Orí Kinni

1 Alàgbà náà sí Gáíù olùfẹ́, ẹnití mo fẹ́ràn ní òtítọ́. 2 Olùfẹ́, mo gbàdúrà pé kí o le ṣe rere nínú ohun gbogbo àti kí o sì wà ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí ọkàn rẹ se ń ṣe rere. 3 Nítorí mo yọ ayọ̀ ńláńlá nígbàtí àwọn arákùnrin dé tí wọ́n sì j'ẹ̀rí sí òtítọ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti fi òtítọ́ rìn. 4 Èmi kò ní ayọ̀ ńlá kan tí óju báyìí lọ, láti gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́. 5 Olùfẹ́, ìwọ ń fi ìsòtítọ́ sí ìse ní gbogbo ìgbà tí o báse isẹ́ fún àwọn arákùnrin àti fún àwọn àlejò, 6 àwọn tí wọ́n ti jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ níiwájú ìjọ. Ìwọ se dáradára tí o sìn wọ́n sọ́nà ni ọ̀nà tí ó yẹ sí Ọlọ́run, 7 nítorípé nítorí ti orúkọ Olúwa ni wọ́n jáde lọ, láí gba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn kèfèrí. 8 Nítorínà a gbọdọ̀ fi ààye gba irú àwọn ènìyàn báwọ̀nyí, a ó sìle jọ jẹ́ alábàásisẹ́pọ̀ fún òtítọ́. 9 Mo kọ ìwé sí agbo náà, ṣùgbọ́n Díótréfìs, ẹnití ó fẹ́ láti máa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàrin wọn, kò fi àyè gbà wá. 10 Nítorínà, bí mo bá dé, èmi ó mú ìṣe rẹ̀ tí ó ń ṣe wá sí ìrántí, bí ó se ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ búburú ní ìlòdì sí wa láti yẹ̀yẹ́ wa. Àwọn ìṣe wọ̀nyí kò sì tún tó o, òun tìkalárarẹ̀ kò tùn fi ààyè gba àwọn arákùnrin náà. Ó ń dá àwọn tí wọ́n fẹ́ se lẹ́kun, ó sì tún ń lé wọn jáde kúrò nínù agbo. 11 Olufẹ́, máse se àfarawé ohun tí íse ibi ṣùgbọ́n ohun tí ń se rere. Ẹnití ó se rere jẹ́ ti Ọlọ́run; ẹni tí ó ń ṣe ibi kò tí rí Ọlọ́run. 12 Òtítọ́ jẹ́rìí gbe Démétíríù àti àwọn ènìyàn jẹ́ríì rẹ̀. Àwa pẹ̀lú se ẹlẹ́rìí, ẹ sì mọ̀ pé ẹ̀rí wa òtítọ́ ni. 13 Mo ní ohun púpọ̀ láti kọ síi yín, ṣùgbọ́n n kò fẹ́ kọ wọ́n pèlúu kálàmù àti aró. 14 Ṣùgbọ́n mo ní ìrètí láti rí yín láìpẹ́, a ó sì sọ̀rọ̀ lójúkoojú. 15 Kí àlàáfíà wà pẹ̀lú yín. Àwọn ọ̀rẹ́ kìi yín. Ẹ kí àwọn ọ̀rẹ́ ní pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan.