Orí kejìlá

1 Mo bẹ̀yín nítorinà, arákùnrìn, pẹ̀lu àánú Ọlọ́run, ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run bi ẹbọ àye, mímọ́, ìtẹ́wọ́gbá sí Ọlọ́run. Èyí ni iṣẹ́ìṣìn yín tí ó mọ́gbọ́nwá 2 Ẹ máse faramọ́ohun ayé yíì, ṣùgbọ́n ẹ yípadà nípa ìṣọdọ̀tun ọkàn yín, se èyí láti mọ ohun tí ó dára, ìtẹ́wọ́gbà, àti pípé ọkàn Ọlọ́run. 3 Mo wí, nítori ore ọ̀fẹ́ tí a fifuń mi, pé ẹnikẹ́ni nínu yín máse rò nípa igbega ara wọn ju bí ó se yẹ kí wọn rò lọ, ṣùgbọ́n, kí wọ́n ronu ní ọ̀nà ọgbọ́n, gẹ́gẹ́bí Ọlọ́run ti fi fún olúkúulùkù ni iye ìgbàgbọ́. 4 Nítorí a ní ọ̀pọlọ̀pọ ẹ̀yà nínu ara, ṣúgbọ́n kíì se gbogbo ẹ̀yà ni ó ní iṣẹ́kan na. 5 Ní ọ̀nà kanaa, àwa ti a jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀jẹ́ ọ̀kan nínu Krístì, àti olúkúlùkù ẹ̀yà sí ara wọn. 6 A ní oríṣiríṣi ẹ̀bùn gẹ́gẹ́bí ore ọ̀fẹ́tí a fi fún wa. Bì ẹ̀bùn ẹlòmíràn bá jẹ́àsọtẹ́lẹ̀, kí ó sé gẹ́gẹ́bi ìwọ̀tún ìgbàgbọ́rẹ̀. 7 Bí ẹ̀bùn ẹlòmíràn bá jẹ́iṣẹ́, jẹ́kí ó se iṣẹ́. Bi ẹlòmíràn bá si ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, jẹ́kí ó kọ́ni. 8 Bí ẹ̀bùn ẹlòmíràn bá jẹ́ìgbani níyànjú, jẹ́kí ó gbani níyànjú. Bí ẹ̀bùn ẹlòmíràn bá jẹ́ififúni, jẹ́kí ó se dáradára. Bí ẹ̀bùn ẹlòmíràn bá jẹ́ti ìdarí, jẹ́ kí ó see pẹ̀lu àbójútó. BÍ ẹ̀bùn ẹlòmíràn bá si jẹ́fífi áànú hàn, jẹ́kí ó se pẹ̀lú inú dídùn. 9 Jẹ́kí ìfẹ́ kí ó wà láìsí àgàbàgebè. Kórìra ohun tí ó jẹ́ibi; di èyí tí ó dára mú. 10 Nípa ti ìfẹ́ará, ẹ fẹ́ara yín. Nípa ti ìbu ọlá, ẹ bu ọlá fún ara yín. 11 NÍpa ti ìmẹ́lẹ́, ẹ má se se iyèméjì. Nípa ti ẹ̀mí, ẹní ìtara. Nípa ti Ọlọ́run, sin Ọlọ́run. 12 Ẹ yọ̀nípa ìgboyà tí ẹ ní fún ọjọ́iwájú. Ẹ ní sùúrù nínú wàhálà. Ẹ tẹ̀síwájú nínu àdúrà. 13 Pín nínu àìní àwọn onígbàgbọ́. Wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ọ̀nà láti se ìtọ́jú àlejò. 14 Bùkún àwọn tí ó se inúnibíni sí ọ; bùkún máse gégúǹ. 15 Bá àwọn tí ó ńyọ̀yọ̀; sọkún pẹ̀lú àwọn tí ó ńṣukún. 16 Ẹ ní inú kannaa sí ara yín. Máse ronú ní ọ̀nà ìgbéraga, gba àwọn onírẹ́lẹ̀gbọ́. Másè gbọ́ní ìrò inú rẹ. 17 Máse fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni. Ṣe ohun rere ní ojú gbogbo enìyàn 18 Bí ó bá séese, bí ìwọ bá se gbárale, gbé pẹ̀lú àláfíà pẹ̀lu gbogbo ènìyan. 19 Máse gbẹ̀ṣan fúnrarẹ̀rẹ, olùfẹ́, fi àyè sílẹ̀fún ìbínú Ọlọ́run. Nítorí tí a ti kọ́, pe "Tèmi ni ẹ̀san, èmi yoo sán, ni Olúwa wí." 20 Ṣùgbọ́n bí ebi bá ńpa ọ̀tá rẹ, fún ní oúnjẹ. Bí òrùngbẹ bá ńgbẹ ẹ́, fún ní omi. Nípa ṣíse bẹ́ẹ̀ìwọ ńda ẹ̀yín iná le ní orí." 21 Máse jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.