Orí Kínǹíí

1 Pọ́ọ̀lù, òǹdè Krístì Jésù àti arákùnrin náà Tímótì, sí Fílímónì, ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n, 2 àti sí Áfíià arábìnrin wa, àti sí Ákkíppúsì ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa àti sí ìjọ tí ńpàdé nínú ilé rẹ̀. 3 Kí oreọ̀fẹ́ kí o bá ọ ati àláfià láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì Olúwa 4 Mo sábà máa ńdúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi. Mo ńdarukọ rẹ ninú àwọn àdúrà mi. 5 Mo ti gbọ́ nípa ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ ti o ní nínú Krístì Jésù Olúwa, àti sí gbogbo àwọn onígbàgbọ́ 6 Mo gbàdúrà wípé kí ìbásepọ̀ igbàgbọ́ rẹ le jáfáfá fún ìmọ̀ ohun rere gbogbo ti´ ó wà láàrin wà nínú Krístì. 7 Nítorí mo ti ní ayọ̀ àti ìtùnú púpọ̀ nitorí ìfẹ́ rẹ, nítorí ọkàn gbogbo àwọn onígbàgbọ́ ni ó ti di sísọjí nípasẹ̀ rẹ, arákùnrin. 8 Nítorínáà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé mo ní ìgboyà nínú Krístì láti pàsẹ ohun tí ó yẹ kí o se, 9 Síbẹ̀, nítorí ìfẹ́, mo kúkú pàrọwà - Èmi Pọ́ọ̀lù, àgbàlagbà, àti nísinsìnyí, ẹlẹ́wọ̀n fun Krístì Jésù. 12 10 Mo n bi ọ léèrè nípa ọmọ mí, Ónésímù, ẹnití mo se baba fún nínú ẹ̀wọ̀n mi. 11 Nígbàkanrí, kò wúlò fún ọ, sùgbọ́n nísinsìnyí, ó wúlò fún ìwọ àti èmi. Mo ti rán an padà sí ọ, òhun ni ọkàn mi gangan. 13 Ó wùmí kí ó wà ní ọ̀dọ̀ mi; ki o lee ma sisẹ́ fún mi, nígbàtí mo wà nínú ẹ̀wọ̀n nítorí ìyìnrere. 14 Ṣùgbọ́n n kò fẹ́ se ohunkóhun láì tíì gba ìyọ̀nda rẹ. N kò fẹ́ kí ohun rere tí o se kí o di tipátipá, bíkòse tìfẹ́tìfẹ́. 15 Bọ́yá nítorí ìdí èyí ni ó se yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà diẹ, kí iwọ kí o leè tún ní hin padà laílaí. 16 Kii se ẹrú fún ọ mọ́, o sàn ju ẹrú lọ, ẹnití íse olùfẹ́ arákùnrin, pàápàá fún èmi, àní ju bẹ́ẹ̀ lọ fún ọ pẹ̀lú, kódà nínú ara àti nínú Olúwa. 17 Nítorínáà bí ìwọ́ bá gbà mí gẹ́gẹ́bí akẹgbẹ́, gbàá gẹ́gẹ́bí èmi. 18 Bí o bá ti sẹ̀ ọ́, tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohunkóhun, kàá sí mi lọ́rùn. 19 Èmi Pọ́ọ̀lù ni o fi ọwọ ara mi kọwe, emi yoo san an pada fun ọ. N ko fẹẹ sọ fun ọ wipe iwọ funrarẹ jẹ ajigbese si mi. 20 Bẹ́ẹ̀ni, arákùnrin, se ojúrere sí mi nínú Olúwa; fún ọkàn mi ni ìsinmi nínú Krístì. 21 Mo gbẹ́kẹ̀lé ìgbọràn rẹ, mo kọ̀wé sí ọ. Mo mọ̀ wípé oó se ju ohun tí mo béèrè lọ. 22 Bákannáà, sèètò yààrá àlejò mi, nítorí mo ni ìrètí, pẹ̀lú àwọn àdúrà rẹ, a o da mi padà fún yín. 23 Épáfrásì ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú mi nínú Krístì ń ki yín. 24 Bẹ́ẹ̀ ni Máàkù, Árístárkúsì, Déémà, àti Lúùkù, àwọn alábasisẹ́pọ̀ fún mi. 25 Kí oorèọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ, àmín.