Orí Kẹrindinlogun.

1 Nígbàtí ọjọ́ ìsinmi tí kọjá, Màríà Magdalénì àti Màríà ìya Jákọ́bù àti Salomíì mú tùràrí wá kí wón le kun ara Jésù. 2 Ní kété tí ilẹ̀ mó ní ọjó ìkíní ọ̀sẹ̀ wọ́n lọ sí ẹnu ibojì ní kẹ́tẹ́ tí òòrùn yọ. 3 Wọ́n ńbá ara wọ́n sọ̀rọ̀, wípé tani yóò yí òkúta kúrò lẹ́nu ibojì nàà? 4 Nígbàtí wọ́n gbójú wo òkè, wọ́n rí pé a ti yí òkúta náà kúrò, nítorí tí ó tóbi gan. 5 Wón wọ inú ibojì náà, wọ́n sì rí ọmọdékùnrin kan tí ó wọ asọ funfun, jókọ ní ọwọ́ ọ̀tún, ẹnú sì yàwọ́n. 6 Ó wí fún wọn pé , "Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ̀yin ń wá Jésù ará Násárẹ́tì, Ẹni tí a kàn mó àgbélèbú. Ó ti jí dìde. Kòsí ní ìhín. Ẹ wo ibi tí a tẹ́ sí. 7 Sùgbọ́n ẹ lọ, sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti Pétérù pé ó ti síwájú yín lọ sí Gálílì. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ri, bí ó ṣe sọ fún yín." 8 Wọ́n jáde wọ́n sì sá kúrò nínú ibojì náà; ẹ̀rù bà wọ́n, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n kò sọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni nítorítí ẹ̀rù bà wọ́n gidi gan. 9 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ ìkíní ọ̀sẹ̀, lẹ́yìn tí ó ti jí dìde, ó kọ́kọ́ farahàn Màríà Magdalénì, lára ẹni tí ó ti lẹ́ ẹ̀mí èsù méje jáde. 10 Ó lọ sọ fún àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, níbi tí wọ́n tí ń sọ̀fọ̀ tí wọ́n sì ń sọkún. 11 Wón gbọ́ pé ó wà láàyè àti pé ó ti rí i, sùgbọ́n wọn kò gbàgbọ́ 12 Lẹ́hìn ǹkan wọ̀nyí ó farahàn ní orísirísi ọ̀nà fún méjì nínú wọn bí wọ́n sé ń jáde lọ sí inú orílẹ̀ èdè náà. 13 Wọ́n lọ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù, sùgbọ́n wọn kò gbà wọ́n gbọ́. 14 Jésù sì tún farahàn fún àwọn mọ́kànlá bí wọ́n tí ń jẹun lórí tábìlì, ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti líle àyà wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí ó kọ́kọ́ rí i, lẹ́yìn tí ó jí dìde gbọ́. 15 Ó sọ fún wọn pé, "Ẹ lọ sí gbogbo ayé kí ẹ lọ wáásù ìhìnrere fún gbogbo ẹ̀dá. 16 Ẹnikẹ́ni tí ó bà gbàgbọ́ tí a sì baptìstì rẹ̀ ni a ó gbàlà, àti ẹnikẹ́ni tí kò bá gbàgbọ́ a ó dá a lẹ́jọ́. 17 Àmìn wọ̀nyí ni yóò ma bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ: Ní orúkọ mi ni wọn yóò ma lé àwọn ẹ̀mí òkùnkùn jáde. Wọn yóò ma fi èdè titun sọ̀rọ̀. 18 Wọn yóò gbé ejò sókè ní ọwọ́ wọn, bí wọ́n bá mu ohunkóhun tí ó lóró, kì yóò pa wọ́n lára. Wọn yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá. 19 Lẹ́yìn tí Olúwa ti báwọn sọ̀rọ̀ tán, a gbà á lọ sí ọ̀run, ó sì jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 20 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kúrò wọ́n sì ń wásù níbi gbogbo, nígbàtí Olúwa ń bá wọn ṣiṣẹ́, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ nípa iṣẹ́ àmìn tí ó ń tẹlẹ wọn.