Orí Kejìdínlógún

1 Ní àkókò náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jésù wọ́n sì wípé, "Taani o tóbijùlọ ní Ìjọba Ọ̀run?" 2 Jésù pe ọmọdé kan sí ọ̀dọ ara rẹ̀, ó gbé e sí ààrin wọn 3 Ó sì wípé "lóòótọ ni mo wí fun yín, bíkòṣe pé ẹ bá yípadà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ kò lee wọ ìjọba òrun rárá." 4 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí omo kékeré yìí ni ó ga jù ní ìjọba ọ̀run. 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ààyè gba omo kékeré kan bí èyí ní orúkọ mi gbà mí. 6 Ṣùgọ́on ẹnikẹ́ni tí ó bá mú kí ọ̀kan nínú àwọn kékeré yìí tí ó gbàgbọ́ nínú mi dẹ́ṣẹ̀, kòbá sàn kì wọ́n so òkúta ọlọ ńlá mọ́ ọ lọ́rùn, kí wọn sì rì í sí ìsàlẹ̀ òkun. 7 Ègbé ni fún ayé nítorí àwọn ìgbà ìsubú! Nítorí àwọn ìgbá náà kòle ṣe àìwá, ṣùgbẹọ́n ègbé ni fún ẹni tí àwọn ìgbà wọ̀nyí ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ wá! 8 Tí ọwọ́ rẹ tàbí ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ ṣubú, gé e dànù kí o sì jùú sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè ní aláàbọ̀ ara jù kí wọ́n jù ọ́ sínú iná ayérayé pẹ̀lú ọwọ́ mééjèjì àti ẹsẹ̀ mééjèjì. 9 Tí ojú rẹ yóò bá gbé ọ ṣubú, yọ ọ́ jáde kí o sì jù ú sọnù. Nítorí ó sàn fún ọ láti wọ inú ìyè pẹ̀lú ojú kan jù kí wọ́n jù ọ́ sínú iná ayérayé pẹ̀lú ojú méjèjì . 10 Rí i dájú wípé o kò fi ojú kéré èyíkéyìí nínú àwọn kékeré wọ̀nyí. Nítorí mo wí fún yín wípé ní ìjọba ọ̀run àwọn áńgẹ́lì wọn ń wo ojú Bàbá mi tí Ó wà ní ọ̀run. 11 Nítorí ọmọ èníyàn wá láti gba àwọn tí ó sọnù là. 12 Kínni èrò yín? Tí ẹnikẹ́ni bá ní ọgọ́rùn ún àgùtàn, tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣì sọnù, ṣé òun kí yóò fi àwọn ọ̀kàndílọ́gọ́rùn ún náà sílẹ̀ kí ó ṣì wá èyí tí ó sọnù lọ? 13 Tí ó bá rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, òun yóò yọ̀ lórí rẹ̀ jù lórí àwọn ọ̀kàndílọ́gọ́rùn ún tí kò sọnù lọ. 14 Bákan náà, kìíṣe ìfọ́ Bàbá yín tí Ó wà lọ́run pé kí ọ̀kankan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí ṣègbé. 15 Tí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ bá a kí o sì sọ àsìṣe rẹ̀ fún un, láàrin òun àti ìwọ nìkan. Tí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ yóò ti gba ọkàn arákùnrin rẹ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ. 16 Ṣùgbọ́n tí kò bá gbọ́ tìrẹ, mú ẹnìkan tàbí méjì lẹ́yìn, kí á le fi ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀ lẹ́nu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta. 17 Tí ó bá ṣí kọ̀ síbẹ̀ láti gbọ́ tiwọn, ẹ sọ ọ̀rọ̀ náà fún ìjọ. Tí ó bá ṣì tún kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ, ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ sí yín bí kèfèrí àti agbowó òde. 18 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohun kohun tí ẹ̀yin ba dè ní ayé ni a yóò dè lọ́run; àti ohun kohun tí ẹ̀yin bá tú láyé ni a ó tú lọ́run. 19 Bẹ́ẹ̀ni mo tún wí fún yín, bí ẹni méjì nínú yín bá fi ohùn sọ̀kan ní ayé lórí ohun kohun tí ẹ̀yin bá bèèrè, Bàbá mi tí n bẹ lọ́run yóò ṣe é fún wọn. 20 Nítorí, ibi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kójọ ní orúkọ mi, èmi wà níbẹ̀ láàrin wọn. 21 Nígbà náà ni Pétérù wá ó ṣì wí fún Jésù pé, "Olúwa ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mí tí èmi yóò ṣì dáríjìn? Ṣé ìgbà méje?" 22 Jésù wì fun pé "èmi kò sọ fún ẹ pé ìgbà méje, ṣùgbọ́n títí dé ìgbà àádọ́rin méje. 23 Nítorí náà ìjọba ọ̀run dà bí Ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 24 Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣirò náà, wọ́n mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tálẹ́ńtì. 25 Ṣùgbọ́n nítorí kò ní ọ̀nà láti san án padà, ọ̀gá rẹ̀ pàṣẹ kí wọ́n tà á, pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti ohun gbogbo tí ó ní, láti le san gbèsè rẹ̀. 26 Nítorí náà ni ìranṣẹ́ náà ṣubú lulẹ̀, ó dọ̀bálẹ̀ ní iwájú rẹ̀, ó ṣì wípé, 'ọ̀gá, ẹ mú sùúrú fún mi, èmi yóò ṣì san gbogbo owó yín." 27 Nítorí náà ọ̀gá ìránṣẹ́ náà, Nítorí tí àánú ṣe é, ó tú u sílẹ̀ ó ṣì dárí gbèsè rẹ̀ jì. 28 Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà jáde lọ ó ṣì rí ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ akẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn ún dénárì. Ó mú u so, ó gbamú ní gògóńgò ọrùn, ó ṣì wípé 'San ohun tí o jẹmi fún mi.' 29 Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ akẹgbẹ́ rẹ̀ ṣubú sílẹ̀ ó ṣì bẹ̀ ẹ́, wípé 'mú sùúrù fún mi, èmi yóò san án fún ẹ padà.' 30 Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ àkọ́kọ́ náà kọ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó lọ ó ṣì sọ ọ́ sínú túbú títí di ìgbà tí yóò fi san ohun tí ó jẹ. 31 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ akẹgbẹ́ rẹ̀ yókù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó bàwọ́n nínú jẹ́. Wọ́n wá, wọ́n ṣì sọ fún ọ̀gá wọn ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀. 32 Nígbà náà ni ọ̀gá ìránṣẹ́ náà pè é, ó ṣì wí fún un, 'ìwọ ìránṣẹ́ búburú, mo dárí gbogbo gbèsè náà jín ọ́ nítorí wípé o bẹ̀mí. 33 Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìwọ ti ṣàánú fún ìránṣẹ́ akẹgbẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣàánú fún ọ?' 34 Ọ̀gá rẹ̀ bínú ó ṣì fi í le àwọn afìyàjẹni títí yóò fi san ohun gbogbo tí ó jẹ. 35 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Bàbá mi tí ḿbẹ lọ́run yóò ṣe fún yín, bí ẹni kọ̀ọ̀kan yín kò bá dárí jin arákùnrin rẹ̀ láti ọkàn yín."