Mákùù Orí Kẹẹ̀dógún

1 Ní àárọ̀ kùtùkùtù, àwọn olórí àlúfàà pàdé pẹ̀lú àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé àti gbogbo ìgbìmọ̀ àwọn Júù. Lẹ́yìn náà ni wọ́n so Jésù, wọ́n sì múu lọ. Wọ́n fi lé Pílátù lọ́wó. 2 Pílátù bií, "Sé ìwọ ni ọba àwọn Júù bí?" Ó dáalóhùn, "Ìwọ́ wí." 3 Àwọn olórí àlùfáà ń fi ẹ̀sùn púpọ̀ kan Jésù. 4 Pílátù tún bií léèrè, "Ìwọ kò ní ìdáhùn ni? Wo iye àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ́!" 5 Sùgbọ́n Jésù kò dá Pílátù lóhùn mọ́, èyí sì yàá ní ẹnu. 6 Nísinsnìyí ni àsìkò àsè, Pílátù máa ń fi ẹlẹ́wọ̀n kan lé wọn lọ́wọ́, ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bá béèrè. 7 Ní ibẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́tẹ̀ nínu túbú, láàrin àwọn apànìyàn tí ó lọ́wọ́ nínú ọ̀tẹ̀, ni ọkùnrin tí à ń pè ní Bárábà wà. 8 Àwọn èrò náà wá sí ọ̀dọ̀ Pílátù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi léèrè pé kí ó se oun tí ó tí n se tẹ́lẹ̀ fún wọn. 9 Pílátù dáwọn lóhùn wípé, "Ǹjẹ́ ẹ̀yin fẹ́ kí èmi fi Ọba àwọn Júù lé e yín lọ́wọ́ bi?" 10 Nítorí ó mọ̀ pé àwọn olórí àlùfáà fi Jésù lé òun lọ́wọ́ nítorí owú ni 11 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà ru àwọn èrò sókè láti pariwo pé Baraba ni kí ó fi sílẹ̀ (ẹ̀wẹ̀). 12 Pílátù sì tún dáwọn lóhùn wípé, "Kíni kí èmi kí ó se fún Ọba àwọn Júù nígbànáà?" 13 Wọn sì tún pariwo, "Kàn-án mọ́ àgbélèbú" 14 Pílátù sì wí fún wọn, "Kíni àìda tó se?" Sùgbọ́n wọ́n tún pariwo sókè síi, "Kàn-án mọ́ àgbélèbú." 15 Pílátù fẹ́ tẹ́ àwọn èrò náà lọ́rùn, nítorínà, ó fi Bárábà sílẹ̀ fún wọn. Ósì naa Jésù, lẹ́yìn náà ó fi lé wọn lọ́wọ́ láti kà-án mọ́ àgbélèbú. 16 Àwọn ọmọ ogun sì múu wọ inú ilé ẹjọ (èyí tí ńse olú ilé-iṣẹ́ ìjọba), wọ́n sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun ìyókù 17 Wọ́n fi asọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ọ́, wọ́n sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dée ní orí 18 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí júbà rẹ̀ pé "Ìbà o, Ọba àwọn Júù!" 19 Wọ́n lu orì rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pá wọ́n sì tu itọ́ síi lára. Wọ́n kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ bíì pé wón júbà rè. 20 Nígbàtí wọ́n ti fi se ẹlẹ́yà tán, wọ́n bọ́ asọ ìgúnwà elése àlùkò náà wọ́n sì fi asọ rẹ̀ wọ̀ọ́, wón sì múu lọ láti kàán mọ́ àgbélèbú 21 Wọ́n fi ipá mú ẹnìkan tó n kọjá lọ lẹ́bàá ọ̀nà láti gbé àgbélèbú Jésù, ọkùnrin tí à n pé orúkọ rẹ̀ ní Símónì ará Kírénì, bàbá Alesándérù àti Rúfọ́sì. 22 Àwọn ọmọ ogun náà mú Jésù lọ sí ibi tí à ńpè ní Gọ́lgọ́tà (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ńjẹ́, "Ibi agbárí"). 23 Wọ́n fun ní wáínì tí a pò pẹ̀lú òjìá, ṣùgbọ́n kò muú 24 Wón Kàn-án mọ́ àgbélèbú nígbàtí wọ́n sì sẹ́ gègé láti pín asọ rẹ̀ láàrin ara wọn. 25 Ójẹ́ wákàtí kẹẹ̀ta ọjọ́ nigbàtí wọ́n kà-án mọ́ àgbélèbú 26 Wọ́n kọ ẹ̀sùn rẹ̀ sí orí pátákó kan pé, "Ọba àwọn júù." 27 Wọ̀n kàn-án mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú olè mèjí, ìkan ní ọwọ́ ọ̀tún àti ìkan ní ọwọ́ òsì 28 "Amú ìwé mímọ́ náà ṣẹ pé, 'Akàá pẹ̀lú àwọn arúfin.' 29 Àwọn tó n kọjá lọ búu, wọ́n mi orí wọn wọ́n sì wípé, "Áha! Ìwọ́ tó fẹ́ wó tẹ́mpìlì kí osì tún kọ láàrin ọjọ́ mẹta, 30 gba ara rẹlà ki osì sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbú!" 31 Bàkanáà ni àwọn olórí àlàfáà ńse ẹlẹ́yà rẹ̀ láàrín ara wọn, pẹ̀lú àwọn akọ̀wé, wọ́n sì wípé, "Ó gba àwọn míràn là sùgbọ́n kò lè gba ara rẹ̀. 32 Jẹ́kí Krístì náà, Ọba Ísrẹ́ẹ́lì náà, sọ̀kalẹ̀ nísinsìnyí láti orí àgbélèbú, kí àwá lè ríi, kí à sì gbàgbọ́," àwọn tí a kàn mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú rẹ̀ náà sì kẹ́gàn rẹ̀. 33 Nígbàtí ó di wákàtí kẹfà ọjọ̀, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹẹ̀sán 34 Ní ìgbà tí ó di wákàtí kẹẹ̀sán, Jésù pariwo ní ohùn rara, "Eloi, Eloi, lama sabachthani?" èyí tí ó túmọ̀ sí "Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kílódé tí ìwọ́ fi kọ̀ mí sílẹ̀?" 35 Àwọn tí ó dúró gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n sì wípé, "wòó, óún pe Èlíjà" 36 Ẹnìkan sáré láti fí ọtí kíkan sí orí fùkẹ̀fùkẹ̀, wón fi sí orí ọ̀pá, wọ́n sì fi fun láti mu. Ọkùnrin náà wípé, "Ẹjẹ́ kí á wòó bóyá Èlíjà yó wá múu sọ̀kalẹ̀." 37 Jésù sì kígbe lóhùn rara, ósì kú 38 Asọ ìkéle tẹ́mpílí sì fàya sí méjì láti òkè títí dé ìsàlẹ̀. 39 Nígbàtí Ọ̀gágun ọgọ̀rún tí ó dúró kojú sí Jésù ri pé ó ti kú, ó wípé, "Nítòótọ́, ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yíí." 40 Àwọn obìnirin tí n wò láti ọ̀kánkán wànì ibẹ̀. Nínú wọn ni Maria Magdaleni, Maria (ìya Jákọ́bù kékerè àti Jósè), àti Sàlómì. 41 Nígbàtí ó wà ní Galili, wọ́n tẹ̀le láti sìn. Àwọn obìnrin míràn sì tẹ̀lee wá sí Jerusalemu pẹ̀lú. 42 Nígbàtí alẹ́ dé, nítorípé ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún Sábátì 43 Jósẹ́fù ará Arimatia wá síbẹ̀. Ó jẹ́ ènìyàn pàtàkì nínú ìgbìmọ̀ tó ń dúró de ìjọba Ọlọ́run. Ó lọ sí ọ̀dọ Pílátù pẹ̀lù ìgboyà láti bèrè fún ara Jésù. 44 Ẹnú ya Pílátù pé Jésù ti kú; ó pe ògágun-ọgọ̀rún láti bií bóyá Jésù ti kú. 45 Nígbàtí Pílátù gbọ́ láti ọ̀dọ ọ̀gágun-ọgọ̀rún pé Jésù ti kú, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún Jósẹ́fù 46 Jóséfù sì ti ra asọ dídán kan. Ó gbe sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbú, ó fi asọ náà wée, ó sì tẹ sí inú ibojì tí a ti gbẹ́ nínú àpáta. Nígbà náà, ó yí òkúta sí ẹnu ọ̀nà ibojì náà 47 Maria Magdaleni àti Maria ìya Jósè sì rí ibi tí a sin Jésù sí.