Orí Kẹtàlá

1 Bí Jésù ti ń lọ kúrò ni tẹ́ḿpílì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí fun pé. "Olùkọ́ni, wo òkúta iyebíye àti àwọn ilé iyebíye!" 2 Ó sì sọ fún n wípé, "Ǹjẹ́ ìwọ́ rí àwọn ilé ńlá yìí? Kò sí ọ̀kan nínú àwọn òkúta wọ̀nyí tí yíò dúró lórí ara wọn tí a kò ní dàwó lulẹ̀. 3 Bí ó ti jòkó ní orí òkè Ólífì ní òdìkejì tẹ́ḿpìlì, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù, àti Ándérù bi í léérèè níkọ̀kọ̀ pè, 4 Sọ fún wa, nígbàwo ni àwọn ǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ àmìn nígbàtí àwọn ǹkán wọ̀nyí bá fẹ́ ṣẹlẹ̀? 5 Jésù sí bẹ̀rẹ̀ síí sọ́ fun wọn pé, "Ẹ kíyèsára kí ẹnikẹ́ni máṣe ṣì yiń lọ́nà. 6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóó wàá lórúkọ mì, tí wọ́n yíò sọ pé, 'Èmi ni ẹní nà,' nwọ́n yóò sì ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ́nà. 7 Nígbàtí ẹ̀yin bá ń gbọ́ ìró ogun tàbí àwọn ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun, ẹ máṣe ṣe àníyàn; àwọn ǹkan wọ̀nyí gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kò ì tí dè. 8 Nítorí orílẹ̀èdè yíò dìde sí ara wọn, àti ìjọba lòdì sí ìjọba. Ilẹ̀ ríru yóò wà ní ọpọ̀lọpọ̀ ibi, àti ìyaǹ. Ǹwọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú. 9 Ẹ wà ní ìgbáradì. Nwọn ó jọ̀wọ́ yín fún àwọn ìjòyè, a ó sì nà yín nínú àwọn sínágógù. Ẹ̀yin yóò dúró ní iwájú àwọn gómìnà ati àwọn ọba nítorí mi, bi ẹ̀rí fún wọn. 10 Ṣùgbọ́n a kọ́kọ́ kéde ìhìnrere ní gbogbo orílẹ̀-èdè. 11 Nígbàtí a bá mu yiń tí a sì jọ̀wọ́ yiń lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn oun tí ẹ̀yin yíó sọ. Nítorí ní wákàtí náà, a ó fún yiń ní ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin yóò sọ; ki yíò jẹ́ ẹ̀yin ni yóò sọ̀rọ̀, bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́. 12 Arákùnrin yóò jọ̀wọ́ arákùnrin fún ikú, àti bàbá yóò jọ̀wọ́ ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Àwọn ọmọ yio dìde sí àwọn òbi wọn, nwọn yóò sì sọwọ́n di ẹni tí ikú npa. 13 Gbogbo ènìyàn ni yóò kórira yín nítorí orúkọ mi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forí tì í dópin, ẹni náà yóò yè. 14 Nígbàtí ẹ bá ń rí àwọn ohun ìtìjú tí ó nfa ìdibàjẹ́, tí ó ńdúró níbi tí kò ti yẹ, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Jùdíà sáré lọ sí orí òkè, 15 jẹ́ kí ẹni tí ó wà lórí ilé má ṣe lọ inú ilé tàbí mú ohunkóhun kúrò nínú rẹ̀, 16 ati ẹni ti o wà ní oko máṣe páda wá sí ilé mú aṣọ. 17 Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tó gbé ọmọ àti àwọn tó ńtọ́jú ọmọ ọwọ́ ní àwọn ọjọ́ náà. 18 Ẹ gbàdúra pe kí èyí má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. 19 Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò ti i ṣẹlẹ̀ ri láti àsìkò, ti Ọlọ́run dá ayé, títí di òní, rárá, tàbí tí yóò tùń ṣẹlẹ̀ mọ́. 20 Àyàfi bí Olúwa bá dín ọjọ́ náà kù, kò sí ẹni tí yóò yè. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn àyànfẹ́, àwọn tí ó yàn, ó ti gé àwọn ọjọ́ náà kúrú. 21 Nígbànáà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fùn un yín pé, 'wò ó, èyí ni Krísìtì náà!' Wò ó, níbìyí ló wà! má ṣe gbàágbọ́. 22 Nítorí èké Krístì àti èké wòlíì yóò farahàn, nwọ̀n o si fi àmìn àti iṣẹ́-ìyanu han, láti le tanni, tí ó bá ṣeéṣe, àwọn àyànfẹ́ náà pèlú. 23 Ẹ wà ní ìṣọ́ra! Èmí ti ńsọ ǹkan wọ̀nyí fún yín ṣáájú àkokò náà. 24 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìpọ́njú àwọn ọjọ́ náà, oòrùn yio ṣóòkùn, òṣùpá kì yíò tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, 25 àwọn ìrawọ̀ yio jábọ́ lati òkè, àti àwọn agbára ti o wà lọ́run yíó mì. 26 Nígbànáà ni nwọ́n o rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ǹsọ̀kalẹ̀ láti inú àwọọ́sánmọ̀n pèlú agbára àti ògo. 27 Nígbànáà ni yíò ràń àwọn ángẹ́lì rẹ̀, yio si ko àwọn àyànfẹ́ rẹ lati inú orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti òpin ayé títí dé òpin àwọọ́sánmọ̀n. 28 Kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Ni kété tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti yọ, tí ó rúwé, ẹ̀yin yíó mọ̀ pè ìgbà òjò ti súnmọ́. 29 Bákań náà, nígbàtí ẹ bá ńrí ǹkan wọ̀nyí tí ó ńṣẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pe Ó sún mọ́ etílé, Ó wà nítòsí. 30 Nítòótó, mo sọ fún un yín, ìran yí kò ní kọjá lọ títí gbogbo ǹkan wọ̀nyi yóò fi wá sí ìmúṣẹ. 31 Ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yóò kọjá. 32 Ṣùgbọ́n nípa ọjọ́ náà tàbí wákàtí náà, ẹ́nìkan kò mọ̀, kódà àwọn ángélì, tàbí Ọmọ, bíkòṣe Baba nìkan ní ò mọ̀. 33 Ẹ kíyèsára! Ẹ ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ àkokò tí yíò jẹ̀ ẹ́. 34 Ó dàbí ọkùnrin kan tí ó n lọ sí ìrìnàjò- ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, o si fi ọmọọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe àbojútó ilé rẹ̀, enikọ̀ọ̀kan pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ̀, o si pàṣẹ fún aṣọ́nà kí ó ma sùn. 35 Nítorínà, ẹ kíyèsára nítorí ẹ kò mọ àsìkò tí olórí ilé yóò padà wá ilé; ó le jẹ́ ìrọ̀lẹ́, tàbí ní àárín òru, tabi ní àfẹ̀mọ́jú, tàbí ní òwúrọ̀. 36 Bí ó bá dé lójijì, máṣe jẹ́ kí ó bá ọ nínú oorun. 37 Oun tí mo sọ fún ọ, na ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn. Ẹ ṣọ́nà!"