Orí Kínní

1 Símónì Pétérù, ẹrú àti àpóstélì Jésù Krístì, sí àwọn tọ́ ti gba ìgbàgbọ́ iyebíye tí àwa náà ti gbà, ìgbàgbọ nínú òdodo Ọlórun àti Olùgbàlà wá Jésù Krístì 2 Kí Oreọ̀fẹ́ àti àláfíà máa pọ̀ si ní ìwọ̀n ọgbọ́n Ọlórun àti ti Jésù Olúwa wá. 3 Gbogbo ohun tí óníṣe pẹ̀lú agbára àtòkèwá fún ìyè àti ìwàbíi-Ọlórun lati fi fún wa nípa ọgbọn Ọlórun, Ẹni tí óti pèwá nípa ògo àti ìwà rerẹ̀ Rẹ̀. 4 Nípa ìwọ̀nyí, Óti fún wa ní ìlérí ńlá àti èyítí óse iyebíye, kí ìwọ leè jẹ́ alábàápín nínú-un ara àtòkèwá, bí ó ṣe ń yọ kúrò nínu ìbàjẹ́ tí ó wà nínu ayé nítorí àwọn ìfẹ́-ọkàn búburú. 5 Fún ìdí èyí, sa ipá rẹ láti fikún ìwà-rere nípa ìgbàgbọ rẹ, àti nípa ìwà-rere, ìmọ̀. 6 Nípa òye rẹ, fikún ìwà ìkóra ẹni-ní-ìjánu, àti nípa ìwà ìkóra ẹni-ní-ìjánu rẹ, fikún ìpamọ́ra, àti nípa ìpamọ́ra rẹ, fikún ìwà bí Ọlórun. 7 Nípa ìwà bí Ọlórun rẹ, fikún ìfé-ará, àti nípa ìfẹ́-ará rẹ, fikún ìfẹ́. 8 Bí àwọn ǹkan wọ̀nyín báwà nínú-ùn rẹ, tí wọ́n sì-ń dàgbà nínú rẹ, o kò ní jẹ́ àgàn tàbí àláìléso ní ti ìmọ̀ Olúwa wa Jésù Krístì. 9 Sùgbọ́n ẹnikẹ́ni tóbá jẹ́ aláìní àwọn ǹkan wọ̀nyí rí oun tó súnmọ́ọ nìkan; ó jẹ́ afọ́jú. Ó ti gbàgbé ìwẹ̀nùmó kúrò nínú ẹ̀sẹ̀ àtijọ́ rẹ̀. 10 Nítorínà, ará, sá ipáàrẹ láti jẹ́ kí ìpè àti yíyàn rẹ dá ọ lójú. Bí o bá ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyín, o kò ní subú. 11 Ní ọ̀nà yí wíwọlé sí ìjọba ayérayé ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì ní a ó fifún yín lọ́pọ̀lọpọ̀. 12 Nítorínà èmi yóò ṣetán nígbàgbogbo láti máarán-yín létí àwọn ǹkan wọ̀nyí, bótilẹ̀jẹ́pé ẹ mọ̀ wọ́n, àti bótilẹ̀jẹ́pé ẹ ti dàgbà nínú òtítọ́ nísisìnyí. 13 Mo lé rò pé ó tọ́ fún mi láti ru yín sókè pẹ̀lú ìrántí nípa àwọn ǹkan wọ̀nyí, ní ìwọ̀n ìgbà tí mo wà nínu àgọ́ yìí. 14 Nítorí mo mọ̀ pé láìpẹ́, èmi yóò yọ àgọ́ mí, bí Olúwa wa Jésù Krístì tí fí hàn mí. 15 Èmi yóò sa ipá mi fún-un yín láti lè ma rántí àwọn ǹkan wọ̀nyí lẹ́yìn tí mo bá lọ tán. 16 Nítorí a kò tẹ̀lé pẹ̀lú àkàyé àwọn àròsọ tí a dá nígbàtí asọ fún yín nípa agbára àti ìrísí Olúwa wa Jésù Krístì. Dípò, àwa jẹ́ ẹlẹ́rìí ọláńlá rẹ̀. 17 Nítorí ó gbà látọ̀dọ Ọlórun Bàbá, ọlá àti ògo nígbàtí ohùn kan tọ̀ọ́ wá nípa ọlá Ògo tó wípé, ''Èyí ni Ọmọ mi, Ẹni tí mo fẹ́, ẹni tí inú-ùn mí dùn sí gidgidi'' . 18 Agbọ́ ohùn tó jáde látọ̀run wá, nígbàtí a wà pẹ̀lú rẹ̀ lórí òkè mímọ́. 19 A ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí ó dájú. Ẹ ṣe dárádára láti ṣe àkíyèsí rẹ̀. Ó dàbí àtùpà tín taná nínú òkùnkùn títí di òwúrọ̀ àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ gbésékè nínu ọkàn rẹ 20 Ẹ kọ́kọ́ mọ èyí, wípé kòsí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ tí ìtumọ̀ ènìyàn kan. 21 Nítorí kòsí àsọtẹ́lẹ̀ tó wá nípa ìfẹ́ ènìyàn. Dípò, àwọn ènìyàn tí Ẹ̀mí Mímọ́ tó sọ jáde látọ̀dọ Ọlọ́run.