Orí kẹrìndínlógún

1 Àwọn Farisí àti Sadusí wá láti dán a wò nípa sísọ fún n pé kí ófi àmì hàn wọ́n làti ọ̀run. 2 Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn ó sì wí fún wọn pé, "Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin wípé, 'ojú ọjọ́ yí ò dára, nítorí ojú ọ̀run pọ́n.' 3 Nígbà tí ó di òwúrọ̀, ẹ̀yin wípé, 'ojú ọjọ́ yóó dára, nítorí ojú ọ̀run pọ́n ó sì sú dẹdẹ. Ẹ̀yin mọ bí a tí ń túmọ̀ àmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ bí a tí ń túmọ̀ àmì àkókò. 4 Ìran búburú àtí panságà ń wá àmì kan, ṣùgbọ́n a kì yío fún n ní àmì bíkòse ti Jónà." Jésù si fi wọ́n sílẹ̀ ó sì kúrò níbẹ̀. 5 Nígbàtí àwọn ọmọ ẹ̀yìn dé òdì kejì, wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà lọ́wọ́. 6 Jésu wí fún wọn, "Ẹ kíyèsára kí ẹ sì máa sọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti Sadusí." 7 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ wọ́n sì wípé, "Nítorípé a kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni." 8 Jésù si mọ èyí ó sì wípé, "èyin onígbàgbọ́ kékeré, kí lódé tí ẹ̀yin fi ń bá ara yín sọ̀rọ̀ wípé nítorí àwa kò mú ákàrà lọ́wọ́ ni? 9 Kò tí yé yín di ìsinsìnyí tàbí ẹ̀yin kó rántí ìsù àkàrà márǔn fún àwọn ẹgbèrún márǔn nì, àti iye agbọ̀n tí ẹ̀yin sì kó jọ? 10 Tàbí ìsù àkàrà méje fún àwọn ẹgbèrún mérin, àti iye agbọ̀n tí ẹ̀yin kó jọ? 11 Báwo ni kò se yé yín pé èmi kò bá yín sọ̀rọ̀ nípa ti àkàrà? "Ẹ kíyèsára kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti Sadusí". 12 Nígbà náà ni ó yé wọn pé kò bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ti ìwúkàrà ti àkàrà, ṣùgbọ́n kí wọ́n sọ́ra fún ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti Sadusí. 13 Nígbàtí Jésù dé ìgbèríko tí ó súnmọ́ Kesaréà Fílíppì, ó bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lěrè, wípé, Tali àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ Ènìyàn pè? 14 Nwọ́n sì wí fún u pé, "Òmíràn ní, Johanu Baptisti; òmíràn wípé, Elijah; àwọn ẹlòmíràn ní, Jeremiah, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòólì. 15 Ó bi wọ́n lêrè, wípé, Ṣùgbọ́n tali ẹ̀yin ńfi mí pè? 16 Símónì Pétérù si dáhùn, wípé, ìwọ ni Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alààyè. 17 Jésù dáhùn ó sì wí fún pé, Alábùkúnfún ni ìwọ Símónì Ọmọ Jona, nítorí kìí ṣe ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ni ó fi èyí hàn ọ́, ṣùgbọ́n Baba mi tí ḿbẹ lí ọ̀run. 18 Èmi sì wí fún ọ pẹ̀lú pé ìwọ ni Pétérù, orí àpáta yí ni èmi yó kọ́ ìjọ mi lé pẹ̀lú. Ẹnu ọ̀nà ipò òkú kì yóò sì le borí rẹ̀. 19 Èmi ó sì fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá dè lí aiyé a ó sì dè é lí ọ̀run, ohunkóhun tí ìwọ bá tú sìlẹ̀ li aiyé a ó tu sílẹ̀ lí ọ̀run. 20 Jésù sí pàsẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn kí wọ́n má se sọ fún ẹnikẹ́ni wípé òhun ni Krístì. 21 Láti ìgbànáà lọ ni Jésu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wípé òun gbọdọ̀ lọ sí Jerúsálẹ̀mù, láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyaà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àlùfâ, àti àwọn akọ̀wé, kí a sì pa òun, àti ní ọjọ́ kẹta, kí òun sí jí dìde. 22 Nígbànâ ni Pétérù mu u sí ẹ̀gbẹ́ kan ó sì bá a wí pé, "Kí á má ri i, Olúwa, kì yóò rí bẹ̃ fún ọ. 23 Ṣùgbọ́n ó yípadà, ó sì wí fún Pétérù pé, "Kúrò lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí ìwọ kò ro ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, bíkòṣe èyí tí í ṣe ti ènìyàn. 24 Nígbànáà ni Jésu wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, " Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tẹ̀lé mi, ó gbọ́dọ̀ sé ara rẹ̀, kí ó gbé ǎgbélébǔ rẹ̀, kí ó sì tèlé mi. 25 Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ là yóó sọ ọ́ nù, àti ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ nù nítorí mi yó ri. 26 Nítorí àǹfàní kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn tí ó bá jèrè gbogbo ayé tí ó sì sọ èmí rẹ̀ nù? Kíni yí ó fì se pàsí pàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? 27 Nítorì ọmọ ènìyàn yóò wá nínú ògo Bàbá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì. yóò sì san án fún oníkálukú gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe. 28 Nítòtotó mo sọ fún n yín, àwon míràn wà nínú yín tí wọ́n dúró sí ibí, tí kò ní tọ́ ikú wò bíkòse igbà tí wọ́n bárí ọmọ Ènìyàn tí óń bọ̀ láti ìjọba rẹ̀.