, pẹ̀lú àwọn ènìyan Rẹ̀." 11 Àti pẹ̀lú, "Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí; jẹ́kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ń." 12 Ìsáíàh tún wípé, "Gbóńgbò Jéssè kan yóò wà, àti èyí tí yóò dìde láti jọba lórí àwọn Kèfèrí. Àwọn Kèfèrí yóò ní ìgboyà nínú Rẹ̀." 13 Nísinsìnyí kí Ọlọ́run tí ó ní ìgboyà kún yín pẹ̀lú ayọ̀ àti àlàáfìà fún ìgbàgbọ́, kí ẹ̀yin kí ó le è kún fún ìgoyà, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ 14 Èmi tìkaláraà mi ní ìdánilójú nípa yín, ẹ̀yin ará à mi. Mọ ní ìdánilójú pé ẹ̀yin tíkalárayín kún fún ìsore, e kún fún gbogbo ìmọ̀. Mọ ní ìdánilójú pé ẹ̀yin yóò le máa kọ́ ara yín. 15 Ṣùgbọ́n mọ̀ ń fi ìgboyà kọ sí i yín nípa àwọn ohun ǹ kan, láti rán an yín létí lẹ́ẹ̀kan síi,nítorí ẹ̀bùn tí a fifún mi nípasẹ̀ Ọlọ́run. 16 Ẹ̀bùn yí ni pé kí èmi kí ó lè jẹ́ ìránsẹ́ Krístí Jésú tí a rán sí àwọn Kèfèrí, kí á leè fifún gẹ́gẹ́ bí àlúfà ìhìnrere Ọlọ́run. Ó yẹ kí n se èyí kí ẹbọ àwọn Kèfèrí le è jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, tí a yà sọ́tọ̀ nípa Ẹ̀mi Mímọ́ 17 Ìdùnnú mi wà nínú Krístì Jésu àti nínú ohun ti Ọlọ́run. 18 Nítorí èmi kò le è sọ ohunkóhun bíkòse ohun tí Krístì bá se nípasẹ̀ mi fún ìgbọ́ràn àwọn Kèfèrí. Èyí ní àwọn ohun tí à ń se nípa ọ̀rọ̀ àti ìse, 19 nípa agbára àmì àti ìyanu, apti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Kí ó baà lẹ jẹ́ pé láti Jerúsálẹ́mù, àti yípo títí tí ó fi dé Ìllyrícúmù, Mo lè wàásù ìhìnrere ti Krístì. 20 Ní ọ̀nà yí, ó wù mí kí n lè kéde ìhìnrere, ṣùgbọ́n kìí se ibi tí a ti mọ́ orúkọ Jésù,kí èmi kí ó má baà kọ́ lórí ìpìlè ẹlòmíràn. 21 Ó wà bí a ti kọ́: " Àwọn tí ìró o rẹ̀ kò tọ̀ wá yóò ri, àti pé yóò yé àwọn tí kò tíì gbọ́. 22 Nítorínà, a dí mi lọ́wọ́ lọ́pọ̀ igbà láti wá sọ́dọ̀ yín. 23 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, èmi kò ní ibi kan ní agbègbè yí, mo sì ti ń fẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti wá sọ́dọ̀ yín. 24 Nígbà tí mo lọ Spáìnì, mo fẹ́ lati rí i yín nígbà tí mo bá kọjá, àti pé kí ẹ lè rán mi lọ, nígbà tí èmi bá ti fara mọ́ ọ yín díẹ̀. 25 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo ń lọ sí Jerúsálẹ́mù láti sin àwọn onígbàgbọ́. 26 Nítorí ìfẹ́ inú rere àwọn tí ó wà ní Macedóníà àti Ácháíà láti kó owó jọ fún àwọn tálákà láàrín àwọn onígbàgbọ́ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù. 27 Bẹ́ẹ̀ni, ìfẹ́ inú wọ́n ni, wọ́n sì jẹ́ ajigbèsè wọn nítòótọ́. Nítorí tí àwọn Kèfèrí bá ti pín nínú ohun èmí wọn, wọ́n jẹ́ wọ́n láti sìn wọ́n pẹ̀lú ohun ìní wọn. 28 Nítorínà, nígbàtí mo bá ti parí isẹ́ yǐ, tí mo sì ti mọ̀ dájú pé wọ́n wa ohun tí a gbà, èmi a lọ sí Spáínì màá sì bèyín wọ̀. 29 Mo mọ̀ pé tí mo bá tọ̀ yín wá, èmi yóò wá nínú ẹ̀kún ìbùkún Krístì. 30 Nísinsìnyí mo bẹ̀ yín, ara, pẹ̀lú Olúwa wa Jésù Kristì, àti ìfẹ́ Ẹ̀mi, pé kí ẹ̀yin kó tiraka pẹ̀lú mi nínú àdúrà sí Ọlọ́rún fún mi. 31 Ẹ gbàdúrà kí á gbà mí lọ́wọ́ àwọn aláìgbọràn tí ó wà ní Jùdéà, àti pé kí isẹ́ ìsìn mi kí ó le è jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún àwọn onígbàgbọ́. 32 Ẹ gbàdúrà kí n lè wá sí ọ̀dọ̀ yín pèlú ayọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti kín n lè, pẹ̀lú u yín, rí ìsinmi. 33 Kí Ọlọ́run ore-ọ̀fẹ́ wà pẹ́lú gbogbo yín. Àmín.