Orí Kẹẹ̀dógún

1 Nígbà náà ni àwọn Farisí àti akọ̀wé kan tọ Jésù wá látǐ Jérúsálẹ́mù. Wọ́n wí pé, 2 Èése tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn re fin ń se lòdì sí ìse àwọn àgbà? Nítorípé wọn kò fo ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n má ń jẹun." 3 Ó dá wọn lóhùn ó sì wí fún wọn pé, "Èése tí ẹ̀yin fi ń rú òfin Ọlọ́run nítorí ìse yín? 4 Nítorí Ọlọ́run wípé, 'Bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ,' àti pé 'Ẹni tí ó bá so búburú nípa bàbá tàbí ìyá rẹ̀, kíkú ni yíò kú. 5 Ṣùgbọ́n ẹ̀yín wípé, 'Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ wípé "ìrànwọ́ yìó wù tí ó yẹ kí ẹ̀yin ó rí gbà lí ọwọ́ mi ti di ẹ̀bùn fún Ọlọ́run,"' 6 kò yẹ kí ẹni bẹ́ẹ̀ bu ọlá fún bàbá a rè. Nípa bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ti sọ òfin Ọlọ́run di òfo nítorí ìse yín. 7 Ẹ̀yin alágàbàgebè! Òtítọ́ ni Ìsáíàh so tẹ́lẹ́ nípa yín nígbà tí ó sọ wipé, 8 Àwọn ènìyàn yí ń sìn mí pẹ̀lú ètè wọn ṣùgbọ́n ọkàn wọn jínà sí mi. 9 Wọ́n ń sìn mí ní asán, wọ́n ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ bíi òfin àwọn ènìyàn.'" 10 Ó sì pe àwọn ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ó sì wí fún wọn pé, "Ẹ gbọ́ kí ó sì yé e yín-- 11 Kòsí ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn tí ó so ni di aláìmọ́. Bíkòse, ohun tí ó jáde látǐ ẹnu wá, èyí ni ó sọ ẹni di aláìmọ́." 12 Nígbà náà ni àwọn ọmọ ẹyìn wá, wọ́n sì wí fún Jésù pé, "Ǹjẹ́ o mọ̀ pé inú bí àwọn Farisí nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yí?" 13 Jésù dáhùn ó sì wípé, Gbogbo igi tí Bàbá à mi ní ọ̀run kò gbìn ni a ó fà tu jáde. 14 Ẹ jọ̀wọ́ wọn, afọ́jú tí ń fi ọ̀ná han ni ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì fi ónà han afọ́jú mǐràn, àwọn méjééjì yíò subúsí kòtò." 15 Pétérù dáhùn ó wí fún Jésù pé, "Sàlàyé ówe è yí fún wa." 16 Jésù wípé, "Èyin kò ha tún ní òye bí? 17 Ẹ̀yin ko ríi pé ohun kóhun tí ó bá lo sí ẹnu gba inú lọ a sì yàá jáde? 18 Ṣùgbọ́n ohun tí ó tẹnu wá ó wá láti ọkàn. Àwọn ni ohún tí ó ń sọ ni di àìmọ́. 19 Nítorí láti ọkàn ni èrò búburú ti jáde wá, ìpànìyàn, panságà, àgbèrè, olè, ẹlẹ́rǐ èké ati ìbanilórúkọ jẹ́. 20 Èyí ni àwọn ohun tí óń sọ ni di àìmọ́. Ṣùgbọ́n láti jẹun pẹ̀lú ọwọ́ tí a kò fọ̀ nù kò sọ ni di àìmọ́." 21 Jésù si kúrò níbẹ̀ lọ sí ẹkùn Tírè àti Sídónì. 22 Sì wó, obìnrin arà Kénánì ti ẹkùn náà wa. Ó sì kígbe pé, "Sàánú fún mi, Olúwa, Ìwọ Ọmọ Dáfídì! Ọmọ mi ni ẹ̀mí èsù ń dá lóró." 23 Ṣùgbọ́n Jésù kò dáa lóhùn ọ̀rọ̀ kan. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá wọ́n bẹ̀ẹ́, wípé, "Lé e lo kúrò, nítorí ó ń kígbe tò wá lẹ́yìn," 24 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó wípé, "A kò rán mi sí ẹnikẹ́ni bí kò se sí agùntàn ilé Ísrélì." 25 Ṣùgbọ́n ó wá ó sì foríbalẹ̀ níwájú u rẹ̀, ó wípé, "Olúwa, rànmílọ́wọ́." 26 Ó dáhùn ó wípé, "Kò tọ́ kí á mú àkàrà ọmọ kíá jǔ fún ajá kéékèé jẹ." 27 Ó wípé, "Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí i tábílí olúwa wọn jábọ́." 28 Jésù si dáhùn ó wí fún n pé, "Arábìnrin, ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ; kí ó rí fún ọ bí ó ti wù ọ́." NÍ wákàtí náà ara ọmọ re si yá. 29 Jésù sí kúròní ibẹ̀ ó wá sí etí òkun Gálílì. Ó gun orí òkè lọ ó sì jókǒ níbẹ̀. 30 Ọpọ̀ èrò sî tọ̀ ọ́ wá. Pẹ̀lú wọn ni àwọn amúkǔn, afọ́jú, odi àti arọ, àti ọpọ̀ àwọn tí ó ní àìlera. Wọ́n gbé wọn sí esè Jésù, ó sì wò wọ́n sàn. 31 Ẹnú sì ya àwọn ọpọ̀ enìyàn nígbà tí wọ́n rí odi tí ó sọrọ̀, arọ́ gba iwòsàn, amúkǔn rìn, àti afọ́jú ríran. Wọ́n yin Ọlórun Ìsrẹ́lì. 32 Jésù si pe àwọn ọmọẹyìn rẹ̀ sí ọdọ̀ rẹ̀ ó wípé, "Àánú ọ̀pọ̀ enìyàn yí se mí, nitorí wọ́n ti dúró tì mí fún ọjọ́ mẹ́ta wọn kò sì ní ohun láti je. Èmi kò fé rán wọn lọ láì jẹun, kí àárẹ̀ má baà mú wọn ní ọnà." 33 Àwọn ọmọ ẹyìn siwí fún n pé, "Níbo li a ó ti rí akàrà tí yíò tó ní aginjù yí tí yíò bọ́ ọpọ̀ erò yí?" 34 Jésù wí fún wọn pé, "Ìsù akàrà mélǒ nió wà? Wọ́n wípé, "Méje, àti eja wẹ́wẹ́ díè." 35 Jésù si pàsẹ kí ọ̀pọ̀ enìyàn náà jókǒ sílẹ̀. 36 Ó sì mú ìsù akàrà méje àti ẹja náà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó bu akàrà náà ó sì fún àwọn ọmọ ẹyìn. Àwọn ọmọ ẹyìn si fún àwọn ọpọ̀ enìyàn. 37 Gbogbo wọ́n sì jẹ ẹ́ wọ́n sì yó. Wọ́n sì kó apẹ̀rẹ̀ méjé jọ tí óún fún àjẹkù. 38 Àwọn tí ó sì jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbàájì okùnrin, yàtọ̀ sí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé. 39 Jésù si rán ọ̀pọ̀ enìyàn náà lọ ó sì bọ́ sínú ọkọ̀, ó sì lọ sí ẹ̀kún Màgádàn.