Orí kẹtàdínlógún

1 Lẹ́yìn ijọ́ mẹ́fà Jésù mú pẹ̀lú rẹ̀ Pétérù, àti Jákọ́bù, àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀, ó sì mú wọn wá sí orí òkè gíga kan fún ra wọn. 2 A yi ní ara padà níwájú wọn. Ojú rẹ̀ si tàn bí òòrùn, asọ rẹ̀ si yọ bí ìmólẹ̀. 3 Sì kíyèsi, Mose àti Elijah yọ sí wọn nwọn ń bá a sọ̀rọ̀. 4 Peteru dáhùn ó sì wí fún Jésù pé, Olúwa, ó dára fún wa láti wà ní ìhín. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta síhǐn- ọ̀kan fún ọ, àti ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjàh 5 Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀, sìkíyèsi, àwọsánmà dídán ṣìji bò wọ́n, sì wò ó, ohùn kan ti àwọsánmà wá, tí ó wípé, "Èyí ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹnití inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. 6 Nígbàtí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ gbọ́, wọ́n da ojú wọn bo lẹ̀, ẹ̀ru sì bà wọ́n gidigidi. 7 Jésù si wá ó fi ọwọ́ kàn wọ́n ó sì wípé, "Ẹ dìde, ẹ sì má bẹ̀rù. 8 Nígbànǎ nwọ́n sì gbé ojú wọn sókè, wọọn kò rí ẹnìkan bíkòṣe Jésù nìkan. 9 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jésu pàsẹ fún wọn, ó wípé, Ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ìran yî fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ Ènìyàn yóó fi jíǹde nínú òkú. 10 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í lěrè, wípé, "Êse tí àwọn akọ̀wé ha fi wípé, Èlíjàh ni kí ó kọ́kọ́ dé? 11 Jésù dáhùn ó wí pé, Elijah yóò wá nítòótọ́ yí ò sí mú ohun gbogbo padà bọ̀ sípò. 12 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, Èlíjàh ti lẹ̀ wá ná, Ṣùgbọ́n wọn kò dá a mọ̀. Dípò, wọ́n se ohun tí ó wù wọ́n sí i. Ní ọ̀nà kannáà, ọmọ Ènìyàn yóò jìyà ní ọwọ́ wọn. 13 Nígbà ná ni ó yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn wípé àwọn ni ó ń bá wí nípa Jòhánù onítẹ̀bọmi. 14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, okùnrin kan wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ ní iwájú rẹ̀, ó sì wípé, 15 Olúwa, sàánú fún ọmọkùnrin mi, nítorí tí ó ní wárápá ó sìn ń joró gidigidi. Nítori ó ma ń sábà subú sínú iná tàbí omi. 16 Mo mu wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò le wò ó sàn. 17 Jésù sí dáhùn ó wípé, "ìran aláìgbàgbọ́ àti alárekérekè, bá wo ni èmi ó bá ti bá yín gbé pẹ́ tó? èmi ó sì ti mú sũrù fún yín pẹ́ tó? Gbé ọmọ náà tọ̀ mí wá níhǐn. 18 Jésù sí bá ẹ̀mí èsù náà wí, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀ a sì mú ọmọ náà láradá láti wákàtí náà. 19 Nigbànâ ni àwọn ọmọ èyìn Jésù tọ̀ ọ́ wá lẹ́yìnwọ́n sì wípé, Ẽṣe tí awa kò fi le lé e jàde? 20 Jésù sí wí fún wọn pé, "Nítorí ìgbàgbó yín tí ó kéré ni. Lótǐtọ́ ni mo wí fún n yín, bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí i wóró irúgbìn mústárdì, ẹ̀yin ó wì fún òkè yí pé, Ṣí níhǐn lọ sí ọ̀hún, yíò sì ṣí; kò sì sí ohun tí yíò sòro se fún yín. 21 irú ẹ̀mí èsù yí kò le jáde bíkòse nípa àdúrà àti àwẹ̀. 22 Nígbà tí wọ́n dúró ní gálilì, Jésù wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wípé, " A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, 23 wọn yíò sí paá, ní ọjọ́ kẹta yíò sì jí dìde. "Àwọn ọmọ èyìn sí bínú gidigidi. 24 Nígbàtí wọ́n dé Kapernaumu, àwọn okùnrin tí ó ń gbà àbọ̀-shékélí owó orí wásí ọ̀dọ̀ Peteru wọ́n sì wípé, "sé olùkọ́ yín kìí san olukọ nyin ki àbọ̀-shékélí owó orí ni"? 25 Ó wípé, "Bẹ̌ni". Ṣùgbọ́n nígbàtí Peteru sì wọ inú ilé, Jésù kọ́kọ́ bá sọ̀rọ̀ ówí pé, "Kíni ìwọ́ rò, Simoni? Lọ́wọ́ tani àwọn ọba ayé ti ń gba owó orí tàbí ìṣákọ́lẹ̀? Lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà tàbí àlejò? 26 Nígbàtí Pétérù wípé, "Lọ́wọ́ àlejò," Jésù wí fún n pé, " A yọ àwọn ẹmẹ̀wá láti má san owó ná 27 Ṣùgbọ́n kí a má se mú kí àwọn agbowó òdẹ dẹ́sẹ̀, lọ sí etí òkun, ju àwọ̀n sí i, kí o sì mú eja tí ó bá kọ́kọ́ jáde. Bí o bá ti la ẹnu rẹ̀, wâ rí shékẹ́lì kan, mú u kí o sì fún àwọn agbọwó orí fún èmi àti ìwọ.