1
Júdà, ìránsé Jésù Kristì, àti arákùnrin Jákọ́bù, sí àwọn tí a pè, olùfẹ́ nínú Ọlọ́run Bàbá, tí a sì ti pamọ́ fun Jésù Kristí:
2
ǹjẹ́ kí àánú, àti àlàáfíà, àti ìfẹ́ di ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún yín.
3
Olùfẹ́, ní ìgbà tí èmi ń gbìyànjú láti kọ ìwé síi yín nípa ìgbàlà wa, èmi kọ ìwé síi yín láti gbàyín níyànjú pé kí ẹ jà fitanfitan fún ìgbàgbọ́ tí a fi lélẹ̀ lékanṣoṣo fún gbogbo onígbàgbó.
4
Nítorí àwọn arákùnrin kan ti yọ́ wọ àárín yín. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn tí ati fi àmì yà sí ọ̀tọ̀ fún ìdálẹ́bi. Wọ́n jẹ́ àwọn aláíwà bí Ọlọ́run tí ó ń yí oreọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí ẹran ara, àti tí ó ń ṣe Ọ̀gá wa kansoso àti Olúwa wa Jésù Kristì.
5
Nísinsìnyí, ó wù mí láti rán yín létí - bí ótilẹ̀ jẹ́ wípé ó yé yín yékéyéké ní ìgbà kán rí - wípé Olúwa gba àwọn ènìyàn kan là jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, sùgbọ́n léyìn ọ̀rẹyìn Ó pa àwọn tí kò gbàgbọ́ run.
6
Átiwípé àwọn áńgẹ́lì tí kò pa àye wọn mọ́, sùgbọ́n tí wọ́n kúrò ní àye ìgbé wọn tí ó yẹ - Ọlọ́run ti pawọ́n mọ́ nínú ìdè ayérayé, nínú òkùnkùn biribiri, fún ìdájọ́ ní ọjọ́ ńlá nì.
7
Ó dà bi Sódómù àti Gòmórà, àti àwọn ìlú tí ó yín wọn ká, tí àwọn naa kó ipa nínú àgbèrè àti ìlépa ìfẹ́kùfẹ́ ẹran ara. A fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bíi àpẹrẹ àwọn tí ó ń jiya ìdájọ́ nínú iná ìléru
8
Síbẹ̀ ní ònà kanna, àwọn alaala yi tún sọ àgú ara wọn di àìmó. Wọ́n t'àpá sí àsẹ, wọ́n sì tún sọ ọ̀rọ̀ òdì sí àwọn ẹni ògo.
9
Ṣùgbọ́n Máíkẹ́lì olú àwọn áńgẹ́lì, nígbà tí ó ń bá èsù ṣe àríyànjíàn lórí àgọ́ ara Mósè, ó kọ̀ láti sọ̀rò òdì si. Kàkà bẹ́ ó wípé, "Olúwa bá ọ wí!"
10
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn yí sọ̀rò òdì sí ohun gbogbo tí kó yé wọn. Èyí tí ó si yé wọn ní ó ń pawọ́n run, ní èyí tí àwọn ẹranko náà mọ̀.
11
Ègbé ni fún wọn! Nítorí wọ́n rìn ní ọ̀na Káínì, wọ́n sì ti wọ inú àsìse Bálámù fún èrè. Wọ́n ti parun sínú ọ̀tẹ̀ Kórà.
12
Àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn oníṣé ibi tó farapamọ́ nínú àsè yín. Wọ́n ṣe àsè láì ní ojútì, wọ́n jẹun fún arawọn. Wọ́n jẹ́ kùrukùru tí ò lómi, èyí tí atẹ́gùn ń gbé kiri. Wọ́n jẹ́ igi aláìléso - tí ati hú kúrò tí ó sìti kú.
13
Wọ́n dàbí ìjì ńlá lójú òkun, wọ́n ru ìtìjú ara wọn jáde. Wọ́n dàbi ìràwọ̀ tí ń ráre, àwọn ẹni tí òkùnkùn biribiri ńdúró dè títíláí.
14
Énọ́kù, ẹni ìkeeje làti Ádámù, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn, wípé, "Wòó! Olúwa ńbọ̀ pẹ̀lú egbẹgbèrún àwọn ẹni mímó Rẹ̀.
15
Ó ń bọ̀ láti ṣe ìdájọ́ gbogbo éníyán. Ó ń bọ̀ láti fi ẹ̀rí ọkàn jẹ́ gbogbo áwọn oní àìwà bíi Ọlórun fún gbogbo iṣé tí wọ́n ṣe ní ọ̀na àìwà bíi Ọlọ́run, ati gbogbo ọ̀rọ̀ òdì tí àwọn àìwà bíi Ọlọ́run sọ si I."
16
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n ń kùn tí wọ́n sì ń ṣe àwáwí, tí wọ́n ń tẹ̀lé ìfẹ́kùfẹ́ ara wọn. Wọ́n jẹ́ onígbéraga tí ń fún àwọn ẹlòmíràn ní íyin èké nítorí èrè arawọn.
17
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ẹrántí àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn àpọ́stélì Jésù sọ sẹ́yìn.
18
Wọ́n sọ fún yín wípé, "Ní ìgbà ìkẹyìn àwọn elékèé yóò wà tí wọ́n yóò ma tẹ̀lé ìfẹ́kùfẹ́ ara."
19
Àwọn ènìyàn yìí jẹ́ onírúgúdù. Wọ́n jẹ́ ẹni ti ayé, wọn kò sì ní Ẹ̀mí Mímó.
20
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, olùfẹ́, ẹ mú ara yín dàgbà nínú ìgbàgbọ́ mímó yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà nínú Ẹ̀mí Mímó
21
Ẹ fi ara yín pamọ́ sínú ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ sì dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristì tí yóò mú ìyè ayérayé wá fún yín.
22
Ẹmáa ṣàánú àwọn tó ń siyè méjì.
23
Ẹgba àwọn ẹlòmíràn nípa jíjáwọn gbà kúrò nínú iná. Sí àwọn òmíràn ẹṣàánú pẹ̀lúu ẹ̀rù. Kódà ẹkóríra aṣọ tí ẹran ara ti sodi alábàwọ́n.
24
Nísinsìnyín sí Ẹni tí ó leè pa yìn mọ́ kúrò nínú ìsubú, àti láti mú n yín dúró níwájú ìwàláàyè ológo Rẹ̀, láìsí àbàwọ́n àti pẹ̀lú ayọ̀ ńlá,
25
sí Ọlọ́run Olùgbàlà wa nípasẹ̀ Jésù Kristì Olùwa wa, kí ògo, ọlá, ìjọba àti agbára, sáájú gbogbo àkókò, nísinsìnyí, àti títí láíláí. Àmín.