Orí Kejìlá

1 Nígbànáà ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe kọ́ wọn. Ó wípe, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ilẹ̀ fún ìfúntí wáìnì. Ó kọ́ ilé ìṣọ́, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà. Ó sì lọ sí ìrìnàjò. 2 Lákokò tí ó tọ́, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. 3 Ṣùgbọ́n wọ́n mú u, wọ̀n lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 4 Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú. 5 Ó sì tún rán òmíràn, èyí nì wọ́n sì pa. wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn. 6 “Ó ní ẹnìkan síi láti rán, èyí ni àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn olùṣọ́gbà náà. Ó wípé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’ 7 “Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’ 8 Wọ́n mú ọmọ, wọ́n sì pa á, wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà. 9 Ńjẹ́ kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe? Òun yíò wá láti pa àwọn olùsọ́gbà ni run, òun yóò sì fún àwọn mìíràn ní ọgbà rẹ̀. 10 Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́?  ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé. 11 Èyí wá láti ọdọ̀ Olúwa, ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?” 12 Wọ́n ń wá ọnà láti mú Jesu, ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ. 13 NÍgbànáà ni wọ́n rán àwọn Farisí pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Herodu wá sọ́dọ̀ Jesu, láti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú. 14 Bí wọn ti dé, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Ńjẹ́ ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” Kí àwa kí ó san án, tàbí kí a máa san án? 15 Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn, Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” 16 Wọ́n mú owó idẹ kan fún Jésù. Ó wí fún wọn pé, “Àwòrán àti orúkọ ta ni èyí?” Wọ́n dáhùn pé, “Ti Kesari ni.” 17 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi. 18 Nígbànáà ni àwọn Sadusí, tí ó wípé kò sí àjíǹde, tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n biì léèrè pé, 19 “Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé, 'Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà. 20 Àwọn arákùnrin méje kan wà; èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni arákùnrin kẹta. 22 Àwọn méjèèje kò sì fi ọmọ sílẹ̀, Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. 23 Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?” 24 Jesu wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ tàbí agbára Ọlọ́run? 25 Nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn, ṣùgbọ́n wọn dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. 26 Ṣùgbọ́n nípa àjíǹde tó ti kú, ẹ̀yin kò ì tí ka nínú ìwé Mósè, àkọsílẹ̀ pápá tí ń jó, bí Ọlọ́run se bá Mósè sọ̀rọ̀ tó wípé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù’? 27 Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè. Ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.” 28 Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin wá ó sì fetísílẹ̀ gbọ́ àròyé wọn; ó ṣàkíyèsí pé Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?” 29 Jesu dáhùn ó wípé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ ni, ‘Gbọ́ Ísráẹ́lì; Olúwa Ọlọ́run wa, Olúwa kan ni. 30 Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.' 31 Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bíi ara à rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju èyí lọ.” 32 Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ pé Ọlọ́run kan ni ó wà, àti pé kò sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀. 33 Àti kí a fi gbogbo ọkàn, àti gbogbo òye, àti agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.” 34 Nígbà tí Jesu rí i dájú pé ó ti dáhùn pẹ̀lú òye, Ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnà sí ìjọba Ọlọ́run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jesu. 35 Jesu dáhùn nígbà tí ó ń kọ́ ni nínú tẹ́ḿpílì, ó wípé, “Èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin fi wí pé Kristi ní ọmọ Dáfídì? 36 Dáfídì tìkára rẹ̀, nípa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé, “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.' 37 Dáfídì tìkára rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni Olúwa tún ṣe lè jẹ́ ọmọ Dáfídì?” Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 38 Nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ Jésù wípé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin, tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà 39 àti ibùjókòó ọlá nínú Sínágọ́gù àti ipò ọlá níbi àsè. 40 Wọ́n a tún máa jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àsehàn. Àwọn wọ̀nyí yíò wa ìdálẹ́bi púpọ̀." 41 Jésù sî jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra ní tẹ́ḿpílì; ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra. Opọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. 42 Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀. 43 Ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí fi sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. 44 Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n wá. Sùgbọ́n ní ti opó yǐ, nínú àìní rẹ̀, ó fi gbogbo ohun tí ó ní sílẹ̀.