Orí Kẹtàlá

1 Lọ́jọ́ náà Jésù jáde láti inú ilé , Ó sì jókòó létí òkun. 2 Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn kórajọ sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí naà Ó kọjá sínú ọkọ̀ ojú omi, Ó sì jókòó sínú rẹ̀, nígbàtí ìjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn dúró létí bèbè òkun. 3 Nígbà naà, Jésù sọ ohun tí ó pọ̀ fún wọn pẹ̀lú òwe, wípé, "Kíyèsi, àgbẹ̀ kan lọ láti fúnrúgbìn. 4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá láti sàá jẹ. 5 Irúgbìn díẹ̀ bọ́ sórí àpáta, níbití kòsí ilẹ̀ púpọ̀, lójú ẹsẹ̀ ó yọ jáde nítorí ilẹ̀ nàa kò jìn. 6 Ṣùgbọ́n, nígbà tíi òòrùn ràn , wọ́n rọ, wọ́n sì gbẹ, nítorí wọn kò ní gbòngbò. 7 Àwọn irúgbìn míràn bọ́ s'áàrin àwọn ẹ̀gún, ẹ̀gún dàgbà, wọ́n sì fún irúgbìn ná pàa. 8 Irúgbìn míràn bọ́ sí ilẹ̀ rere, wọ́n sì ní èso, àwọn míràn Ọgọ́run bi tirẹ̀, Ọgọ́ta , àti Ọgbọ̀n 9 Ẹnití ó bá ní etí, kí ó tẹ́tí." 10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá, wọ́n sì sọ fún Jésù pé "èése tí ó fi ń bá àwọ̀n ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn òwe?" 11 Jésù dáhùn, Ó sì wí fún wọn pé, A ti fún un yín ní ànfààní láti ní òye ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn ni a kò fifún. 12 Nítorí àwọn tí ó ní, ni a o tun fi púpọ̀ fun, ṣùgbọ́n àwọn tí kò ní, a ó gbàa eyítí wọ́n ní lọ́wọ́ wọn. 13 Ìdí tí mo fi báwọn sọ̀rọ̀ ní òwe ni èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wòó, wọn kò ri, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gbọ́, òye kò si fún wọn. 14 Àsọtẹ́lẹ̀ Wòlíì Ìsáiàh sẹ nípa wọn wípé, "Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, ṣùgbọ́n kòní yée yín, ní rírí ẹ ó rìí, ẹ kì yoo ni òye rẹ̀." 15 Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì, ó nira fún wọn láti gbọ́, wọ́n di ojú wọn láti má ríran, tàbí etí wọn láti má gbọ́, tàbí ọkàn wọn láti má ní òye. Wọn ìbá yípadà, èmi ìbá wò wọ́n sàn. 16 Ìbùkún ni fún ojú yín tí ó ri, àti etí yín tí ó gbọ. 17 Lóòtítọ́ ni mo wí fun yín , ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn olódodo ni ó fẹ́ rí ohun tí ẹ rí yìí, ṣùgbọ́n tí wọn ko rìi tàbí gbọ́ ohun tí ẹ gbọ́ yìí, ṣùgbọ́n tí wọn kò gbọ́. 18 Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe àgbẹ̀ tí ó fúnrúgbìn rẹ̀. 19 Nígbà tí enìkan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run, sùgbọ́n tí kò ye, ẹni búburú naa ló wá láti jí ohun gbogbo tí a gbìn sí ọkàn rẹ̀. Èyí ni irúgbìn tí a gbín sí ẹ̀bá ọ̀nà. 20 Èyí tí ó bọ́ sórí àpáta ni, ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ naa, lójú ẹsẹ̀, tí ó sì f'ayọ̀ gbàá. 21 Ọ̀rọ̀ naa kò pẹ́ nínú rẹ̀, nítorí kòní gbòngbò. Nígbà tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni dé nítorí ọ̀rọ̀ naa, ó padà sẹ́yìn. 22 Irúgbìn tí a gbìn sáàrin ẹ̀gún ni, ẹnití ó gbọ́ ọ̀rọ̀ naa, sùgbọ́n tí ìtọ́jú ohun ayé àti ìtànjẹ ọrọ̀, fún ọ̀rọ̀ naa, kò sì jẹ́kí ó ní èso. 23 Irúgbìn tí ó bọ́ sílẹ̀ rere ni ẹnití ó gbọ́ ọ̀rọ̀ naa, tí ó ye, tí ó sí so èso, tí ó sí nìí irúgbìn bi ìlọ́po ọgọ́ọ̀rún, ọgọ́ta àti ọgbọ̀n irúfẹ́ ọ̀gbìn na tí ó gbìn. 24 Jésù pa òwe míràn fún wọn wípé, "Ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin kan tí ó gbin irúgbìn rere sínú ọgbà rẹ̀. 25 Ṣùgbọ́n nígbàtí ènìyàn sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, Ó sì gbin èpò sínú àlìkámọ̀, ó bá tirẹ̀ lọ. 26 Nígbàtí irúgbìn na ń yọ ewé, tí ó sì ń so èso, èpò pẹ̀lú farahàn. 27 Ìránsẹ́ ẹnití ó ni ọgbà naa wá, Ó sì wí fún un pé, 'Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ni o gbìn sínú ọgbà? níbo ni èpò ti wá?' 28 Ọ̀gá wí fún wọn pé, 'ọ̀tá ni ó se èyí.' Àwọn ìránsẹ́ na wí fún un pé, 'ǹjẹ́ o fẹ́ ká lọ láti fà wọ́n tu bí?' 29 Ẹnití ó ni ọgbà na wí pé, 'Rárá. Nígbà tí ẹ bá ń tu èpò, kí ẹ má ba tu àlìkámà pẹ̀lú rẹ̀.' 30 Jẹ́kí àwọn méjèjì ma dàgbà pọ̀ títí di àkókò ìkórè. Ní àkókò ìkórè, n ó sọ fún àwọn olùkórè, ẹ kọ́kọ́ tu àwọn èpò kí ẹ si dìwọ́n ní ìwọ̀n láti sun wọ́n, sùgbọ́n ẹ kó àlìkámà sínú àká èmi." 31 Jésù sọ òwe mìíràn fún wọn wí pé, "Ìjọba ọ̀run dàbí wóró músítádì kan, tí ẹnìkan mú tí ó sì gbìn sínú ọgbà rẹ̀. 32 Wóró irúgbìn yìí ni ó kéré jù nínú gbogbo wóró irúgbìn. Ṣùgbọ́n nígbàti ó bá dàgbà, a má tóbí ju gbogbo igi ọgbà lọ, á di igi tí àwọn ẹyẹ inú òfurufú ń se ìtẹ̀ wọn sí." 33 Jésù tún sọ òwe míràn fún wọn, "Ìjọba ọ̀run dàbí títàn ìwúkàrà tí obìnrin kan pò pẹ̀lú òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí ó fi gbé ra." 34 Gbogbo n kàn wọnyìí ni Jesù fi òwe sọfún àwọn ọ̀pọ́ ènìyàn; kò sí ohun tí ó sọ lai lo òwe. 35 Kí èyítí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ kí o lè sẹ, nígbàtí ó wípé, "Èmi yó yà ẹnu mi pẹ̀lú òwe, èmi yó sọ̀ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ tí o wà láti ìpìnlẹ̀ ayé wá." 36 Jésù fi ìjọ ènìyàn na sílẹ̀, Ó sì lọ sínú ilé, àwọn ọmọ ẹ̀yin Rẹ̀ tọ̀ọ́ wá wọ́n wípé, " Sàlàyé ìtumọ̀ àwọn òwe èpò nínú ọgbà fún wa." 37 Jésù dáhùn wípé, 'ẹnití ó gbin irúgbìn rere ni ọmọ ènìyàn. 38 Ayé ni ọgbà; àti irúgbìn rere ni àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ọmọ ẹni búburú na. 39 Ọ̀tá tí ó gbìn wọ́n ni èṣù. Àkókò ìkórè ni àkókò òpin ayé, àwọn olùkórè ni àwọn ángẹ́lì. 40 Nítorí nàa, gẹ́gẹ́bí a ti nkó èpò jọ láti fi jóná bẹ́ẹ̀ni yóò rí ní òpin ayé. 41 Ọmọ-ènìyàn yóò rán àwọn ángẹ́lì, wọn yoó sì kó ohun gbogbo tí ó ń fa ẹ̀sẹ̀ jáde kúrò nínú ìjọba rẹ̀, àti àwọn tí ń dẹ́sẹ̀. 42 A ó sì sọ̀ wọ́n sínú adágún iná, níbití ẹkún òhun ìpayínkeke yóò gbé wà. 43 Nígbà náà ni àwọn olódodo yo sì ma tàn nínú ìjọba bàbá wọn. Ẹnití ó bá ní etí, kí ó tẹ́tí. 44 Ìjọba Ọlọ́run dàbí ìsura tí a fi pamọ́ sínú ilẹ̀. Ènìyàn kan ri, ó sì fi pamọ́, pẹ̀lú ayọ̀, ó lọ, láti ta ohungbogbo tí ó ní, ó sì ra ilẹ̀ na. 45 Bákan náà, ìjọba Ọlọ́run dàbí ọkùnrin onísòwò tí ń wá ìsura dáradára. 46 Nígbàtí ó rí ìsura ńlá tí ó niye lórí, ó lọ láti ta ohungbogbo tí ó ní, ó sì rá. 47 Bákan náà, ìjọba ọ̀run dàbíi àwọ̀n tí a sọ sínú òkun, eléyìí tí ó kó onírúurú ẹja. 48 Nígbàtí àwọ̀n na kún, àwọn apẹja gbe àwọ̀n naa wá sí étí bèbè odò. Wọ́n jokòó, wọ́n yọ àwọn ẹja tí ó dara s'ápákan ṣùgbọ́n àwọn tí kò dára ni wọ́n gbé dànù. 49 Báyìí ni yóò se rí lópin ayé, àwọn ángẹ́lì yoo wa, wọn yóo sì yọ ènìyàn búburú kúrò nínú ènìyàn rere. 50 Wọn yóo sọ àwọn ènìyàn búburú sínú iná níbẹ̀ ni ẹkún òhun ìpayínkeke yóò gbé wà. 51 Ǹjẹ́ eléyìí ye yín?" Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, "Bẹ́ẹ̀ni." 52 Nígbà náà Jésù wí fún wọn pé, "Gbogbo akọ̀wé tí ó bá ti di ọmọ-ẹ̀yìn sí ìjọba ọ̀run, ó dàbí ẹnití ó ní ilé, tí ń kó ohun tí ó dara àti èyítí kò dára jáde láti inú ìsura rẹ̀." 53 Ó sìṣe, nígbàtí ó fi òwe báwọn sọ̀rọ̀ tan, Ó jáde kúrò ní agbègbé nà. 54 Jésù sí lọ̀ si agbègbè òun tìkararẹ̀, ó ń kọ́ni nínú Ṣínágọ́gù wọn. Àbájáde rẹ̀ ni pé ẹnú ya àwọn ènìyàn yìí, wípé, "Níbo ni ọkùnrin yìí ti rí irú ọgbọ́n àti isẹ́ ìyanu báyìí? 55 Ǹjẹ́ ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà naa kọ́ ni eléyìí? Ǹjẹ́ ìyá rẹ̀ kọ́ni Màríà? Àwọn arákùnrin rẹ̀ a kọ́ni Jàkọ́bù, Jòsẹ́fù, Símónì àti Júdà? 56 Àwọn arábìnrin rẹ̀ kò ha wà pẹ̀lú wa? Níbo ni Ó ti rí àwọn n ǹkan wọnyìí? 57 Ohun tí Ó sọ mú wọn bínú. Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, "Wòólì kìí lọ́lá ní ilu rẹ̀ àti nínú ẹbí rẹ̀." 58 Kò sì le sè isẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrin wọn , nítorí àìgbàgbọ́ wọn.