Orí Kẹrìnlá

1 Gba ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́aláilágbara nínú ìgbàgbọ́, láì ṣe ìdájọ́nípa àriyànjiyàn. 2 Ẹnìkan ní ìgbàgbọ́láti jẹ ohunkóhun, ẹni tí ó jẹ́ aláìlagbara jẹ ẹ̀fọ́. 3 Kí ẹni tí ó jẹ oríṣiríṣi máse ka ẹnití kò jẹ oríṣiriṣí bí aláìsí; kí ẹnití kò jẹ oríṣíriṣi máṣe ṣe ìdájọ́ ẹnití o jẹ oríṣiríṣi. NÍtorí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́gbàá. 4 Tani ìwọ, tí ó ńṣe ìdájọ́ìránṣẹ́tí ó jẹ́ti ẹlòmíràn? Iwájú ọ̀gá rẹ̀ni ó ti léè dúró tàbí ṣubú. Ṣùgbọ́n a o mu dúró, nítorí Olúwa ní agbára láti lee mu dúró. 5 Ènìyàn kan mú ọjọ́kan se iyebíye ju ọjọ́míràn lọ. Àwọn mìran mú ojojúmọ́bákanna. Jẹ́kí ènìyàn kọ̀ọkan gbàgbọ́nínú ọkàn rẹ. 6 Ẹnití ó kíyèsí ọjọ́, kíyèsi fún Olúwa; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹun, jẹun fún Olúwa, nítorí ó fi ìyìn fún Ọlọ́run. Ẹnikẹ́ni tí kò jẹun, ó dáwọ́ oúnjẹ dúró fún Ọlọ́run, òun paapa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run. 7 Nítorí pé a kò wà láàyè fún ara wa, àtipé a kò kú fún ara wa. 8 Nítorí bí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Olúwa, àti bí a kú, a kú fún Olúwa. Nígbàna bóyá ní yíyè tàbí kíkú, àwa jẹ́ti Olúwa. 9 Ìdí èyí krístì kú ó sì tún wà lááyè, kí ó lè jẹ́ Olúwa àwọn òkú àti àwọn alàyè. 10 Ṣùgbọ́n ìwọ, kíni ìdí tí ìwọ fi ńdá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́? Àti ìwọ̀, kíni ìdí tí ìwọ fi ńkẹ́gàn arákùnrin rẹ? Nítorí gbogbo wa ní yoo dúró ní iwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. 11 Nítorí ati kọ́, "BÍ mo se wà láàye," ni Olúwa wí." Sí mi gbogbo éèkùn yoo wólẹ̀, àti gbogbo ahán ni yoo fi ìyìn fun Ọlọ́run." 12 Nítorínáà, olúkúlùkù ni yóò jíyìn iṣẹ́ohun tìkárarẹ̀fún Ọlọ́run. 13 Nítorínà kí a má se da ara wa lẹ́jọ́, ṣùgbọ́n dípo èyi pinnu, pé ẹnikẹ́ni ki yoo fi ohun ìkọ̀ṣẹ̀ tàbí ìdẹkùn fún arákùnrin rẹ̀. 14 Mo mọ̀pe a yí mi lọ́kàn pádà nínu Jésù Olúwa, pe ohunkohun kíì se àìmọ́nípaṣẹ̀ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n fun un ẹnití ó ronú pé ohunkóhun kò jẹ́mímọ́, síi kò jẹ́mímọ́. 15 Bí ó bá jẹ́nítorí oúnjẹ ni arákùnrin rẹ fi ní ìfarapa, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́mọ́. Máse run ẹnití krístì kú fún nípa oúnjẹ rẹ 16 Nítorí náà máse jẹ́kí ohun tí o kà sí ní dídára di ìṣọ̀rọ̀ibi sí. 17 Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì íse nípa oúnjẹ tàbí nípa ohun mímu, ṣùgbọ́n nípa ìṣòdodo, àláfíà, àti ayọ̀ ní inú Ẹ̀mí MÍmọ́. 18 Nítorí ẹnití o ṣìn Krístì ní ọ̀nà yìí, se ìtẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run àti ìfọwọ́sí àwọn ènìyàn. 19 Nítorína, ẹ jẹ́kí a lépa ohun ti àláfíà àti ohun tí ó mú ènìyàn dàgbà. 20 Máse ba iṣẹ́Ọlọ́run jẹ́nítorí oúnjẹ. ohun gbogbo nítòótọ́ni ó mọ́, Ṣùgbọ́n ibi ni fún ẹni tí ó jẹẹ́ti o sì jẹ kí ó kọṣẹ̀. 21 Kò dára láti jẹ ẹran, tàbí láti mu wáìnì, tàbí ohunkohun tí o lè mú arákùnrin rẹ̀kọsẹ̀. 22 Ìgbàgbọ́tí o ní, paámọ́láàrin ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùnkún ni ẹni náà tí kò da ara rẹ̀lẹ́bi nípaṣẹ̀ohun tí ó fọwọ́sí. 23 Ẹnikẹ́nití ó bá se iyèméjì ti dá ara rẹ̀lẹ́bi tí ó báá jẹ́, nítorí kìí se láti inú ìgbàgbọ́. Àti ohunkóhun tí kò bá wá láti inú ìgbàgbọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni.